Dan 4:1-9
Dan 4:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn. Ami rẹ̀ ti tobi to! agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ ti pọ̀ to! ijọba ainipẹkun ni ijọba rẹ̀, ati agbara ijọba rẹ̀ ati irandiran ni. Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi: Mo si lá alá kan ti o dẹ̀ruba mi, ati ìro ọkàn mi lori akete mi, ati iran ori mi dãmu mi. Nitorina ni mo ṣe paṣẹ lati mu gbogbo awọn ọlọgbọ́n Babeli wá niwaju mi, ki nwọn ki o le fi itumọ alá na hàn fun mi. Nigbana ni awọn amoye, ọlọgbọ́n, awọn Kaldea, ati awọn alafọṣẹ wá siwaju mi: emi si rọ́ alá na fun wọn, ṣugbọn nwọn kò le fi ìtumọ rẹ̀ hàn fun mi. Ṣugbọn nikẹhin ni Danieli wá siwaju mi, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari, gẹgẹ bi orukọ oriṣa mi, ati ninu ẹniti ẹmi Ọlọrun mimọ́ wà: mo si rọ́ alá na fun u pe, Belteṣassari, olori awọn amoye, nitoriti mo mọ̀ pe ẹmi Ọlọrun mimọ mbẹ ninu rẹ, kò si si aṣiri kan ti o ṣoro fun ọ, sọ iran alá ti mo lá fun mi, ati itumọ rẹ̀.
Dan 4:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn. “Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an! Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ! Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀, àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba. “Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi. Mo lá àlá kan tí ó bà mí lẹ́rù. Èrò ọkàn mi ati ìran tí mo rí lórí ibùsùn mi kó ìdààmú bá mi. Nítorí náà, mo pàṣẹ pé kí wọ́n kó gbogbo àwọn ọ̀jọ̀gbọ́n Babiloni wá sọ́dọ̀ mi, kí wọ́n wá túmọ̀ àlá náà fún mi. Gbogbo àwọn pidánpidán, ati àwọn aláfọ̀ṣẹ, àwọn ará Kalidea, ati àwọn awòràwọ̀ bá péjọ siwaju mi; mo rọ́ àlá náà fún wọn, ṣugbọn wọn kò lè túmọ̀ rẹ̀ fún mi. Lẹ́yìn gbogbo wọn patapata ni Daniẹli dé, tí a sọ ní Beteṣasari, orúkọ oriṣa mi, Daniẹli yìí ní ẹ̀mí Ọlọrun ninu. Mo rọ́ àlá mi fún un, mo ní: Beteṣasari, olórí gbogbo àwọn pidánpidán, mo mọ̀ pé ẹ̀mí Ọlọrun mímọ́ wà ninu rẹ, ati pé o mọ gbogbo àṣírí. Gbọ́ àlá mi kí o sì sọ ìtumọ̀ rẹ̀ fún mi.
Dan 4:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nebukadnessari ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé: Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn. Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó, Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni. Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà. Mo lá àlá kan èyí tí ó bà mí lẹ́rù. Nígbà tí mo wà lórí ibùsùn mi, ìran tí ó jáde lọ́kàn mi dẹ́rùbà mí. Nígbà náà, ni mo pàṣẹ pé kí a mú gbogbo àwọn amòye Babeli wá, kí wọn wá sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Nígbà tí àwọn apidán, àwọn apògèdè, àwọn awòràwọ̀ àti àwọn aláfọ̀ṣẹ wá, mo sọ àlá náà fún wọn, ṣùgbọ́n wọn kò le è sọ ìtumọ̀ àlá náà fún mi. Ní ìkẹyìn Daniẹli wá síwájú mi, mo sì sọ àlá náà fún (ẹni tí à ń pè ní Belṣassari gẹ́gẹ́ bí orúkọ òrìṣà mi àti pé ẹ̀mí àwọn Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ̀.) Mo wí pé, “Belṣassari, olórí àwọn amòye, èmi mọ̀ wí pé ẹ̀mí Ọlọ́run mímọ́ wà nínú rẹ, kò sì ṣí àṣírí kan tí ó ṣòro jù fún ọ. Sọ àlá mi kí o sì túmọ̀ rẹ̀ fún mi.