Dan 4:34-37
Dan 4:34-37 Bibeli Mimọ (YBCV)
Li opin igba na, Emi Nebukadnessari si gbé oju mi soke si ọrun, oye mi si pada tọ̀ mi wá, emi si fi ibukún fun Ọga-ogo, mo yìn, mo si fi ọla fun ẹniti o wà titi lailai, ẹniti agbara ijọba rẹ̀ jẹ ijọba ainipẹkun, agbara ati ijọba rẹ̀ lati irandiran. Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì? Lakoko kanna oye mi pada tọ̀ mi wá; ati niti ogo ijọba mi, ọlá ati ogo didan mi si pada wá sọdọ mi: awọn ìgbimọ ati awọn ijoye mi si ṣafẹri mi; a si fi ẹsẹ mi mulẹ ninu ijọba mi, emi si ni ọlanla agbara jù ti iṣaju lọ. Nisisiyi, emi Nebukadnessari yìn, mo si gbé Ọba ọrun ga, mo si fi ọlá fun u, ẹniti gbogbo iṣẹ rẹ̀ iṣe otitọ, ati gbogbo ọ̀na rẹ̀ iṣe idajọ: ati awọn ti nrìn ninu igberaga, on le rẹ̀ wọn silẹ.
Dan 4:34-37 Yoruba Bible (YCE)
Nebukadinesari ní, “Lẹ́yìn ọdún meje náà, èmi, Nebukadinesari, gbé ojú sí òkè ọ̀run, iyè mi pada bọ̀ sípò. Mo yin Ẹni Gíga Jùlọ, mo fi ọlá ati ògo fún Ẹni Ayérayé. “Ìjọba ayérayé ni ìjọba rẹ̀ láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀, àní, láti ìrandíran ni ìjọba rẹ̀. Gbogbo aráyé kò jámọ́ nǹkankan lójú rẹ̀; a sì máa ṣe bí ó ti wù ú láàrin àwọn aráyé ati láàrin àwọn ogun ọ̀run. Kò sí ẹni tí ó lè ká a lọ́wọ́ kò, tabi tí ó lè yẹ̀ ẹ́ lọ́wọ́ wò. “Ní àkókò gan-an tí iyè mi pada bọ̀ sípò, ògo, ọlá, ati iyì ìjọba mi náà sì tún pada sọ́dọ̀ mi. Àwọn ìgbìmọ̀ ati àwọn ìjòyè mi wá mi kàn, wọ́n gbà mí tọwọ́ tẹsẹ̀, ìjọba mi tún fi ìdí múlẹ̀, mo sì níyì ju ti àtẹ̀yìnwá lọ ní gbogbo ọ̀nà. “Ẹ gbọ́, èmi Nebukadinesari, fi ìyìn, ògo, ati ọlá fún ọba ọ̀run. Nítorí pé gbogbo iṣẹ́ rẹ̀ pé, ọ̀nà rẹ̀ tọ́, ó sì lè rẹ àwọn agbéraga sílẹ̀.”
Dan 4:34-37 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní òpin ìgbà náà, Èmi, Nebukadnessari gbé ojú mi sókè sí ọ̀run, iyè mi sì sọjí. Mo fi ọpẹ́ fún Ọ̀gá-ògo; mo fi ọlá àti ògo fún ẹni tí ó wà láéláé. Ìjọba rẹ̀ ìjọba títí ayé ni ìjọba rẹ̀ wà láti ìran dé ìran Gbogbo àwọn ènìyàn ayé ni a kà sí asán. Ó ń ṣe bí ó ti wù ú, pẹ̀lú àwọn ogun ọ̀run, àti gbogbo àwọn ènìyàn ayé tí kò sì ṣí ẹnìkankan tí ó lè dí i lọ́wọ́ tàbí sọ fún un wí pé: “Kí ni ìwọ ń ṣe?” Ní àkókò kan náà, iyè mi padà, ọlá àti ògo dídán mi padà tọ̀ mí wá fún ògo ìjọba mi. Àwọn ìgbìmọ̀ àti àwọn ọlọ́lá mi, wá mi rí, wọ́n sì dá mi padà sórí ìjọba mi, mo sì di alágbára ju ti ìṣáájú lọ. Báyìí, èmi, Nebukadnessari fi ọpẹ́, mo sì gbé Ọlọ́run ga, mo sì fi ògo fún ọba ọ̀run, nítorí pé gbogbo nǹkan tí ó ṣe ló dára, gbogbo ọ̀nà rẹ̀ sì tọ́. Gbogbo àwọn tó sì ń rìn ní ìgbéraga ni ó le rẹ̀ sílẹ̀.