Dan 5:17-23

Dan 5:17-23 Bibeli Mimọ (YBCV)

Nigbana ni Danieli dahùn, o si wi niwaju ọba pe, Jẹ ki ẹ̀bun rẹ gbe ọwọ rẹ, ki o si fi ẹsan rẹ fun ẹlomiran; ṣugbọn emi o ka iwe na fun ọba, emi o si fi itumọ rẹ̀ hàn fun u. Iwọ ọba! Ọlọrun Ọga-ogo fi ijọba, ati ọlanla, ati ogo, ati ọlá fun Nebukadnessari, baba rẹ: Ati nitori ọlanla ti o fi fun u, gbogbo enia, orilẹ, ati ède gbogbo nwariri, nwọn si mbẹ̀ru niwaju rẹ̀: ẹniti o wù u, a pa, ẹniti o si wù u, a da si lãye; ẹniti o wù u, a gbé ga; ẹniti o si wú u, a rẹ̀ silẹ. Ṣugbọn nigbati ọkàn rẹ̀ gbega, ti inu rẹ̀ si le nipa igberaga, a mu u kuro lori itẹ rẹ̀, nwọn si gba ogo rẹ̀ lọwọ rẹ̀: A si le e kuro lãrin awọn ọmọ enia; a si ṣe aiya rẹ̀ dabi ti ẹranko, ibugbe rẹ̀ si wà lọdọ awọn kẹtẹkẹtẹ igbẹ; nwọn si fi koriko bọ́ ọ gẹgẹ bi malu, a si mu ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara; titi on fi mọ̀ pe Ọlọrun Ọga-ogo ni iṣe alakoso ninu ijọba enia, on a si yàn ẹnikẹni ti o wù u ṣe olori rẹ̀. Ati iwọ Belṣassari, ọmọ rẹ̀, iwọ kò rẹ̀ ọkàn rẹ silẹ, bi iwọ si tilẹ ti mọ̀ gbogbo nkan wọnyi; Ṣugbọn iwọ gbé ara rẹ ga si Oluwa ọrun, nwọn si ti mu ohun-elo ile rẹ̀ wá siwaju rẹ, iwọ ati awọn ijoye rẹ, ati awọn aya rẹ, ati awọn àle rẹ si ti nmu ọti-waini ninu wọn; iwọ si ti nkọrin iyìn si oriṣa fadaka, ati ti wura, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta, awọn ti kò riran, ti kò gbọran, bẹ̃ni nwọn kò si mọ̀: ṣugbọn Ọlọrun na, lọwọ ẹniti ẹmi rẹ wà, ati ti ẹniti gbogbo ọ̀na rẹ iṣe on ni iwọ kò bu ọlá fun.

Dan 5:17-23 Yoruba Bible (YCE)

