Dan 12:1-13
Dan 12:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI akoko na ni Mikaeli, balogun nla nì, ti yio gbeja awọn ọmọ awọn enia rẹ yio dide, akokò wahala yio si wà, iru eyi ti kò ti isi ri, lati igba ti orilẹ-ède ti wà titi fi di igba akokò yi, ati ni igba akokò na li a o gbà awọn enia rẹ la, ani gbogbo awọn ti a ti kọ orukọ wọn sinu iwe. Ati ọ̀pọlọpọ ninu awọn ti o sùn ninu erupẹ ilẹ ni yio ji, awọn miran si ìye ainipẹkun, ati awọn miran si itiju ati ẹ̀gan ainipẹkun. Awọn ọlọgbọ́n yio si ma tàn bi imọlẹ ofurufu: awọn ti o si nyi ọ̀pọlọpọ pada si ododo yio si ma tàn bi irawọ̀ lai ati lailai. Ṣugbọn iwọ, Danieli sé ọ̀rọ na mọhun, ki o si fi edidi di iwe na, titi fi di igba ikẹhin: ọ̀pọlọpọ ni yio ma wadi rẹ̀, ìmọ yio si di pupọ. Nigbana ni emi Danieli wò, si kiyesi i, awọn meji miran si duro: ọ̀kan lapa ihín eti odò, ati ekeji lapa ọhún eti odò. Ẹnikan si wi fun ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla ti o duro lori omi odò pe, opin ohun iyanu wọnyi yio ti pẹ to? Emi si gbọ́, ọkunrin na ti o wọ̀ aṣọ àla, ti o duro loju omi odò na, o gbé ọwọ ọtún ati ọwọ òsi rẹ̀ si ọrun, o si fi Ẹniti o wà titi lai nì bura pe, yio jẹ akokò kan, awọn akokò, ati ãbọ akokò; nigbati yio si ti ṣe aṣepe ifunka awọn enia mimọ́, gbogbo nkan wọnyi li a o si pari. Emi si gbọ́, ṣugbọn kò ye mi: nigbana ni mo wipe, Oluwa mi, kini yio ṣe ikẹhin wọnyi? O si wipe, Ma ba ọ̀na rẹ lọ, Danieli, nitoriti a ti se ọ̀rọ na mọ sọhún, a si fi edidi di i titi fi di igba ikẹhin. Ọ̀pọlọpọ li a o wẹ̀ mọ́, nwọn o si di funfun, a o si dan wọn wò: ṣugbọn awọn ẹni-buburu yio ma ṣe buburu: gbogbo awọn enia buburu kì yio kiyesi i; ṣugbọn awọn ọlọgbọ́n ni yio kiyesi i. Ati lati igba akokò ti a o mu ẹbọ ojojumọ kuro, ati lati gbé irira isọdahoro kalẹ, yio jẹ ẹgbẹrun ati igba le ãdọrun ọjọ. Ibukún ni fun ẹniti o duro dè, ti o si de ẹgbẹrun, ati ọdurun le marundilogoji ọjọ nì. Ṣugbọn iwọ ma ba ọ̀na rẹ lọ, titi opin yio fi de, iwọ o si simi, iwọ o si dide duro ni ipo rẹ ni ikẹhin ọjọ.
Dan 12:1-13 Yoruba Bible (YCE)
Angẹli tí ó wọ aṣọ funfun náà ní, “Ní àkókò náà Mikaeli, aláṣẹ ńlá, tí ń dáàbò bo àwọn eniyan rẹ, yóo dìde. Àkókò ìyọnu yóo dé, irú èyí tí kò tíì sí rí láti ọjọ́ tí aláyé ti dáyé; ṣugbọn a óo gba gbogbo àwọn eniyan rẹ, tí a bá kọ orúkọ wọn sinu ìwé náà là. Ọ̀pọ̀ ninu àwọn tí ó ti kú, tí wọ́n ti sin ni yóo jí dìde, àwọn kan óo jí sí ìyè ainipẹkun, àwọn mìíràn óo sì jí sí ìtìjú ati ẹ̀sín ainipẹkun. Àwọn ọlọ́gbọ́n yóo máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ojú ọ̀run, àwọn tí wọn ń yí eniyan pada sí ọ̀nà òdodo yóo máa tàn bí ìràwọ̀ lae ati títí lae.” Ó ní, “Ṣugbọn ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé, kí o sì fi èdìdì dì í títí di àkókò ìkẹyìn. Nítorí àwọn eniyan yóo máa sá síhìn-ín, sá sọ́hùn-ún, ìmọ̀ yóo sì pọ̀ sí i.” Nígbà náà ni mo rí i tí àwọn meji dúró létí bèbè odò kan, ọ̀kan lápá ìhín, ọ̀kan lápá ọ̀hún. Ọ̀kan ninu wọn bi ẹni tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò pé, “Nígbà wo ni àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ tí ń bani lẹ́rù wọnyi yóo dópin?” Ọkunrin tí ó wọ aṣọ funfun, tí ó wà lókè odò na ọwọ́ rẹ̀ mejeeji sókè ọ̀run, mo sì gbọ́ tí ó fi orúkọ ẹni tí ó wà láàyè títí lae búra pé, “Ọdún mẹta ààbọ̀ ni yóo jẹ́. Nígbà tí wọn bá gba agbára lọ́wọ́ àwọn eniyan Ọlọrun patapata, ni gbogbo nǹkan wọnyi yóo ṣẹlẹ̀.” Mo gbọ́ tí ó ń sọ̀rọ̀, ṣugbọn ohun tí ń sọ kò yé mi. Mo bá bèèrè pé, “Olúwa mi, níbo ni nǹkan wọnyi yóo yọrí sí?” Ó dáhùn pé, “Ìwọ Daniẹli, máa bá tìrẹ lọ, nítorí a ti pa ọ̀rọ̀ yìí mọ́, a sì ti fi èdìdì dì í, títí di àkókò ìkẹyìn. Ọ̀pọ̀ eniyan ni yóo wẹ ara wọn mọ́, tí wọn yóo sọ ara wọn di funfun, wọn yóo sì mọ́; ṣugbọn àwọn ẹni ibi yóo máa ṣe ibi; kò ní sí ẹni ibi tí òye yóo yé; ṣugbọn yóo yé àwọn ọlọ́gbọ́n. “Láti ìgbà tí wọn yóo mú ẹbọ ojoojumọ kúrò, tí wọn yóo gbé ohun ìríra sí ibi mímọ́, yóo jẹ́ eedegbeje ọjọ́ ó dín ọjọ́ mẹ́wàá (1,290). Ayọ̀ ń bẹ fún ẹni tí ó bá forítì í ní gbogbo eedegbeje ọjọ́ ó lé ọjọ́ marundinlogoji (1,335) náà. “Ṣugbọn, ìwọ Daniẹli, máa ṣe tìrẹ lọ títí dé òpin. O óo lọ sí ibi ìsinmi, ṣugbọn lọ́jọ́ ìkẹyìn, o óo dìde nílẹ̀ o óo sì gba ìpín tìrẹ tí a ti fi sílẹ̀ fún ọ.”
