Amo 6:1-14

Amo 6:1-14 Bibeli Mimọ (YBCV)

EGBE ni fun ẹniti ara rọ̀ ni Sioni, ati awọn ti o gbẹkẹ̀le oke nla Samaria, awọn ti a pè ni ikini ninu awọn orilẹ-ède, awọn ti ile Israeli tọ̀ wá! Ẹ kọja si Kalne, si wò; ẹ si ti ibẹ̀ lọ si Hamati nla: lẹhìn na ẹ sọ̀kalẹ lọ si Gati ti awọn Filistini: nwọn ha san jù ilẹ ọba wọnyi lọ? tabi agbègbe wọn ha tobi jù agbègbe nyin lọ? Ẹnyin ti o sún ọjọ ibi siwaju, ti ẹ si mu ibùgbe ìwa-ipá sunmọ tòsi; Awọn ti o ndùbulẹ lori akete ehin-erin, ti nwọn si nnà ara wọn lori irọ̀gbọku wọn, ti nwọn njẹ ọdọ-agùtan inu agbo, ati ẹgbọ̀rọ malu inu agbo; Ti nwáhùn si iró orin fioli, ti nwọn si nṣe ohun-ikọrin fun ara wọn, bi Dafidi; Awọn ti nmuti ninu ọpọ́n waini, ti nwọn si nfi olori ororo kun ara wọn; ṣugbọn nwọn kò banujẹ nitori ipọnju Josefu. Nitorina awọn ni o lọ si igbèkun pẹlu awọn ti o ti kọ́ lọ si igbèkun; àse awọn ti nṣe aṣeleke li a o mu kuro. Oluwa Ọlọrun ti fi ara rẹ̀ bura, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ ogun wi, Emi korira ọlanla Jakobu, mo si korira ãfin rẹ̀: nitorina li emi o ṣe fi ilu na, ati ohun gbogbo ti o wà ninu rẹ̀ tọrẹ. Yio si ṣe, bi enia mẹwa li o ba kù ninu ile kan, nwọn o si kú. Ati arakunrin rẹ̀, ati ẹniti o nfi i joná, lati kó egungun wọnni jade kuro ninu ile, yio gbe e, yio si bi ẹniti o wà li ẹba ile lere pe, O ha tun kù ẹnikan pẹlu rẹ? On o si wipe, Bẹ̃kọ̀. Nigbana li on o wipe, Pa ẹnu rẹ mọ: nitoripe awa kò gbọdọ da orukọ Oluwa. Nitori kiyesi i, Oluwa paṣẹ, yio si fi iparun kọlù ile nla na, ati aisàn kọlù ile kékèké. Ẹṣin ha le ma sure lori apata? ẹnikan ha le fi akọ malu ṣiṣẹ ìtulẹ̀ nibẹ̀? nitoriti ẹnyin ti yi idajọ dà si oró, ati eso ododo dà si iwọ: Ẹnyin ti nyọ̀ si ohun asan, ti nwipe, Nipa agbara ara wa kọ́ li awa fi gbà iwo fun ara wa? Ṣugbọn kiyesi i, emi o gbe orilẹ-ède kan dide si nyin, ẹnyin ile Israeli, li Oluwa Ọlọrun awọn ọmọ-ogun wi; nwọn o si pọ́n nyin loju lati iwọle Hamati, titi de odò pẹ̀tẹlẹ.

Amo 6:1-14 Yoruba Bible (YCE)

Ègbé ni fún àwọn tí wọ́n wà ninu ìdẹ̀ra ní Sioni, ati àwọn tí wọn ń gbé orí òkè Samaria láìléwu, àwọn eniyan ńláńlá ní Israẹli, tí ó jẹ́ àkọ́kọ́ láàrin àwọn orílẹ̀-èdè, àwọn tí àwọn eniyan gbójúlé. Ẹ lọ wo ìlú Kane; ẹ ti ibẹ̀ lọ sí Hamati, ìlú ńlá nì, lẹ́yìn náà ẹ lọ sí ìlú Gati, ní ilẹ̀ àwọn ará Filistia. Ṣé wọ́n sàn ju àwọn orílẹ̀-èdè yín lọ ni? Tabi agbègbè wọn tóbi ju tiyín lọ? Ẹ kò fẹ́ gbà pé ọjọ́ ibi ti súnmọ́ tòsí; ṣugbọn ẹ̀ ń ṣe nǹkan tí yóo mú kí ọjọ́ ẹ̀rù tètè dé. Àwọn tí ń sùn sórí ibùsùn tí wọ́n fi eyín erin ṣe gbé! Àwọn tí wọ́n nà kalẹ̀ lórí ìrọ̀gbọ̀kú wọn, tí wọn ń jẹ ẹran ọ̀dọ́ aguntan, ati ti ẹgbọ̀rọ̀ mààlúù láti inú agbo ẹran wọn! Àwọn tí ń fi hapu kọ orin ìrégbè, tí wọ́n sì ń ṣe ohun èlò orin fún ara wọn bíi Dafidi. Àwọn tí wọn ń fi abọ́ mu ọtí, tí wọn ń fi òróró olówó iyebíye para, ṣugbọn tí wọn kò bìkítà fún ìparun Josẹfu. Nítorí náà, àwọn ni wọn yóo kọ́kọ́ lọ sí ìgbèkùn, gbogbo àsè ati ayẹyẹ àwọn tí wọn ń nà kalẹ̀ sórí ibùsùn yóo dópin. OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ti fi ara rẹ̀ búra, ó ní: “Mo kórìíra ìwà ìgbéraga Jakọbu, ati gbogbo àwọn ibi ààbò rẹ̀; n óo mú ọwọ́ kúrò lọ́rọ̀ ìlú náà ati gbogbo nǹkan tí ó wà ninu rẹ̀.” Bí ó bá ku eniyan mẹ́wàá ninu ìdílé kan, gbogbo wọn yóo kú. Nígbà tí ẹni tí ó jẹ́ olùdarí ìsìnkú bá kó eegun òkú jáde, tí ó bá bi àwọn eniyan tí ó kù ninu ilé pé, “Ǹjẹ́ ó ku ẹnikẹ́ni mọ́?” Wọn yóo dá a lóhùn pé, “Rárá.” Nígbà náà ni olùdarí ìsìnkú yóo sọ pé, “Ẹ dákẹ́, ẹ ṣọ́ra, a kò gbọdọ̀ tilẹ̀ dárúkọ OLUWA.” Wò ó! OLUWA pàṣẹ pé, a óo wó àwọn ilé ńlá, ati àwọn ilé kéékèèké lulẹ̀ patapata. Ṣé ẹṣin a máa sáré lórí àpáta? Àbí eniyan a máa fi àjàgà mààlúù pa ilẹ̀ lórí òkun? Ṣugbọn ẹ ti sọ ẹ̀tọ́ di májèlé, ẹ sì ti sọ èso òdodo di ohun kíkorò. Ẹ fọ́nnu pé ẹ̀yin ni ẹ ṣẹgun ìlú Lodebari, ẹ̀ ń wí pé: “Ṣebí agbára wa ni a fi gba ìlú Kanaimu.” OLUWA Ọlọrun àwọn ọmọ ogun ní: “Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, n óo rán orílẹ̀-èdè kan láti pọn yín lójú, wọn yóo sì fìyà jẹ yín láti ibodè Hamati, títí dé odò Araba.”

