Dan 6:1-6
Dan 6:1-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba; Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara. Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba. Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀. Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́.
Dan 6:1-6 Yoruba Bible (YCE)
Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀. Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún. Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.” Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́
Dan 6:1-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó dára lójú Dariusi láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba, pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára. Daniẹli ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrín àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbèrò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba. Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara. Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí Daniẹli lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dariusi ọba, kí o pẹ́!