Dan 5:1-9
Dan 5:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
BELṢASSARI, ọba se àse nla fun ẹgbẹrun awọn ijoye rẹ̀, o si nmu ọti-waini niwaju awọn ẹgbẹrun na. Bi Belṣassari ti tọ́ ọti-waini na wò, o paṣẹ pe ki nwọn ki o mu ohun-elo wura, ati ti fadaka wá, eyiti Nebukadnessari baba rẹ̀, kó jade lati inu tempili ti o wà ni Jerusalemu wá, ki ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, ki o le ma muti ninu wọn. Nigbana ni nwọn mu ohun-elo wura ti a ti kó jade lati inu tempili ile Ọlọrun ti o wà ni Jerusalemu wá; ọba, ati awọn ijoye rẹ̀, awọn aya rẹ̀, ati awọn àle rẹ̀, si nmuti ninu wọn. Nwọn nmu ọti-waini, nwọn si nkọrin ìyin si awọn oriṣa wura, ati ti fadaka, ti idẹ, ti irin, ti igi, ati ti okuta. Ni wakati kanna ni awọn ika ọwọ enia kan jade wá, a si kọwe sara ẹfun ogiri niwaju ọpa-fitila li ãfin ọba: ọba si ri ọwọ ti o kọwe na. Nigbana ni oju ọba yipada, ìro-inu rẹ̀ si dãmu rẹ̀, tobẹ̃ ti amure ẹ̀gbẹ rẹ̀ tu, ẽkunsẹ̀ rẹ̀ mejeji si nlù ara wọn. Ọba si kigbe kikan pe, ki a mu awọn amoye, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá. Ọba dahùn o si wi fun awọn ọlọgbọ́n Babeli, pe, Ẹnikan ti o ba kà iwe yi, ti o ba si fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi, on li a o fi aṣọ ododó wọ̀, a o si fi ẹ̀wọn wura kọ̀ ọ li ọrùn, on o si jẹ ẹkẹta olori ni ijọba. Nigbana ni gbogbo awọn amoye ọba wọle; ṣugbọn nwọn kò le kà iwe na, nwọn kò si le fi itumọ rẹ̀ hàn fun ọba. Nigbana ni ẹ̀ru nla ba Belṣassari ọba gidigidi, oju rẹ̀ si yipada lori rẹ̀, ẹ̀ru si ba awọn ijoye rẹ̀.
Dan 5:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọjọ́ kan, Beṣasari ọba, se àsè ńlá kan fún ẹgbẹrun (1,000) ninu àwọn ìjòyè rẹ̀, ó sì ń mu ọtí níwájú wọn. Nígbà tí ó tọ́ ọtí náà wò, ó pàṣẹ pé kí wọn kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí Nebukadinesari, baba rẹ̀, kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, kí òun, ati àwọn ìjòyè òun, àwọn ayaba ati àwọn obinrin òun lè máa fi wọ́n mu ọtí. Wọ́n bá kó àwọn ife wúrà ati ti fadaka tí wọ́n kó ninu tẹmpili ní Jerusalẹmu jáde, wọ́n sì bẹ̀rẹ̀ sí fi wọ́n mu ọtí. Bí wọn tí ń mu ọtí, ni wọ́n ń yin ère wúrà, ère fadaka, ère irin, ère igi, ati ère òkúta. Lẹsẹkẹsẹ, ọwọ́ kan bẹ̀rẹ̀ sí kọ̀wé sí ara ògiri ààfin níbi tí iná fìtílà tan ìmọ́lẹ̀ sí, ọba rí ọwọ́ náà, bí ó ti ń kọ̀wé. Ojú ọba yipada, ẹ̀rù bà á, ara rẹ̀ ń gbọ̀n, orúnkún rẹ̀ sì ń lu ara wọn. Ó kígbe sókè pé kí wọ́n tètè lọ pe àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea ati àwọn awòràwọ̀ wá. Nígbà tí wọ́n dé, ọba sọ fún wọn pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka ohun tí wọ́n kọ sára ògiri yìí, tí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, n óo fi aṣọ elése àlùkò dá a lọ́lá, n óo ní kí wọ́n fi ẹ̀gbà wúrà sí i lọ́rùn, yóo sì wà ní ipò kẹta sí ọba ninu ìjọba mi.” Gbogbo àwọn amòye ọba wá, wọn kò lè ka àwọn àkọsílẹ̀ náà, wọn kò sì lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Ọkàn Beṣasari dàrú, ojú rẹ̀ yipada. Àwọn ìjòyè rẹ̀ dààmú, wọn kò sì mọ ohun tí wọ́n lè ṣe.
Dan 5:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Belṣassari, ọba ṣe àsè ńlá fún ẹgbẹ̀rún (1,000) kan nínú àwọn ọlọ́lá rẹ̀, ó sì mu wáìnì pẹ̀lú u wọn. Bí Belṣassari ṣe ń mu wáìnì, ó pàṣẹ pé kí wọn kó kọ́ọ̀bù wúrà àti ti fàdákà wá, èyí tí Nebukadnessari baba rẹ̀ kó wá láti inú tẹmpili ní Jerusalẹmu, kí ọba àti àwọn ọlọ́lá rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀ kí ó ba à le fi mu wáìnì. Wọ́n sì kó kọ́ọ̀bù wúrà àti fàdákà àti fàdákà èyí tí wọ́n kó jáde láti inú tẹmpili, ilé Ọlọ́run ní Jerusalẹmu, ọba àti àwọn ìjòyè rẹ̀, àwọn ìyàwó àti àwọn àlè rẹ̀, sì fi mu wáìnì. Bí wọ́n ṣe ń mu wáìnì bẹ́ẹ̀ ni wọ́n ń yin òrìṣà wúrà àti fàdákà, ti idẹ, irin, igi àti òkúta. Lójijì, ìka ọwọ́ ènìyàn jáde wá, ó sì ń kọ̀wé sára ẹfun ògiri ní ẹ̀gbẹ́ ibi tí fìtílà ń dúró ní ààfin ọba. Ọba ń wo ọwọ́ náà bí ó ṣe ń kọ ọ́. Ojú ọba sì yí padà, ẹ̀rù sì bà á, tó bẹ́ẹ̀ tí orúnkún ẹsẹ̀ rẹ̀ méjèèjì rẹ̀ fi ń gbá ara wọn. Ọba kígbe pé, kí wọn pe àwọn awòràwọ̀, àwọn onídán, àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, ọba sì sọ fún àwọn amòye Babeli pé, “Ẹnikẹ́ni tí ó bá lè ka àkọsílẹ̀ yìí kí ó sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀, ẹni náà ni a ó fi aṣọ elése àlùkò wọ̀ àti ẹ̀gbà wúrà ni a ó fi sí ọrùn un rẹ̀, òun ni yóò sì ṣe olórí kẹta ní ìjọba à mi.” Nígbà náà ni gbogbo àwọn amòye ọba wọ ilé, ṣùgbọ́n, wọn kò le è ka àkọsílẹ̀ náà tàbí sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún ọba. Nígbà náà ni Belṣassari ọba bínú gidigidi, ojú u rẹ̀ sì túbọ̀ dàrú sí i. Ẹ̀rù sì ba àwọn ìjòyè Belṣassari.