Amo 6:1-14 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ègbé ni fún ẹ̀yin tí ará rọ̀ ní Sioni àti ẹ̀yin tí ẹ wà ní abẹ́ ààbò ní òkè Samaria àti ẹ̀yin olókìkí orílẹ̀-èdè tí ẹ̀yin ènìyàn Israẹli máa ń tọ̀ ọ́ wá Ẹ lọ Kalne kí ẹ lọ wò ó kí ẹ sí tí ibẹ̀ lọ sí Hamati ìlú ńlá a nì. Kí ẹ sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ Gati ní ilẹ̀ Filistini Ǹjẹ́ wọ́n ha dára ju ìpínlẹ̀ yín méjèèjì lọ? Ǹjẹ́ a ha rí ilẹ̀ tó tóbi ju tiyín lọ bí? Ẹ̀yin sún ọjọ́ ibi síwájú, ẹ sì mú ìjọba òǹrorò súnmọ́ tòsí Ẹ̀yin sùn lé ibùsùn tí a fi eyín erin ṣe ẹ sì tẹ́ ara sílẹ̀ ni orí àwọn ibùsùn ẹyin pa èyí tí o dára nínú àwọn ọ̀dọ́-àgùntàn yín jẹ ẹ sì ń pa àwọn ọ̀dọ́ màlúù láàrín agbo wọn jẹ Ẹ̀yin ń lo ohun èlò orin bí i Dafidi ẹ sì ń ṣe àwọn àpilẹ̀rọ àwọn ohun èlò orin Ẹ̀yin mu wáìnì ẹ̀kún ọpọ́n kan àti ìkunra tí o dára jùlọ ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò káàánú ilé Josẹfu tí ó di ahoro Nítorí náà, àwọn ni yóò lọ sí ìgbèkùn pẹ̀lú àwọn tí ó ti kó lọ sí ìgbèkùn àsè àwọn tí ń ṣe àṣelékè ni a ó mú kúrò. OLúWA OLúWA Olódùmarè ti búra fúnrarẹ̀, OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun sì ti wí pé: “Mo kórìíra ìgbéraga Jakọbu n kò sì ní inú dídùn sí odi alágbára rẹ̀ Èmi yóò sì fa ìlú náà lé wọn lọ́wọ́ àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀.” Bí Ọkùnrin mẹ́wàá bá ṣẹ́kù nínú ilé kan, àwọn náà yóò kú Bí ẹbí tí ó yẹ kí ó gbé òkú wọn jáde fún sínsin bá wọlé, bí o ba sì béèrè pé ǹjẹ́ ẹnìkan wa tí ó fi ara pamọ́ níbẹ̀, “Ǹjẹ́ ẹnìkankan wà lọ́dọ̀ yín?” tí ó bá sì dáhùn wí pé, “Rárá,” nígbà náà ni yóò wí pé, “Pa ẹnu rẹ mọ́ àwa kò gbọdọ̀ dárúkọ OLúWA.” Nítorí OLúWA tí pa àṣẹ náà, Òun yóò sì wó ilé ńlá náà lulẹ̀ túútúú Àti àwọn ilé kéékèèkéé sí wẹ́wẹ́. Ǹjẹ́ ẹṣin a máa sáré lórí àpáta bí? Ǹjẹ́ ènìyàn a máa fi akọ màlúù kọ ilẹ̀ níbẹ̀? Ṣùgbọ́n ẹ̀yin ti yí òtítọ́ padà sí májèlé ẹ sì ti sọ èso òdodo di ìkorò. Ẹ̀yin yọ̀ torí ìṣẹ́gun lórí Lo-Debari Ẹ̀yin sì wí pé, “Ṣé kì í ṣe agbára wa ni àwa fi gba Karnaimu?” Nítorí OLúWA Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun wí pé, “Èmi yóò gbé orílẹ̀-èdè kan dìde sí ọ ìwọ Israẹli, wọn yóò pọ́n yín lójú ní gbogbo ọ̀nà, láti Lebo-Hamati, títí dé pẹ̀tẹ́lẹ̀ Arabah.”