Dan 5:25-28
Dan 5:25-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Eyiyi si ni iwe na ti a kọ, MENE, MENE, TEKELI, PERESINI. Eyi ni itumọ ohun na: MENE, Ọlọrun ti ṣirò ijọba rẹ, o si pari rẹ̀. TEKELI; A ti wọ̀n ọ wò ninu ọ̀ṣuwọn, iwọ kò si to. PERESINI; A pin ijọba rẹ, a si fi fun awọn ara Media, ati awọn ara Persia.
Dan 5:25-28 Yoruba Bible (YCE)
“Ohun tí a kọ náà nìyí: ‘MENE, MENE, TEKELI, PERESINI.’ Ìtumọ̀ rẹ̀ sì nìyí: MENE, Ọlọrun ti ṣírò àwọn ọjọ́ ìjọba rẹ, ó sì ti parí rẹ̀. TEKELI, a ti wọ̀n ọ́ lórí ìwọ̀n, o kò sì kún ojú ìwọ̀n. PERESINI, a ti pín ìjọba rẹ, a sì ti fún àwọn ará Mede ati àwọn ará Pasia.”
Dan 5:25-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Èyí ni àkọlé náà tí a kọ: mene, mene, tekeli, peresini “Èyí ni nǹkan tí ọ̀rọ̀ náà túmọ̀ sí: “ Mene: Ọlọ́run ti ṣírò ọjọ́ ìjọba rẹ. Ó sì ti mú u wá sí òpin. “ Tekeli: A ti gbé ọ lórí òṣùwọ̀n, ìwọ kò sì tó ìwọ̀n. “Peresini: A ti pín ìjọba rẹ a sì ti fi fún àwọn Media àti àwọn Persia.”