Kol 4:3-6
Kol 4:3-6 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ju gbogbo rẹ̀, ẹ mã gbadura fun wa pẹlu, ki Ọlọrun le ṣí ilẹkun fun wa fun ọrọ na, lati mã sọ ohun ijinlẹ Kristi, nitori eyiti mo ṣe wà ninu ìde pẹlu: Ki emi ki o le fihan, gẹgẹ bi o ti tọ́ fun mi lati mã sọ. Ẹ mã rìn nipa ọgbọ́n si awọn ti mbẹ lode, ki ẹ si mã ṣe ìrapada ìgba. Ẹ jẹ ki ọ̀rọ nyin ki o dàpọ mọ́ ore-ọfẹ nigbagbogbo, eyiti a fi iyọ̀ dùn, ki ẹnyin ki o le mọ̀ bi ẹnyin ó ti mã dá olukuluku enia lohùn.
Kol 4:3-6 Yoruba Bible (YCE)
Ẹ tún máa gbadura fún wa, pé kí Ọlọrun lè ṣí ìlẹ̀kùn iwaasu fún wa, kí á lè sọ ìjìnlẹ̀ àṣírí Kristi. Nítorí èyí ni mo fi wà ninu ẹ̀wọ̀n. Kí ẹ gbadura pé kí n lè ṣe àlàyé bí ó ti yẹ. Ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín pẹlu ọgbọ́n níwájú àwọn alaigbagbọ. Ẹ má ṣe jẹ́ kí àkókò kan kọjá láìjẹ́ pé ẹ lò ó bí ó ti yẹ. Ọ̀rọ̀ ọmọlúwàbí ni kí ó máa ti ẹnu yín jáde nígbà gbogbo, ọ̀rọ̀ tí ó bá etí mu, kí ẹ lè mọ bí ó ti yẹ láti dá ẹnikẹ́ni tí ẹ bá ń bá sọ̀rọ̀ lóhùn.
Kol 4:3-6 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ẹ máa gbàdúrà fún wa pẹ̀lú, kí Ọlọ́run lè ṣí ìlẹ̀kùn fún wa fún ọ̀rọ̀ náà, láti máa sọ ohun ìjìnlẹ̀ Kristi, nítorí èyí tí mo ṣe wà nínú ìdè pẹ̀lú: Ẹ gbàdúrà pé kí èmi le è máa kéde rẹ̀ kedere gẹ́gẹ́ bí ó ti tọ́ fún mi. Ẹ jẹ́ ọlọ́gbọ́n ní ti bí ẹ ti ń ṣe pẹ̀lú àwọn tí ń bẹ lóde, kí ẹ sì máa ṣe ṣí àǹfààní tí ẹ bá nílò. Ẹ jẹ́ kí ọ̀rọ̀ yín kí ó dàpọ̀ mọ́ oore-ọ̀fẹ́ nígbà gbogbo, èyí tí a fi iyọ̀ dùn, kí ẹ̀yin kí ó le mọ́ bí ẹ̀yin ó tí máa dá olúkúlùkù ènìyàn lóhùn.