Dan 1:1-21

Dan 1:1-21 Bibeli Mimọ (YBCV)

LI ọdun kẹta ijọba Jehoiakimu, ọba Juda ni Nebukadnessari, ọba Babeli, wá si Jerusalemu, o si do tì i. Oluwa si fi Jehoiakimu, ọba Juda le e lọwọ, pẹlu apakan ohun-elo ile Ọlọrun, ti o kó lọ si ilẹ Ṣinari, si ile oriṣa rẹ̀: o si kó ohun-elo na wá sinu ile-iṣura oriṣa rẹ̀. Ọba si wi fun Aṣpenasi, olori awọn iwẹfa rẹ̀, pe, ki o mu awọn kan wá ninu awọn ọmọ Israeli, ninu iru-ọmọ ọba, ati ti awọn ijoye; Awọn ọmọ ti kò lẹgan lara, ṣugbọn awọn ti o ṣe arẹwa, ti o si ni ìmọ ninu ọgbọ́n gbogbo, ti o mọ̀ oye, ti o si ni iyè ninu, ati iru awọn ti o yẹ lati duro li ãfin ọba ati awọn ti a ba ma kọ́ ni iwe ati ede awọn ara Kaldea. Ọba si pese onjẹ wọn ojojumọ ninu adidùn ọba ati ninu ọti-waini ti o nmu: ki a bọ wọn bẹ̃ li ọdun mẹta, pe, li opin rẹ̀, ki nwọn ki o le duro niwaju ọba. Njẹ ninu awọn wọnyi ni Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah, lati inu awọn ọmọ Juda: Awọn ẹniti olori awọn iwẹfa si fi orukọ fun: bẹ̃li o pè Danieli ni Belteṣassari, ati Hananiah ni Ṣadraki; ati Miṣaeli ni Méṣaki; ati Asariah ni Abednego. Ṣugbọn Danieli pinnu rẹ̀ li ọkàn rẹ̀ pe, on kì yio fi onjẹ adidùn ọba, ati ọti-waini ti o nmu ba ara on jẹ: nitorina o bẹ̀ olori awọn iwẹfa pe, ki on má ba ba ara on jẹ. Ọlọrun sa ti mu Danieli ba ojurere ati iyọ́nu pade lọdọ olori awọn iwẹfa. Olori awọn iwẹfa si wi fun Danieli pe, Mo bẹ̀ru ọba, oluwa mi, ẹniti o yàn onjẹ nyin ati ohun mimu nyin: nitori bawo li on o ṣe ri oju nyin ki o faro jù ti awọn ọmọkunrin ẹgbẹ nyin kanna lọ? nigbana li ẹnyin o ṣe ki emi ki o fi ori mi wewu lọdọ ọba. Nigbana ni Danieli wi fun olutọju ti olori awọn iwẹfa fi ṣe oluṣọ Danieli, Hananiah, Miṣaeli, ati Asariah pe, Dán awọn ọmọ-ọdọ rẹ wò, emi bẹ̀ ọ, ni ijọ mẹwa; ki o si jẹ ki nwọn ki o ma fi ẹ̀wa fun wa lati jẹ, ati omi lati mu. Nigbana ni ki a wò oju wa niwaju rẹ, ati oju awọn ọmọ ti njẹ onjẹ adidùn ọba: bi iwọ ba si ti ri i si, bẹ̃ni ki o ṣe si awọn ọmọ-ọdọ rẹ. Bẹ̃li o gbà fun wọn li ọ̀ran yi, o si dan wọn wò ni ijọ mẹwa. Li opin ọjọ mẹwa, a ri oju wọn lẹwa, nwọn si sanra jù gbogbo awọn ti njẹ onjẹ adidùn ọba lọ. Bẹ̃ni olutọju mu onjẹ adidùn wọn kuro, ati ọti-waini ti nwọn iba mu, o si fun wọn li ẹ̀wa. Bi o ṣe ti awọn ọmọ mẹrẹrin wọnyi ni, Ọlọrun fun wọn ni ìmọ ati oye ni gbogbo iwe ati ọgbọ́n: Danieli si li oye ni gbogbo iran ati alá. Nigbati o si di opin ọjọ ti ọba ti da pe ki a mu wọn wá, nigbana ni olori awọn iwẹfa mu wọn wá siwaju Nebukadnessari. Ọba si ba wọn sọ̀rọ: ninu gbogbo wọn, kò si si ẹniti o dabi Danieli, Hananiah, Miṣaeli ati Asariah: nitorina ni nwọn fi nduro niwaju ọba. Ati ninu gbogbo ọ̀ran ọgbọ́n ati oye, ti ọba mbère lọwọ wọn, o ri pe ni iwọn igba mẹwa, nwọn sàn jù gbogbo awọn amoye ati ọlọgbọ́n ti o wà ni gbogbo ilẹ ijọba rẹ̀ lọ. Danieli si wà sibẹ titi di ọdun ikini ti Kirusi, ọba.

