Dan 6:1-13

Dan 6:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

O ṣe didùn inu Dariusi lati fi ọgọfa arẹ bãlẹ sori ijọba na, ti yio wà lori gbogbo ijọba; Ati lori awọn wọnyi ni alakoso mẹta: Danieli si jẹ ọkan ninu wọn: ki awọn arẹ bãlẹ ki o le ma jiyin fun wọn, ki ọba ki o má ṣe ni ipalara. Danieli yi si bori gbogbo awọn alakoso ati arẹ bãlẹ wọnyi, nitoripe ẹmi titayọ wà lara rẹ̀: ọba si ngbiro lati fi i ṣe olori gbogbo ijọba. Nigbana ni awọn alakoso, ati awọn arẹ bãlẹ nwá ẹ̀sùn si Danieli lẹsẹ̀ nipa ọ̀rọ ijọba, ṣugbọn nwọn kò le ri ẹ̀sùn tabi ẹ̀ṣẹkẹṣẹ lọwọ rẹ̀; niwọn bi on ti jẹ olododo enia tobẹ̃ ti a kò si ri iṣina tabi ẹ̀ṣẹ kan lọwọ rẹ̀. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi wipe, Awa kì yio le ri ẹ̀sùn kan si Danieli bikoṣepe a ba ri i si i nipasẹ ofin Ọlọrun rẹ̀. Nigbana ni awọn alakoso ati awọn arẹ bãlẹ wọnyi pejọ pọ̀ lẹsẹkanna lọdọ ọba, nwọn si wi bayi pe ki Dariusi ọba, ki o pẹ́. Gbogbo awọn olori alakoso ijọba, awọn bãlẹ ati awọn arẹ bãlẹ, awọn ìgbimọ, ati olori ogun jọ gbìmọ pọ̀ lati fi ofin ọba kan lelẹ, ati lati paṣẹ lile kan, pe ẹnikẹni ti o ba bère nkan lọwọ Ọlọrun tabi eniakenia niwọn ọgbọ̀n ọjọ bikoṣepe lọwọ rẹ, ọba, a o gbé e sọ sinu ihò kiniun. Njẹ nisisiyi, ọba, fi aṣẹ na lelẹ, ki o si fi ọwọ rẹ sinu iwe ki o máṣe yipada, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, eyi ti a kò gbọdọ pada. Nigbana ni Dariusi fi ọwọ sinu iwe ati aṣẹ na. Nigbati Danieli si ti mọ̀ pe a kọ iwe na tan, o wọ ile rẹ̀ lọ; (a si ṣi oju ferese yara rẹ̀ silẹ siha Jerusalemu) o kunlẹ li ẽkun rẹ̀ nigba mẹta lõjọ, o gbadura, o si dupẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀, gẹgẹ bi on ti iṣe nigba atijọ ri. Nigbana ni awọn ọkunrin wọnyi rìn wọle, nwọn si ri Danieli ngbadura, o si mbẹbẹ niwaju Ọlọrun rẹ̀. Nigbana ni nwọn wá, nwọn si wi niwaju ọba niti aṣẹ ọba pe, Kò ṣepe iwọ fi ọwọ sinu iwe pe, ẹnikan ti o ba bère ohunkohun lọwọ Ọlọrun tabi lọwọ enia kan niwọn ọgbọ̀n ọjọ, bikoṣe lọwọ rẹ, ọba, pe a o gbé e sọ sinu iho kiniun? Ọba si dahùn o wipe, Otitọ li ọ̀ran na, gẹgẹ bi ofin awọn ara Media ati Persia, ti a kò gbọdọ pada. Nigbana ni nwọn dahùn nwọn si wi niwaju ọba pe, Danieli ọkan ninu awọn ọmọ igbekun Juda kò kà ọ si, ọba, ati aṣẹ, nitori eyi ti iwọ fi ọwọ rẹ sinu iwe, ṣugbọn o ngbadura rẹ̀ nigba mẹta lõjọ.

