Kol 2:1-8
Kol 2:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NITORI emi nfẹ ki ẹnyin ki o mọ̀ bi iwaya-ìja ti mo ni fun nyin ti pọ̀ to, ati fun awọn ará Laodikea, ati fun iye awọn ti kò ti iri oju mi nipa ti ara; Ki a le tu ọkàn wọn ninu, bi a ti so wọn pọ̀ ninu ifẹ ati si gbogbo ọrọ̀ ẹ̀kún oye ti o daju, si imọ̀ ohun ijinlẹ Ọlọrun ani Kristi; Inu ẹniti a ti fi gbogbo iṣura ọgbọ́n ati ti ìmọ pamọ́ si. Eyi ni mo si nwi, ki ẹnikẹni ki o má bã fi ọ̀rọ ẹtàn mu nyin ṣina. Nitoripe bi emi kò tilẹ si lọdọ nyin li ara, ṣugbọn emi mbẹ lọdọ nyin li ẹmí, mo nyọ̀, mo si nkiyesi eto nyin, ati iduroṣinṣin igbagbọ́ nyin ninu Kristi. Nitorina bi ẹnyin ti gbà Kristi Jesu Oluwa, bẹ̃ni ki ẹ mã rìn ninu rẹ̀: Ki ẹ fi gbongbo mulẹ, ki a si gbe nyin ro ninu rẹ̀, ki ẹ si fi ẹsẹ mulẹ ninu igbagbọ nyin, gẹgẹ bi a ti kọ́ nyin, ki ẹ si mã pọ̀ ninu rẹ̀ pẹlu idupẹ. Ẹ mã kiyesara ki ẹnikẹni ki o máṣe fi ìmọ ati ẹ̀tan asan dì nyin ni igbekun, gẹgẹ bi itan enia, gẹgẹ bi ipilẹṣẹ ẹkọ aiye, ti ki iṣe bi ti Kristi.
Kol 2:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Nítorí mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń ṣe akitiyan tó nítorí yín ati nítorí àwọn tí ó wà ní Laodikia ati nítorí àwọn tí kò mọ̀ mí sójú. Ìdí akitiyan mi ni pé kí Ọlọrun lè mu yín ní ọkàn le, kí ó so yín pọ̀ ninu ìfẹ́ ati ọrọ̀ òye tí ó dájú, kí ẹ sì ní ìmọ̀ ìjìnlẹ̀ àṣírí Ọlọrun, tíí ṣe Kristi fúnrarẹ̀. Ninu Kristi ni Ọlọrun fi gbogbo ìṣúra ọgbọ́n ati ìmọ̀ pamọ́ sí. Mò ń sọ èyí kí ẹnikẹ́ni má baà fi ọ̀rọ̀ dídùn tàn yín jẹ. Nítorí bí n kò tilẹ̀ sí lọ́dọ̀ yín nípa ti ara, sibẹ mo wà pẹlu yín ninu ẹ̀mí. Mo láyọ̀ nígbà tí mo rí ètò tí ó wà láàrin yín ati bí igbagbọ yín ti dúró ninu Kristi. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí ẹ ti gba Kristi Jesu bí Oluwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ máa gbé ìgbé-ayé yín ni ìrẹ́pọ̀ pẹlu rẹ̀. Kí ẹ fẹsẹ̀ múlẹ̀, kí ẹ máa dàgbà ninu rẹ̀, kí ẹ sì jẹ́ kí igbagbọ yín dúró ṣinṣin bí ẹ ti kọ́ láti ṣe, kí ẹ máa dúpẹ́ nígbà gbogbo. Ẹ ṣọ́ra kí ẹnikẹ́ni má ṣe fi ọ̀rọ̀ ọgbọ́n ayé ati ìtànjẹ lásán sọ yín di ẹrú gẹ́gẹ́ bí àṣà eniyan, ati ìlànà àwọn ẹ̀mí tí a kò fi ojú rí, tí ó yàtọ̀ sí ètò ti Kristi.
Kol 2:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Mo fẹ́ kí ẹ mọ bí mo ti ń jìjàkadì fún un yín àti fún àwọn ará Laodikea àti fún ọ̀pọ̀ ènìyàn mìíràn tí wọn kò ì tí ì rí mi sójú rí. Ohun tí mo ń béèrè lọ́wọ́ Ọlọ́run fún un yín nínú àdúrà mi ni pé, kí a lè mú yín lọ́kàn le, kí a sì lè so yín pọ̀ pẹ̀lú ìfẹ́ to lágbára, kí ẹ le ní àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run lẹ́kùnrẹ́rẹ́. Àṣírí ìjìnlẹ̀ Ọlọ́run náà ni Kristi fúnrarẹ̀. Nínú ẹni tí a fi gbogbo ìṣúra ìjìnlẹ̀ ọgbọ́n àti ìmọ̀ pamọ́ sí. Mo sọ èyí fún un yín kí ẹnikẹ́ni ma ba à fi ọ̀rọ̀ ẹ̀tàn mú yín ṣìnà. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé èmi kò sí i lọ́dọ̀ yín nínú ara, ṣùgbọ́n mo wà lọ́dọ̀ yín nínú ẹ̀mí, bẹ́ẹ̀ ni mo sì ń yọ̀ láti kíyèsi ètò yín àti bí ìdúró ṣinṣin yín nínú Kristi ti rí. Nítorí náà, bí ẹ̀yin ti gba Jesu Kristi gẹ́gẹ́ bí Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni kí ẹ̀yin máa gbé nínú rẹ̀. Ẹ fi gbòǹgbò múlẹ̀, kí a sì gbé yín ró nínú rẹ̀, kí ẹ sì fi ẹsẹ̀ múlẹ̀ nínú ìgbàgbọ́ yín, bí a ti kọ́ yín, àti kí ẹ sì máa pọ̀ nínú rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́. Ẹ rí dájú pé ẹnikẹ́ni kò mú yin ní ìgbèkùn pẹ̀lú ẹ̀kọ́ àròsọ àti ìmọ̀ ẹ̀tàn, èyí tí ó gbára lé ìlànà ti ènìyàn àti àgbékalẹ̀ àwọn ẹ̀mí ayé yìí tí ó yàtọ̀ sí ti Kristi.