Dan 10:1-3
Dan 10:1-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
LI ọdun kẹta Kirusi, ọba Persia, li a fi ọ̀rọ kan hàn fun Danieli, orukọ ẹniti ijẹ Belteṣassari; otitọ li ọ̀rọ na, ati lãla na tobi, o si mọ̀ ọ̀rọ na, o si moye iran na. Li ọjọ wọnni li emi Danieli fi ikãnu ṣọ̀fọ li ọ̀sẹ mẹta gbako. Emi kò jẹ onjẹ ti o dara, bẹ̃ni kò si si ẹran tabi ọti-waini ti o wá si ẹnu mi, bẹ̃li emi kò fi ororo kùn ara mi rara, titi ọ̀sẹ mẹta na fi pe.
Dan 10:1-3 Yoruba Bible (YCE)
Ní ọdún kẹta tí Kirusi jọba ní Pasia, Daniẹli, (tí à ń pè ní Beteṣasari) rí ìran kan. Òtítọ́ ni ìran náà, ó ṣòro láti túmọ̀, ṣugbọn a la ìran náà ati ìtumọ̀ rẹ̀ yé Daniẹli. Ní àkókò náà, èmi Daniẹli ń ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹta. N kò jẹ oúnjẹ aládùn, n kò jẹran, n kò mu ọtí, n kò sì fi òróró para ní odidi ọ̀sẹ̀ mẹtẹẹta náà.
Dan 10:1-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ní ọdún kẹta Kirusi ọba Persia, a fi ìran kan hàn Daniẹli (ẹni tí à ń pè ní Belteṣassari). Òtítọ́ ni ọ̀rọ̀ ìran náà, ó sì ní í ṣe pẹ̀lú àsìkò ìpọ́njú ńlá, òye ọ̀rọ̀ náà wá bá a nínú ìran. Ní àsìkò náà, èmi Daniẹli ṣọ̀fọ̀ fún ọ̀sẹ̀ mẹ́ta. Èmi kì í jẹ oúnjẹ tí ó dára, èmi kò fi ẹran tàbí wáìnì kan ẹnu mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kò fi òróró para títí ọ̀sẹ̀ mẹ́ta fi kọjá.