Dan 6:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó dára lójú Dariusi láti yan ọgọ́fà àwọn baálẹ̀ sórí ìjọba, pẹ̀lú alákòóso mẹ́ta, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan nínú wọn, kí àwọn baálẹ̀ lè wá máa jẹ́ ààbọ̀ fún wọn, kí ọba má ba à ní ìpalára. Daniẹli ya ara rẹ̀ sọ́tọ̀ láàrín àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ nítorí ẹ̀mí tí ó tayọ wà lára rẹ̀ dé bi pé ọba sì ń gbèrò láti fi ṣe olórí i gbogbo ìjọba. Nítorí èyí, gbogbo àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ ń gbèrò láti wá ẹ̀ṣẹ̀ kà sí Daniẹli lọ́rùn nínú ètò ìṣèjọba rẹ̀, ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹ̀ṣẹ̀ kankan kà sí i lọ́rùn, wọn kò rí ìwà ìbàjẹ́ kankan tí ó ṣe, nítorí ó jẹ́ olóòtítọ́ kò sì ní ìwà ìjáfara. Nígbẹ̀yìn ni àwọn ọkùnrin wọ̀nyí sọ wí pé, “Àwa kò ní rí ìdí kankan láti kà ẹ̀ṣẹ̀ sí Daniẹli lọ́rùn, àfi èyí tí ó bá ní í ṣe pẹ̀lú òfin Ọlọ́run rẹ̀.” Nígbà náà ni àwọn alákòóso àti àwọn baálẹ̀ lọ gẹ́gẹ́ bí ikọ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba, wọ́n wí pé: “Ìwọ Dariusi ọba, kí o pẹ́! Àwọn alákòóso ọba, ìjòyè, baálẹ̀, olùdámọ̀ràn, àti àwọn olórí gbìmọ̀ pọ̀ wí pé kí ọba kéde òfin kan pé ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, yàtọ̀ fún ìwọ ọba, a ó ju ẹni náà sí inú ihò kìnnìún. Nísinsin yìí, ìwọ ọba, gbé òfin yìí jáde, kí o sì kọ ọ́ sínú ìwé kí a má ba à yí i padà ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn Media àti Persia, èyí tí kò ní le è parẹ́.” Nígbà náà, ni Dariusi ọba fi ọwọ́ sí ìwé àṣẹ náà. Lóòótọ́, Daniẹli mọ̀ pé a ti fi ọwọ́ sí ìwé òfin náà, síbẹ̀ ó wọ ilé e rẹ̀ lọ, nínú yàrá òkè, ó ṣí fèrèsé èyí tí ó kọjú sí Jerusalẹmu sílẹ̀. Ó kúnlẹ̀ lórí orúnkún un rẹ̀ ní ẹ̀mẹ́ta lójoojúmọ́, ó gbàdúrà, ó fi ọpẹ́ fún Ọlọ́run gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀ tẹ́lẹ̀. Nígbà náà ni, àwọn ọlọ̀tẹ̀ yìí kó ara wọn jọ, wọ́n sì rí Daniẹli tí ó ń gba àdúrà, ó sì ń bẹ̀bẹ̀ fún àánú lọ́dọ̀ Ọlọ́run. Wọ́n lọ sí iwájú ọba, wọ́n sì rán ọba létí nípa òfin tí ó ṣe pé, “Ìwọ kò ha fi ọwọ́ sí òfin wí pé ní ìwọ̀n ọgbọ̀n ọjọ́ ẹnikẹ́ni tí ó bá gba àdúrà sí Ọlọ́run tàbí ènìyàn, láì bá ṣe ìwọ ọba, a ó gbé e jù sínú ihò kìnnìún?” Ọba sì dáhùn pé, “Àṣẹ náà dúró síbẹ̀, ní ìbámu pẹ̀lú òfin àwọn ará Media àti Persia, èyí tí a kò le è parẹ́.” Nígbà náà, ni wọ́n sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan lára ìgbèkùn Juda, kò ka ìwọ ọba sí, tàbí àṣẹ ẹ̀ rẹ tí o fi ọwọ́ sí. Òun sì tún ń gba àdúrà ní ẹ̀mẹ́ta lójúmọ́.”