Dan 1:1-21 Yoruba Bible (YCE)

Ní ọdún kẹta ìjọba Jehoiakimu ọba Juda, Nebukadinesari ọba Babiloni wá gbógun ti Jerusalẹmu, ó sì dótì í. OLUWA jẹ́ kí ọwọ́ rẹ̀ tẹ Jehoiakimu ọba Juda. Nebukadinesari kó ninu àwọn ohun èlò ilé Ọlọrun lọ sí ilẹ̀ Ṣinari, ó sì kó wọn sinu ilé ìṣúra tí ó wà ninu ilé oriṣa rẹ̀. Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà rẹ̀ pé kí ó lọ sí ààrin àwọn ọmọ ọba ati àwọn eniyan pataki pataki ninu àwọn ọmọ Israẹli, kí ó ṣa àwọn ọ̀dọ́ tí wọn kò ní àbùkù lára, àwọn tí wọ́n lẹ́wà, tí wọ́n sì jẹ́ ọlọ́gbọ́n lọ́nà gbogbo, tí wọ́n ní ẹ̀bùn ìmọ̀, ati òye ẹ̀kọ́, tí wọ́n lè ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba, kí á sì kọ́ wọn ní ìmọ̀ ati èdè àwọn ará Kalidea. Ọba ṣètò pé kí wọn máa gbé oúnjẹ aládùn pẹlu ọtí waini fún wọn lára oúnjẹ ati ọtí waini ti òun alára. Wọn óo kẹ́kọ̀ọ́ fún ọdún mẹta, lẹ́yìn náà, wọn óo máa ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ ọba. Daniẹli, ati Hananaya, ati Miṣaeli ati Asaraya wà lára àwọn tí wọ́n ṣà ninu ẹ̀yà Juda. Olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ ẹnìkọ̀ọ̀kan wọn ní orúkọ titun: Ó sọ Daniẹli ní Beteṣasari, ó sọ Hananaya ní Ṣadiraki, ó sọ Miṣaeli ní Meṣaki, ó sì sọ Asaraya ni Abedinego. Daniẹli pinnu pé òun kò ní fi oúnjẹ aládùn tí ọba ń jẹ, tabi ọtí tí ó ń mu sọ ara òun di aláìmọ́. Nítorí náà, ó lọ bẹ Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ọba, pé kí ó gba òun láàyè kí òun má sọ ara òun di aláìmọ́. Ọlọrun jẹ́ kí Daniẹli bá ojurere ati àánú olórí àwọn ìwẹ̀fà náà pàdé. Ṣugbọn Aṣipenasi sọ fún Daniẹli, pé, ẹ̀rù ń ba òun, kí ọba tí ó ṣètò jíjẹ ati mímu Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ má baà lọ ṣe akiyesi pé Daniẹli rù ju àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ lọ, kí òun má baà fi ẹ̀mí òun wéwu lọ́dọ̀ ọba. Nítorí náà, Daniẹli sọ fún ẹni tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn láti máa tọ́jú òun ati àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ mẹtẹẹta pé, “Dán àwa iranṣẹ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá, máa fún wa ní ẹ̀wà jẹ, kí o sì máa fún wa ní omi lásán mu. Lẹ́yìn náà, kí o wá fi wá wé àwọn tí wọn ń jẹ lára oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ, bí o bá ti wá rí àwa iranṣẹ rẹ sí ni kí o ṣe ṣe sí wa.” Ó gba ohun tí wọ́n wí, ó sì dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwaa, ojú wọn rẹwà, wọ́n sì sanra ju gbogbo àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn tí ń jẹ oúnjẹ àdídùn tí ọba ń jẹ lọ. Nítorí náà, ẹni tí ń tọ́jú wọn bẹ̀rẹ̀ sí fún wọn ní ẹ̀wà, dípò oúnjẹ aládùn tí wọn ìbá máa jẹ ati ọtí tí wọn ìbá máa mu. Ọlọrun fún àwọn ọdọmọkunrin mẹrẹẹrin yìí ní ọgbọ́n, ìmọ̀, ati òye; Daniẹli sì ní ìmọ̀ láti túmọ̀ ìran ati àlá. Nígbà tí ó tó àkókò tí ọba ti pàṣẹ pé kí wọ́n kó wọn wá, olórí ìwẹ̀fà kó gbogbo wọn wá siwaju rẹ̀. Ọba pè wọ́n, ó dán wọn wò, ninu gbogbo wọn, kò sì sí ẹni tí ó dàbí Daniẹli, Hananaya, Miṣaeli ati Asaraya. Nítorí náà, wọ́n fi Daniẹli ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ sí ọ̀dọ̀ ọba ní ààfin. Ninu gbogbo ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ati ìmọ̀ tí ọba bi wọ́n, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn pidánpidán ati àwọn aláfọ̀ṣẹ tí ó wà ní ìjọba rẹ̀ lọ. Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kinni ìjọba Kirusi.