Daniẹli dá ọba lóhùn, ó ní, “Jẹ́ kí ẹ̀bùn rẹ máa gbé ọwọ́ rẹ, kí o sì fi ọrẹ rẹ fún ẹlòmíràn. Ṣugbọn n óo ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, n óo sì túmọ̀ rẹ̀. “Kabiyesi, Ọlọrun tí ó ga jùlọ fún Nebukadinesari, baba rẹ ní ìjọba, ó sọ ọ́ di ẹni ńlá, ó fún un ní ògo ati ọlá. Nítorí pé Ọlọrun sọ ọ́ di ẹni ńlá, gbogbo eniyan, gbogbo orílẹ̀-èdè ati gbogbo ẹ̀yà ń tẹríba fún un tìbẹ̀rùtìbẹ̀rù. A máa pa ẹni tí ó bá fẹ́, a sì máa dá ẹni tí ó fẹ́ sí. A máa gbé ẹni tí ó bá fẹ́ ga, a sì máa rẹ ẹni tí ó bá wù ú sílẹ̀. Ṣugbọn nígbà tí ó gbé ara rẹ̀ ga, tí ó sì ṣe oríkunkun, a mú un kúrò lórí ìtẹ́ rẹ̀, a sì mú ògo rẹ̀ kúrò. A lé e kúrò láàrin àwọn ọmọ eniyan, ọkàn rẹ̀ dàbí ti ẹranko. Ó ń bá àwọn ẹranko gbé inú igbó. Ó ń jẹ koríko bíi mààlúù, ìrì sì sẹ̀ sí i lára, títí ó fi mọ̀ pé Ọlọrun tí ó ga jùlọ, ni ó ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, tí ó sì ń gbé e fún ẹni tí ó bá wù ú. “Bẹ́ẹ̀ ni, ìwọ ọmọ rẹ̀ Beṣasari, o kọ̀, o kò rẹ ara rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé o mọ̀ nípa ìṣẹ̀lẹ̀ yìí. Ò ń gbéraga sí Ọlọrun ọ̀run. O ranṣẹ lọ kó àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun wá siwaju rẹ. Ìwọ ati àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ayaba ati àwọn obinrin rẹ, ẹ bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí waini. Ẹ sì ń yin àwọn oriṣa fadaka, ti wúrà, ti idẹ, ti irin, ti igi ati ti òkúta. Wọn kò ríran wọn kò gbọ́ràn, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò mọ ohun tí ó ń ṣẹlẹ̀. O kò yin Ọlọrun tí ẹ̀mí rẹ wà lọ́wọ́ rẹ̀ lógo, ẹni tí ó mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.

Dan 5:17-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)

Nígbà náà ni Daniẹli dá ọba lóhùn wí pé, “Fi ẹ̀bùn rẹ pamọ́ fún ara rẹ, tàbí kí o fún ẹlòmíràn. Síbẹ̀ èmi yóò ka àkọsílẹ̀ náà fún ọba, èmi yóò sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀. “Ìwọ ọba, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo fún Nebukadnessari baba rẹ ní ìjọba, títóbi ògo àti ọlá. Nítorí ipò ńlá tí a fi fún un, gbogbo ènìyàn orílẹ̀-èdè àti èdè gbogbo fi ń páyà tí wọ́n sì ń bẹ̀rù rẹ̀. Ó ń pa àwọn tí ó bá wù ú, ó sì ń dá àwọn tí ó bá wù ú sí, ó ń gbé àwọn tí ó bá wù ú ga, ó sì ń rẹ àwọn tí ó bá wù ú sílẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn rẹ̀ ga, tí ó sì le koko. Ó bẹ̀rẹ̀ sí i hùwà ìgbéraga, a mú u kúrò lórí ìtẹ́ ọba rẹ̀, a sì gba ògo rẹ̀ kúrò. A lé e kúrò láàrín ènìyàn, a sì fún un ní ọkàn ẹranko; ó sì ń gbé pẹ̀lú àwọn kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, ó sì ń jẹ koríko bí i ti màlúù; ìrì ọ̀run ṣì sẹ̀ sí ara rẹ̀, títí tó fi mọ̀ pé, Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo ń jẹ ọba lórí ìjọba ọmọ ènìyàn, òun sì ń fi fún ẹni tí ó bá wù ú. “Ṣùgbọ́n ìwọ ọmọ rẹ̀, Belṣassari, ìwọ kò rẹ ara à rẹ sílẹ̀, bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé ìwọ mọ nǹkan wọ̀nyí. Dípò èyí, ìwọ gbé ara à rẹ ga sí Olúwa ọ̀run, a mú ohun èlò inú tẹmpili rẹ̀ wá sí iwájú rẹ, ìwọ àti àwọn ìjòyè rẹ, àwọn ìyàwó ò rẹ àti àwọn àlè rẹ fi ń mu wáìnì. Ìwọ ń yin àwọn òrìṣà fàdákà àti wúrà, idẹ, irin, igi àti ti òkúta, èyí tí kò lè ríran, tí kò le è gbọ́rọ̀ tàbí ní òye nǹkan kan. Ṣùgbọ́n ìwọ kò bu ọlá fún Ọlọ́run ẹni tó ni ẹ̀mí rẹ lọ́wọ́, tí ó sì mọ gbogbo ọ̀nà rẹ.