Dan 4:1-4
Dan 4:1-4 Bibeli Mimọ (YBCV)
NEBUKADNESSARI ọba, si gbogbo enia, orilẹ, ati ède, ti o ngbe gbogbo agbaiye; ki alafia ki o ma pọ̀ si i fun nyin. O tọ loju mi lati fi àmi ati iṣẹ iyanu ti Ọlọrun, Ọga-ogo, ti ṣe si mi hàn. Ami rẹ̀ ti tobi to! agbara iṣẹ iyanu rẹ̀ ti pọ̀ to! ijọba ainipẹkun ni ijọba rẹ̀, ati agbara ijọba rẹ̀ ati irandiran ni. Emi Nebukadnessari wà li alafia ni ile mi, mo si ngbilẹ li ãfin mi
Dan 4:1-4 Yoruba Bible (YCE)
Ọba Babiloni ranṣẹ sí gbogbo àwọn eniyan, ati gbogbo orílẹ̀-èdè ati ẹ̀yà ní gbogbo ayé, pé: “Kí alaafia wà pẹlu yín! Ó tọ́ lójú mi láti fi àmì ati iṣẹ́ ìyanu, tí Ọlọrun tí ó ga jùlọ ṣe fún mi, hàn. “Iṣẹ́ rẹ̀ tóbi gan-an! Iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ sì lágbára lọpọlọpọ! Títí ayérayé ni ìjọba rẹ̀, àtìrandíran rẹ̀ ni yóo sì máa jọba. “Èmi, Nebukadinesari wà ninu ìdẹ̀ra ní ààfin mi, nǹkan sì ń dára fún mi.
Dan 4:1-4 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nebukadnessari ọba, Sí gbogbo ènìyàn, orílẹ̀ àti onírúurú èdè, tí ó ń gbé ní àgbáyé: Kí àlàáfíà máa pọ̀ sí i fún un yín. Kí ẹ ṣe rere tó pọ̀! Ó jẹ́ ìdùnnú fún mi láti fi iṣẹ́ ààmì àti ìyanu tí Ọlọ́run Ọ̀gá-Ògo ti ṣe fún mi hàn. Báwo ni ààmì rẹ̀ ti tóbi tó, Báwo ni ìyanu rẹ̀ ṣe pọ̀ tó! Ìjọba rẹ̀, ìjọba títí ayé ni; ilẹ̀ ọba rẹ̀ láti ìran dé ìran ni. Èmi Nebukadnessari wà ní ààfin mi, pẹ̀lú ìtẹ́lọ́rùn àti àlàáfíà.