Dan 1:1-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ní ọdún kẹta tí Jehoiakimu jẹ ọba Juda, Nebukadnessari ọba Babeli wá sí Jerusalẹmu, ó sì kọlù ú pẹ̀lú àwọn ọmọ-ogun rẹ̀. Olúwa sì fa Jehoiakimu ọba Juda lé e lọ́wọ́, pẹ̀lú àwọn ohun èlò ilé Ọlọ́run. Àwọn nǹkan wọ̀nyí ni ó kó lọ sí ilé òrìṣà ní Babeli, sí inú ilé ìṣúra òrìṣà rẹ̀. Nígbà náà ni ọba pàṣẹ fún Aṣipenasi, olórí àwọn ìwẹ̀fà ààfin rẹ̀ pé, kí ó mú nínú àwọn ọmọ Israẹli tí wọ́n wá láti ìdílé ọba àti lára àwọn tí ó wá láti ilé ọlá. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí kò ní àbùkù ara, tí wọ́n rẹwà, tí wọ́n sì fi ìfẹ́ sí ẹ̀kọ́ hàn, tí wọ́n sì ní ìmọ̀, tí òye tètè ń yé àti àwọn tí ó kún ojú òṣùwọ̀n láti ṣiṣẹ́ ní ààfin ọba kí ó kọ́ wọ́n ní èdè àti onírúurú ẹ̀kọ́ ìwé ti àwọn Babeli. Ọba pèsè oúnjẹ ojoojúmọ́ àti wáìnì láti orí tábìlì i rẹ̀ fún wọn, ó sì kọ́ wọn fún ọdún mẹ́ta. Lẹ́yìn náà ni wọn yóò bẹ̀rẹ̀ sí í ṣiṣẹ́ fún ọba. Lára àwọn wọ̀nyí ni àwọn tó wá láti Juda: Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah. Olórí àwọn ìwẹ̀fà fún wọn ní orúkọ tuntun: Ó fún Daniẹli ní Belteṣassari, ó fún Hananiah ní Ṣadraki, ó fún Miṣaeli ní Meṣaki àti Asariah ní Abednego. Ṣùgbọ́n Daniẹli pinnu ní ọkàn ara rẹ̀ pé òun kò ní ba ara òun jẹ́ pẹ̀lú oúnjẹ àti wáìnì ọba, nígbà náà ni ó gba ààyè lọ́wọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà wí pé òun kò fẹ́ ba ara òun jẹ́ ní ọ̀nà yìí. Ọlọ́run mú kí Daniẹli rí ojúrere àti àánú gbà láti ọwọ́ olórí àwọn ìwẹ̀fà, Ṣùgbọ́n olórí àwọn ìwẹ̀fà sọ fún Daniẹli pé, “Mo bẹ̀rù olúwa mi, ẹni tí o ti pèsè oúnjẹ àti ohun mímu rẹ. Báwo ni ìrísí rẹ yóò ṣe burú jù ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin ẹlẹgbẹ́ ẹ̀ rẹ lọ? Nígbà náà ni èmi yóò fi orí mi wéwu lọ́dọ̀ ọba.” Nígbà náà ni Daniẹli sọ fún olùṣọ́ tí olórí àwọn ìwẹ̀fà yàn lórí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah pé, Jọ̀wọ́ dán àwa ìránṣẹ́ rẹ wò fún ọjọ́ mẹ́wàá: Má ṣe fún wa ní ohun kankan, àfi ewébẹ̀ láti jẹ àti omi láti mu. Nígbà náà ni kí o fi ìrísí i wa wé ti àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba, kí o sì ṣe àwa ìránṣẹ́ rẹ ní ìbámu pẹ̀lú u bí o bá ṣe rí i sí. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì gbà láti dán wọn wò fún ọjọ́ mẹ́wàá. Lẹ́yìn ọjọ́ kẹwàá ara wọn le, wọ́n sì sanra ju àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin tí wọ́n ń jẹ oúnjẹ ọba lọ. Bẹ́ẹ̀ ni olùṣọ́ mú oúnjẹ àdídùn àti wáìnì tí ó yẹ kí wọ́n mu kúrò, ó sì fún wọn ní ewébẹ̀ dípò rẹ̀. Ọlọ́run fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin mẹ́rẹ̀ẹ̀rin wọ̀nyí ní ìmọ̀ àti òye nínú gbogbo onírúurú ìwé àti ẹ̀kọ́ ọ wọn: Daniẹli sì ní òye ìran àti àlá ní oríṣìíríṣìí. Ní òpin ìgbà tí ọba dá, pé kí a mú wọn wá sínú ààfin, olórí àwọn ìwẹ̀fà mú wọn wá síwájú ọba Nebukadnessari. Ọba sì bá wọn sọ̀rọ̀, ó sì rí i pé kò sí ẹni tí ó dàbí i Daniẹli, Hananiah, Miṣaeli àti Asariah; Nítorí náà wọ́n bẹ̀rẹ̀ sí ní ṣe iṣẹ́ ọba. Nínú gbogbo ọ̀ràn ọgbọ́n àti òye tí ọba ń béèrè lọ́wọ́ wọn, ó rí i pé wọ́n sàn ní ìlọ́po mẹ́wàá ju gbogbo àwọn amòye àti ọlọ́gbọ́n tí ó wà ní gbogbo ìjọba rẹ̀. Daniẹli sì wà níbẹ̀ títí di ọdún kìn-ín-ní ọba Kirusi.