Dan 11:31-32
Dan 11:31-32 Bibeli Mimọ (YBCV)
Agbara ogun yio si duro li apa tirẹ̀, nwọn o si sọ ibi mimọ́, ani ilu olodi na di aimọ́, nwọn o si mu ẹbọ ojojumọ kuro, nwọn o si gbé irira isọdahoro nì kalẹ. Ati iru awọn ti nṣe buburu si majẹmu nì ni yio fi ọ̀rọ ipọnni mu ṣọ̀tẹ: ṣugbọn awọn enia ti o mọ̀ Ọlọrun yio mu ọkàn le, nwọn o si ma ṣe iṣẹ agbara.
Dan 11:31-32 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ogun rẹ̀ yóo wá, wọn yóo sọ Tẹmpili ati ibi ààbò di aláìmọ́, wọn yóo dáwọ́ ẹbọ sísun ìgbà gbogbo dúró, wọn yóo sì gbé ohun ìríra tíí fa ìsọdahoro kalẹ̀. Pẹlu ẹ̀tàn, ọba yìí yóo mú àwọn tí wọ́n kọ majẹmu náà sílẹ̀ lọ́rẹ̀ẹ́; ṣugbọn àwọn tí wọ́n mọ Ọlọrun yóo dúró ṣinṣin, wọn óo sì ṣe ẹ̀tọ́.
Dan 11:31-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Agbára ọmọ-ogun rẹ̀ yóò dìde láti ba ohun mímọ́ ilé olódi tẹmpili jẹ́, yóò sì pa ẹbọ ojoojúmọ́ rẹ́. Nígbà náà ni wọn yóò gbé ìríra tí ó fa ìsọdahoro kalẹ̀. Pẹ̀lú irú àwọn tí ń ṣe búburú sí májẹ̀mú ní yóò fi ọ̀rọ̀ ìpọ́nni mú ṣọ̀tẹ̀, ṣùgbọ́n, àwọn tí ó mọ Ọlọ́run wọn yóò mú ọkàn le. Wọn yóò sì máa ṣe iṣẹ́ agbára.