Dan 4:5-18
Dan 4:5-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.) Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Èyí ni ìran náà tí mo rí nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, mo rí igi kan láàrín ayé, igi náà ga gidigidi. Igi náà tóbi, ó sì lágbára, orí rẹ̀ sì ń kan ọ̀run; a sì rí i títí dé òpin ayé. Ewé rẹ̀ lẹ́wà, èso rẹ̀ sì pọ̀, ó sì ń pèsè oúnjẹ fún gbogbo ènìyàn. Abẹ́ ẹ rẹ̀ ni àwọn ẹranko igbó fi ṣe ibùgbé, àwọn ẹyẹ ojú ọ̀run sì ń gbé ní ẹ̀ka rẹ̀, nínú rẹ̀ ni gbogbo alààyè ti ń jẹ. “Lórí ibùsùn mi, mo rí ìran náà, olùṣọ́ kan dúró síwájú u mi, àní ẹni mímọ́ kan, ó ń bọ̀ wá láti ọ̀run ó kígbe sókè wí pé, ‘Gé igi náà kí o sì gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò; gbọn ewé rẹ̀ ká, kí o sì fọ́n èso rẹ̀ dànù. Jẹ́ kí àwọn ẹranko tí ó wà lábẹ́ rẹ̀ sá àti àwọn ẹyẹ tí ó wà ní ẹ̀ka rẹ̀ kúrò. Ṣùgbọ́n fi kùkùté àti gbòǹgbò rẹ̀ tí a fi irin àti idẹ dè ṣẹ́kù sórí ilẹ̀ àti sí orí koríko igbó. “ ‘Jẹ́ kí ìrì ọ̀run sẹ̀ sí i lára, kí ó sì jẹ́ kí ìpín in rẹ̀ wà pẹ̀lú àwọn ẹranko igbó láàrín ilẹ̀ ayé. Jẹ́ kí ọkàn rẹ̀ kí ó yí padà kúrò ní ti ènìyàn, kí a sì fún un ní ọkàn ẹranko, títí ìgbà méje yóò fi kọjá lórí i rẹ̀. “ ‘Olùṣọ́ ni ó gbé ìpinnu náà jáde, àṣẹ sì wá láti ọ̀dọ̀ ẹni mímọ́, kí gbogbo alààyè le mọ̀ wí pé, Ọ̀gá-ògo ni olórí ìjọba ènìyàn, ó sì ń fi fún ẹnikẹ́ni tí ó wù ú, òun sì ń gbé onírẹ̀lẹ̀ lórí i wọn.’ “Èyí ni àlá tí èmi Nebukadnessari ọba lá. Ní ìsinsin yìí ìwọ Belṣassari, sọ ohun tí ó túmọ̀ sí fún mi, nítorí kò sí amòye kan ní ìjọba mi, tí ó lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣùgbọ́n ìwọ lè sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí tí ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà ní inú rẹ.”
Dan 4:5-18 Bibeli Mimọ (YBCV)
Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi. Nitorina ni mo ṣe paṣẹ lati mu gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli wá niwaju mi, ki nwọn ki o le fi itumọ alá na hàn fun mi. Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi. Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe, Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀. Bayi ni iran ori mi lori akete mi; mo ri, si kiyesi i, igi kan duro li arin aiye, giga rẹ̀ si pọ̀ gidigidi. Igi na si dagba, o si lagbara, giga rẹ̀ si kan ọrun, a si ri i titi de gbogbo opin aiye. Ewe rẹ̀ lẹwa, eso rẹ̀ si pọ̀, lara rẹ̀ li onjẹ wà fun gbogbo aiye: abẹ rẹ̀ jẹ iboji fun awọn ẹranko igbẹ, ati lori ẹka rẹ̀ li awọn ẹiyẹ oju-ọrun ngbe, ati lati ọdọ rẹ̀ li a si ti mbọ gbogbo ẹran-ara. Mo ri