Dan 2:27-28
Dan 2:27-28 Bibeli Mimọ (YBCV)
Danieli si dahùn niwaju ọba, o si wipe, Aṣiri ti ọba mbère, awọn ọlọgbọ́n, awọn oṣó, awọn amoye, ati awọn alafọṣẹ, kò le fi hàn fun ọba. Ṣugbọn Ọlọrun kan mbẹ li ọrun ti o nfi aṣiri hàn, ẹniti o si fi hàn fun Nebukadnessari ohun ti mbọ wá ṣe ni ikẹhin ọjọ. Alá rẹ, ati iran ori rẹ lori akete rẹ, ni wọnyi
Dan 2:27-28 Yoruba Bible (YCE)
Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí ọlọ́gbọ́n kan, tabi aláfọ̀ṣẹ, tabi pidánpidán, tabi awòràwọ̀ tí ó lè sọ àṣírí ìjìnlẹ̀ ọ̀rọ̀ tí ọba ń bèèrè yìí fún un. Ṣugbọn Ọlọrun kan ń bẹ ní ọ̀run, tí ń fi àṣírí nǹkan ìjìnlẹ̀ hàn. Òun ni ó fi ohun tí yóo ṣẹlẹ̀ lẹ́yìn ọ̀la han Nebukadinesari ọba. Àlá tí o lá, ati ìran tí o rí ní orí ibùsùn rẹ nìyí
Dan 2:27-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Daniẹli dá ọba lóhùn pé, “Kò sí awòràwọ̀ kan, apògèdè, onídán tàbí aláfọ̀ṣẹ tí ó lè ṣe àlàyé àṣírí tí ọba béèrè fún ṣùgbọ́n, Ọlọ́run kan ń bẹ ní ọ̀run tí ó ń fi àṣírí hàn. Ó ti fihan ọba Nebukadnessari, ohun tí yóò ṣẹlẹ̀ ní ìkẹyìn ọjọ́. Àlá àti ìran tí o rí nígbà tí o dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ ni ìwọ̀nyí