Dan 6:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Dariusi ṣètò láti yan ọgọfa (120) gomina láti ṣe àkóso ìjọba rẹ̀. Ó yan àwọn mẹta láti máa ṣe àbojútó gbogbo wọn, Daniẹli sì jẹ́ ọ̀kan ninu wọn. Àwọn mẹta wọnyi ni àwọn ọgọfa (120) gomina náà yóo máa jábọ̀ fún. Ṣugbọn Daniẹli tún ta gbogbo àwọn alámòójútó ati gomina náà yọ nítorí ẹ̀mí tí kò lẹ́gbẹ́ tí ó wà ninu rẹ̀. Ọba sì ń gbèrò láti fi gbogbo ọ̀rọ̀ ìjọba lé e lọ́wọ́. Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina wọnyi ń wá ẹ̀sùn sí Daniẹli lẹ́sẹ̀ nípa ọ̀rọ̀ ìjọba, ṣugbọn wọn kò rí ẹ̀sùn kankan tí wọ́n lè kà sí i lẹ́sẹ̀. Wọn kò ká ohunkohun mọ́ ọn lọ́wọ́ nítorí olóòótọ́ eniyan ni. Wọn kò bá àṣìṣe kankan lọ́wọ́ rẹ̀. Wọ́n sọ fún ara wọn pé, “A kò ní rí ẹ̀sùn kà sí Daniẹli lẹ́sẹ̀, àfi ohun tí ó bá jẹmọ́ òfin Ọlọrun rẹ̀.” Nítorí náà, àwọn alabojuto ati àwọn gomina gbìmọ̀ pọ̀, wọ́n kó ara wọn jọ sọ́dọ̀ ọba, wọ́n wí fún un pé “Dariusi ọba, kí ọba pẹ́, gbogbo àwọn alabojuto, àwọn olórí, àwọn ìgbìmọ̀, ati àwọn gomina kó ara wọn jọ, wọ́n sì fi ohùn ṣọ̀kan pé kí ọba ṣe òfin kan pé, ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ òun ọba. Ẹni tí ó bá ṣe bẹ́ẹ̀, kabiyesi, kí wọ́n jù ú sinu ihò kinniun. Nisinsinyii, kabiyesi, ẹ fi ọwọ́ sí òfin yìí, kí ó lè fi ìdí múlẹ̀, gẹ́gẹ́ bí òfin Mede ati Pasia tí kò gbọdọ̀ yipada.” Nítorí náà, Dariusi ọba fi ọwọ́ sí òfin náà, ó sì fi òǹtẹ̀ tẹ̀ ẹ́. Nígbà tí Daniẹli gbọ́ pé wọ́n ti fi ọwọ́ sí òfin náà, ó lọ sí ilé rẹ̀, ó wọ yàrá òkè lọ, ó ṣí fèrèsé ilé rẹ̀ sílẹ̀, sí apá Jerusalẹmu. Ó kúnlẹ̀, ó ń gbadura, ó sì ń yin Ọlọrun, nígbà mẹta lojoojumọ. Àwọn ọkunrin wọnyi bá kó ara wọn jọ. Wọ́n wá wo Daniẹli níbi tí ó ti ń gbadura, tí ó sì ń bẹ̀bẹ̀ níwájú Ọlọrun rẹ̀. Wọ́n wá siwaju ọba, wọ́n sọ nípa àṣẹ tí ó pa pé ẹnikẹ́ni kò gbọdọ̀ bèèrè ohunkohun lọ́wọ́ oriṣa kankan tabi eniyan kankan fún ọgbọ̀n ọjọ́, bíkòṣe lọ́wọ́ rẹ̀, ati pé ẹnikẹ́ni tí ó bá rú òfin yìí, a óo jù ú sinu ihò kinniun. Ọba dáhùn, ó ní: “Dájúdájú, òfin Mede ati Pasia ni, tí a kò lè yipada.” Wọ́n bá sọ fún ọba pé, “Daniẹli, ọ̀kan ninu àwọn ìgbèkùn Juda kò kà ọ́ sí, kò sì pa òfin rẹ mọ́. Ṣugbọn ìgbà mẹta lóòjọ́ níí máa gbadura.”