ninu iran ori mi lori akete mi, si kiye si i, oluṣọ, ani ẹni mimọ́ kan sọkalẹ lati ọrun wá; O kigbe li ohùn rara, o si wi bayi pe, Ke igi na lulẹ, ki o si ke awọn ẹka rẹ̀ kuro, gbọ̀n ewe rẹ̀ danu; ki o si fọn eso rẹ̀ ka, jẹ ki awọn ẹranko igbẹ kuro labẹ rẹ̀, ki awọn ẹiyẹ si kuro lori ẹka rẹ̀: Ṣugbọn, fi kukute gbòngbo rẹ̀ silẹ ninu ilẹ, ani pẹlu ide ninu irin ati idẹ ninu koriko tutu igbẹ; si jẹ ki ìri ọrun sẹ̀ si i lara, ki o si ni ipin rẹ̀ ninu koriko ilẹ aiye pẹlu awọn ẹranko: Ki a si pa aiya rẹ̀ da kuro ni ti enia, ki a si fi aiya ẹranko fun u, ki igba meje ki o si kọja lori rẹ̀. Nipa ọ̀rọ lati ọdọ awọn oluṣọ li ọ̀ran yi, ati aṣẹ nipa ọ̀rọ awọn ẹni mimọ́ nì; nitori ki awọn alàye ki o le mọ̀ pe Ọga-ogo li o nṣe olori ni ijọba enia, on a si fi fun ẹnikẹni ti o wù u, on a si gbé onirẹlẹ julọ leke lori rẹ̀. Alá yi li emi Nebukadnessari lá, njẹ nisisiyi, iwọ Belteṣassari, sọ itumọ rẹ̀ fun mi, bi gbogbo awọn ọlọgbọ́n ijọba mi kò ti le fi itumọ rẹ̀ hàn fun mi: ṣugbọn iwọ le ṣe e; nitori ẹmi Ọlọrun mimọ́ mbẹ lara rẹ.
Dan 4:5-18 Yoruba Bible (YCE)
Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi. Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní: Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi. “Nígbà tí mo sùn, mo rí igi kan láàrin ayé, lójú ìran, igi náà ga lọpọlọpọ. Igi náà bẹ̀rẹ̀ sí tóbi, ó sì lágbára; orí rẹ̀ kan ojú ọ̀run, kò sí ibi tí wọn kò ti lè rí i ní gbogbo ayé. Ewé rẹ̀ lẹ́wà, ó so jìnwìnnì, oúnjẹ wà lórí rẹ̀ fún gbogbo eniyan, abẹ́ rẹ̀ ni àwọn ẹranko ń gbé, orí àwọn ẹ̀ka rẹ̀ sì ni àwọn ẹyẹ ń sùn. Èso rẹ̀ ni gbogbo ẹ̀dá alààyè ń jẹ. “Ní ojúran, lórí ibùsùn mi, mo rí olùṣọ́ kan, Ẹni Mímọ́, ó kígbe sókè pé, ‘Gé igi náà lulẹ̀, gé àwọn ẹ̀ka rẹ̀ kúrò, gbọn gbogbo ewé ati èso rẹ̀ dànù; kí àwọn ẹranko sá kúrò lábẹ́ rẹ̀, kí àwọn ẹyẹ sì fò kúrò lórí ẹ̀ka rẹ̀. Ṣugbọn fi kùkùté, ati gbòǹgbò rẹ̀ sílẹ̀ ninu ìdè irin ati ti idẹ ninu pápá. “ ‘Jẹ́ kí ìrì sẹ̀ sí i lára, kí ó máa bá àwọn ẹranko jẹ koríko; kí ọkàn rẹ̀ sì yipada kúrò ní ọkàn eniyan sí ti ẹranko fún ọdún meje. Láti ọ̀dọ̀ àwọn olùṣọ́ ni ìdájọ́ yìí ti wá, ìpinnu náà jẹ́ ti àwọn Ẹni Mímọ́; kí gbogbo àwọn ẹ̀dá alààyè lè mọ̀ pé Ẹni Gíga Jùlọ ní àṣẹ lórí ìjọba eniyan, ẹnikẹ́ni tí ó bá sì wù ú níí máa gbé ìjọba lé lọ́wọ́, pàápàá láàrin àwọn ẹni tí ó rẹlẹ̀ jùlọ.’ “Ìran tí èmi Nebukadinesari rí nìyí. Ìwọ Beteṣasari, sọ ìtumọ̀ rẹ̀, nítorí gbogbo àwọn ọlọ́gbọ́n ìjọba mi kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Ṣugbọn o lè ṣe é, nítorí pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ.”