Kol 1:1-10

Kol 1:1-10 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Paulu, aposteli Jesu Kristi nípa ìfẹ́ Ọlọ́run àti Timotiu arákùnrin wa. Sí àwọn ẹni mímọ́ àti àwọn arákùnrin àti arábìnrin nínú Kristi tí wọ́n ń gbé ní ìlú Kolose. Oore-ọ̀fẹ́ àti àlàáfíà fún un yín láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run Baba wa. Nígbàkúgbà tí a bá ń gbàdúrà fún un yín ni a máa ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run Baba Olúwa wa Jesu Kristi. Nítorí a ti gbúròó ìgbàgbọ́ yín nínú Jesu Kristi, àti bí ẹ ti ṣe fẹ́ràn gbogbo àwọn ènìyàn mímọ́. Ìgbàgbọ́ àti ìfẹ́ tí ń sàn nínú ìrètí tí a gbé pamọ́ fún un yín ní ọ̀run èyí tí ẹ̀yin sì ti gbọ́ tẹ́lẹ̀ nínú ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìhìnrere náà, èyí tí ó ti dé ọ̀dọ̀ yín. Káàkiri àgbáyé ni ìhìnrere yìí ń so èso tí ó sì ń dàgbà, gẹ́gẹ́ bí ó ti ń ṣe láàrín yín láti ọjọ́ náà tí ẹ ti gbọ́ ọ, tí ẹ sì ní ìmọ̀ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run nínú gbogbo òtítọ́ rẹ̀. Ẹ̀yin ti kọ́ ọ lọ́dọ̀ Epafira, ìránṣẹ́ ẹlẹgbẹ́ wa olùfẹ́, ẹni tí ó jẹ́ olóòtítọ́ ìránṣẹ́ Kristi ní ipò wa. Ẹni ti ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín nínú ẹ̀mí. Nítorí ìdí èyí, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ nípa yín, a kò sinmi láti máa gbàdúrà fún yin, tí a sì ń gbàdúrà pé kí Ọlọ́run fi ìmọ̀ ìfẹ́ rẹ̀ kún yín nípasẹ̀ ọgbọ́n àti òye gbogbo tí ń ṣe ti Ẹ̀mí. Àwa sì ń gbàdúrà yìí kí ẹ lè gbé irú ìgbé ayé tó yẹ fún Olúwa kí ẹ sì máa wu ú ní gbogbo ọ̀nà, kí ẹ sì máa so èso rere gbogbo, kí ẹ sì máa dàgbà nínú ìmọ̀ Ọlọ́run

Kol 1:1-10 Yoruba Bible (YCE)

Èmi Paulu, aposteli Kristi Jesu, nípa ìfẹ́ Ọlọrun, ati Timoti arakunrin wa, àwa ni à ń kọ ìwé yìí– Sí ìjọ eniyan Ọlọrun tí ó wà ní Kolose, sí àwọn arakunrin tí ó jẹ́ olóòótọ́ sí Kristi. Kí oore-ọ̀fẹ́ ati alaafia láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun Baba wa kí ó wà pẹlu yín. À ń dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun, Baba Oluwa wa, Jesu Kristi, nígbà gbogbo tí a bá ń gbadura fun yín. A ti gbúròó igbagbọ yín ninu Kristi Jesu ati ìfẹ́ tí ẹ ní sí gbogbo àwọn eniyan Ọlọrun. Ìrètí tí ó wà fun yín ni ọ̀run, tí ẹ gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ òtítọ́ ìyìn rere, ni orísun igbagbọ ati ìfẹ́ yín. Ìyìn rere yìí ti dé ọ̀dọ̀ yín gẹ́gẹ́ bí ó ti dé ọ̀dọ̀ gbogbo aráyé, ó ń so èso, ó sì ń dàgbà. Bẹ́ẹ̀ ni ó sì rí láàrin ẹ̀yin náà láti ọjọ́ tí ẹ ti gbọ́, tí ẹ sì ti mọ oore-ọ̀fẹ́ Ọlọrun nítòótọ́. Bẹ́ẹ̀ ni ẹ ti kọ́ ọ̀rọ̀ ìyìn rere lọ́dọ̀ Epafirasi, àyànfẹ́, alábàáṣiṣẹ́pọ̀ wa. Òun ni ó sọ fún wa nípa ìfẹ́ yín ninu nǹkan ti ẹ̀mí. Nítorí náà, láti ọjọ́ tí a ti gbọ́ ìròyìn yín, àwa náà kò sinmi láti máa gbadura fun yín. À ń bẹ̀bẹ̀ pé kí Ọlọrun lè jẹ́ kí ẹ mọ ìfẹ́ rẹ̀ lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́ pẹlu gbogbo ọgbọ́n, kí ó sì fun yín ní òye nípa nǹkan ti ẹ̀mí. A tún ń gbadura pé kí ìgbé-ayé yín lè jẹ́ èyí tí ó wu Oluwa lọ́nà gbogbo, kí iṣẹ́ rere yín máa pọ̀ sí i, kí ẹ máa tẹ̀síwájú ninu ìmọ̀ Ọlọrun.