Amo 2:6-16

Amo 2:6-16 Bibeli Mimọ (YBCV)

Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Israeli, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn tà olododo fun fàdakà, ati talakà fun bàta ẹsẹ̀ mejeji; Nwọn tẹ ori talaka sinu eruku ilẹ, nwọn si yi ọ̀na ọlọkàn tutù po: ati ọmọ ati baba rẹ̀ nwọle tọ̀ wundia kan, lati bà orukọ mimọ́ mi jẹ. Nwọn si dùbulẹ le aṣọ ti a fi lelẹ fun ògo lẹba olukuluku pẹpẹ, nwọn si mu ọti-waini awọn ti a yá, ni ile ọlọrun wọn. Ṣugbọn mo pa ará Amori run niwaju wọn, giga ẹniti o dàbi giga igi-kedari, on si le bi igi-oaku; ṣugbọn mo pa eso rẹ̀ run lati oke wá, ati egbò rẹ̀ lati isalẹ wá. Emi mu nyin goke pẹlu lati ilẹ Egipti wá, mo si sìn nyin li ogoji ọdun là aginjù ja, lati ni ilẹ awọn Amori. Mo si gbe ninu ọmọkunrin nyin dide lati jẹ woli, ati ninu awọn ọdọmọkunrin nyin lati jẹ Nasarite. Bẹ̃ ki o ri, ẹnyin ọmọ Israeli? li Oluwa wi. Ṣugbọn ẹnyin fun awọn Nasarite ni ọti-waini mu, ẹ si paṣẹ fun awọn woli pe, Ẹ máṣe sọtẹlẹ. Wò o, emi o tẹ̀ nyin mọlẹ, bi kẹkẹ́ ti o kún fun ití ti itẹ̀. Nitorina sisá yio dẹti fun ẹni yiyara, onipá kì yio si mu ipa rẹ̀ le, bẹ̃ni alagbara kì yio le gba ara rẹ̀ là. Bẹ̃ni tafàtafà kì yio duro; ati ẹniti o yasẹ̀ kì yio le gbà ara rẹ̀ là: bẹ̃ni ẹniti ngùn ẹṣin kì yio gbà ara rẹ̀ là: Ati ẹniti o gboiyà ninu awọn alagbara yio salọ ni ihòho li ọjọ na, li Oluwa wi.

Amo 2:6-16 Yoruba Bible (YCE)

OLUWA ní: “Àwọn ará Israẹli ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà; nítorí pé wọ́n ta olódodo nítorí fadaka, wọ́n sì ta aláìní nítorí bàtà ẹsẹ̀ meji. Wọ́n rẹ́ àwọn talaka jẹ, wọ́n sì yí ẹjọ́ àwọn tí ìyà ń jẹ po. Baba ati ọmọ ń bá ẹrubinrin kanṣoṣo lòpọ̀, wọ́n sì ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́. Wọ́n sùn káàkiri yí pẹpẹ inú ilé Ọlọrun wọn ká, lórí aṣọ tí wọ́n gbà lọ́wọ́ àwọn onígbèsè wọn; wọ́n ń mu ọtí tí àwọn kan fi san owó ìtanràn. “Bẹ́ẹ̀ sì ni èmi ni mo pa àwọn ará Amori run fún wọn, àwọn géńdé, tí wọ́n ga bí igi kedari, tí wọ́n sì lágbára bí igi oaku; mo run wọ́n tèsotèso, tigbòǹgbò-tigbòǹgbò. Èmi fúnra mi ni mo mu yín jáde wá láti ilẹ̀ Ijipti, mo mu yín la aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún, kí ẹ lè gba ilẹ̀ àwọn ará Amori. Mo yan àwọn kan ninu àwọn ọmọ yín ní wolii mi, mo sì yan àwọn mìíràn ninu wọn ní Nasiri. Àbí bẹ́ẹ̀ kọ́, ẹ̀yin ọmọ Israẹli? Èmi OLUWA ni mo sọ bẹ́ẹ̀. Ṣugbọn ẹ̀ ń mú kí àwọn Nasiri mu ọtí, ẹ sì ń dá àwọn wolii mi lẹ́kun, pé wọn kò gbọdọ̀ sọ àsọtẹ́lẹ̀ mọ́. Wò ó, n óo tẹ̀ yín ní àtẹ̀rẹ́ ní ibùgbé yín, bí ìgbà tí ọkọ̀ kọjá lórí eniyan. Ní ọjọ́ náà, àárẹ̀ yóo mú àwọn tí wọ́n lè sáré; ipá àwọn alágbára yóo pin, akikanju kò sì ní lè gba ara rẹ̀ sílẹ̀. Tafàtafà kò ní lè dúró, ẹni tí ó lè sáré kò ní lè sá àsálà; bẹ́ẹ̀ ni àwọn ẹlẹ́ṣin kò ní lè gba ara wọn kalẹ̀. Ìhòòhò ni àwọn akọni láàrin àwọn ọmọ ogun yóo sálọ ní ọjọ́ náà.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.

Amo 2:6-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta Israẹli àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà. Wọ́n ta olódodo fún fàdákà àti aláìní fún bàtà ẹsẹ̀ méjèèjì. Wọ́n fi ẹsẹ̀ tẹ orí àwọn tálákà mọ́lẹ̀ bí wọ́n ti ń tẹ erùpẹ̀ ilẹ̀ tí wọ́n ko sì ṣe òtítọ́ si àwọn tí a ni lára Baba àti ọmọ ń wọlé tọ wúńdíá kan náà Láti ba orúkọ mímọ́ mi jẹ́ Wọ́n dùbúlẹ̀ lẹ́bàá a pẹpẹ Lórí aṣọ tí wọ́n ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ ní ilé òrìṣà wọn wọ́n sì mu ọtí tí wọ́n san fún ìtánràn. “Mo pa àwọn ará Amori run níwájú wọn gíga ẹni tí ó dàbí igi kedari. Òun sì le koko bí igi óákù mo pa èso rẹ̀ run láti òkè wá àti egbò rẹ̀ láti ìsàlẹ̀ wá. Èmi mú un yín gòkè láti ilẹ̀ Ejibiti wá, mo sì sìn yín la aginjù já ní ogójì ọdún láti fi ilẹ̀ àwọn ará Amori fún un yín. “Èmi sì tún gbé àwọn wòlíì dìde láàrín àwọn ọmọ yín àti láàrín àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin yín láti jẹ Nasiri èyí kò ha jẹ́ òtítọ́ bí ará Israẹli?” ni OLúWA wí. “Ṣùgbọ́n ẹ̀yin fún àwọn Nasiri ní ọtí mu e sì pàṣẹ fún àwọn wòlíì kí wọ́n má ṣe sọtẹ́lẹ̀. “Ní báyìí, èmi yóò tẹ̀ yín mọ́lẹ̀ bí kẹ̀kẹ́ tí ó kún fún ìtí ti í tẹ̀. Ẹni tí ó yára bí àṣá kò ní rí ọ̀nà àbáyọ alágbára kò ní le è dúró lé agbára rẹ̀ jagunjagun kì yóò le gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là Tafàtafà kì yóò dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀ bẹ́ẹ̀ ni ẹni tí ó gún ẹṣin kì yóò gba ẹ̀mí ara rẹ̀ là Àní jagunjagun tí ó gbóyà jùlọ yóò sálọ ní ìhòhò ní ọjọ́ náà,” ni OLúWA wí.