Kol 2:2-3
Kol 2:2-3 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ki a le tu ọkàn wọn ninu, bi a ti so wọn pọ̀ ninu ifẹ ati si gbogbo ọrọ̀ ẹ̀kún oye ti o daju, si imọ̀ ohun ijinlẹ Ọlọrun ani Kristi; Inu ẹniti a ti fi gbogbo iṣura ọgbọ́n ati ti ìmọ pamọ́ si.
Pín
Kà Kol 2Kol 2:2-3 Yoruba Bible (YCE)
Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí.
Pín
Kà Kol 2Kol 2:2-3 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀. Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí.
Pín
Kà Kol 2