Dan 12:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ní àkókò náà, ni Mikaeli, ọmọ-aládé ńlá, ẹni tí o ń dáàbò bo àwọn ènìyàn an rẹ̀ yóò dìde. Àkókò ìpọ́njú yóò wà, irú èyí tí kò tí ì ṣẹlẹ̀ rí láti ìbẹ̀rẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè títí di àkókò náà. Ṣùgbọ́n ní àkókò náà àwọn ènìyàn rẹ̀, gbogbo àwọn tí a bá ti rí orúkọ wọn nínú ìwé ni a ó gbàlà. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ àwọn tí ó sùn nínú erùpẹ̀ ilẹ̀ ni yóò jí: àwọn mìíràn sí ìyè àìnípẹ̀kun, àwọn tókù sí ìtìjú àti sí ẹ̀gàn àìnípẹ̀kun. Àwọn tí ó jẹ́ ọlọ́gbọ́n yóò máa tàn bí ìmọ́lẹ̀ ọ̀run, àti àwọn tí ó ń tọ́nisọ́nà sí òdodo, yóò máa tàn bí ìràwọ̀ láé àti láéláé. Ṣùgbọ́n ìwọ Daniẹli, pa ìwé náà dé kí o sì pa ọ̀rọ̀ ọ rẹ̀ mọ́ títí àkókò ìgbẹ̀yìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ yóò máa lọ sí ìhín sí ọ̀hún láti jẹ́ kí ìmọ̀ wọn di púpọ̀.” Nígbà náà, ni èmi Daniẹli, wò, ní iwájú mi àwọn méjì mìíràn dúró, ọ̀kan dúró sí apá ìhín ní etí bèbè odò ẹnìkan náà ní apá òdìkejì ọ̀hún etí i bèbè. Ọ̀kan lára wọn sọ fún ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò pé, “Báwo ni yóò ṣe pẹ́ tó kí àwọn nǹkan ìyanu wọ̀nyí tó wá sí ìmúṣẹ?” Ọkùnrin tí ó wọ aṣọ àlà, ẹni tí ó wà lórí omi odò, gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti ọwọ́ òsì rẹ̀, mo gbọ́ tí ó fi ẹni tí ó wà títí láé búra, ó sọ wí pé, “Yóò ṣe ní àkókò kan, àkókò méjì àti ààbọ̀. Nígbà tí agbára àwọn ẹni mímọ́ yóò ti fọ́ tán pátápátá, gbogbo nǹkan wọ̀nyí yóò sì parí.” Èmi gbọ́, ṣùgbọ́n kò yé mi. Nígbà náà ni mo béèrè pé, “Olúwa mi, kí ni yóò jẹ́ àbábọ̀ àwọn nǹkan wọ̀nyí?” Ó sì dáhùn pé, “Máa lọ ní ọ̀nà rẹ, Daniẹli nítorí tí a ti pa ọ̀rọ̀ náà dé, a sì ti fi èdìdì dì í di ìgbà ìkẹyìn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni a ó fọ̀ mọ́, wọn yóò wà láìlábàwọ́n, a ó sì tún wọn ṣe, ṣùgbọ́n àwọn ẹni búburú yóò máa ṣe búburú lọ, kò sí ẹni búburú tí òye yóò yé ṣùgbọ́n òye yóò yé àwọn ọlọ́gbọ́n. “Láti àkókò tí a ó mú ẹbọ ojoojúmọ́ kúrò, tí a ó sì gbé ìríra tí ó ń fa ìsọdahoro kalẹ̀ yóò sì jẹ́ ẹgbẹ̀rún àti igba lé àádọ́rùn-ún ọjọ́ (1,290). Ìbùkún ni fún ẹni tí ó dúró, ti ó sì di òpin ẹgbẹ̀rún àti ọ̀ọ́dúnrún lé àrùndínlógójì ọjọ́ (1,335). “Ṣùgbọ́n ìwọ, máa lọ ní ọ̀nà rẹ, títí di òpin. Ìwọ yóò sinmi, àti ní òpin ọjọ́ ìwọ yóò dìde láti gba èrè rẹ.”