Amo 1:1-5
Amo 1:1-5 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọ̀RỌ Amosi, ẹniti o wà ninu awọn darandaran Tekoa, ti o ri niti Israeli li ọjọ ọba Ussiah ọba Juda, ati li ọjọ Jeroboamu ọmọ Joaṣi ọba Israeli, ọdun meji ṣãju isẹ̀lẹ nì. O si wipe, Oluwa yio bu jade lati Sioni wá, yio si fọ̀ ohùn rẹ̀ lati Jerusalemu wá; ibùgbe awọn olùṣọ-agùtan yio si ṣọ̀fọ, oke Karmeli yio si rọ. Bayi li Oluwa wi; nitori irekọja mẹta ti Damasku, ati nitori mẹrin, emi kì o yi iyà rẹ̀ kuro; nitori nwọn ti fi ohunèlo irin ipakà pa Gileadi: Ṣugbọn emi o rán iná kan si ile Hasaeli, ti yio jo ãfin Benhadadi wọnni run. Emi o ṣẹ ọpá idabu Damasku pẹlu, emi o si ke ará pẹ̀tẹlẹ Afeni kuro, ati ẹniti o dì ọpá alade nì mu kuro ni ile Edeni: awọn enia Siria yio si lọ si igbèkun si Kiri, ni Oluwa wi.
Amo 1:1-5 Yoruba Bible (YCE)
Ìran tí Amosi, ọ̀kan ninu àwọn darandaran Tekoa, rí nípa Israẹli nìyí, nígbà ayé Usaya, ọba Juda, ati Jeroboamu, ọmọ Jehoaṣi, ọba Israẹli, ní ọdún meji ṣáájú ìṣẹ̀lẹ̀ tí ó ṣẹlẹ̀ tí ilẹ̀ fi mì jìgìjìgì. Amosi ní: “OLUWA bú ramúramù lórí Òkè Sioni, ó fọhùn ní Jerusalẹmu; àwọn pápá tútù rọ, ewéko tútù orí òkè Kamẹli sì rẹ̀.” OLUWA ní, “Àwọn ará Damasku ń dẹ́ṣẹ̀ kún ẹ̀ṣẹ̀, dájúdájú, n óo jẹ wọ́n níyà. Wọ́n mú ohun èlò ìpakà onírin ṣómúṣómú, wọ́n fi pa àwọn ará Gileadi ní ìpa ìkà. Nítorí náà, n óo sọ iná sí ààfin Hasaeli, yóo sì jó ibi ààbò Benhadadi kanlẹ̀. N óo fọ́ ìlẹ̀kùn odi ìlú Damasku. N óo sì pa gbogbo àwọn ará àfonífojì Afeni run. Wọn óo mú ọba Betedeni lọ sí ìgbèkùn; òun ati àwọn ará Siria yóo lọ sí ìgbèkùn ní ilẹ̀ Kiri.” OLUWA ló sọ bẹ́ẹ̀.
Amo 1:1-5 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Àwọn ọ̀rọ̀ Amosi, ọ̀kan lára àwọn olùṣọ́-àgùntàn Tekoa; ohun tí o rí nípa Israẹli ní ọdún méjì ṣáájú ilẹ̀-rírì, nígbà tí Ussiah ọba Juda àti Jeroboamu ọmọ Jehoaṣi jẹ́ ọba ní ilẹ̀ Israẹli. Ó wí pé: “OLúWA yóò bú jáde láti Sioni ohùn rẹ̀ yóò sì sán bí àrá láti Jerusalẹmu wá; Ibùgbé àwọn olùṣọ́-àgùntàn yóò sì ṣọ̀fọ̀, orí òkè Karmeli yóò sì rọ.” Èyí ni ohun tí OLúWA wí: “Nítorí ẹ̀ṣẹ̀ mẹ́ta tí Damasku, àní fún mẹ́rin, Èmi kò ní yí ìpinnu ìjìyà mi padà Nítorí wọn fi ohun èlò ìpakà pa Gileadi. Pẹ̀lú ohun èlò irin tí ó ní eyín mímú Èmi yóò rán iná sí ilé Hasaeli Èyí ti yóò jó àwọn ààfin Beni-Hadadi run. Èmi yóò ṣẹ́ ọ̀pá ìdábùú Damasku; Èmi yóò sì pa ọba tí ó wà ní Àfonífojì Afeni run àti ẹni tí ó di ọ̀pá aládé mú ní Beti-Edeni. Àwọn ará a Aramu yóò lọ sí ìgbèkùn sí Kiri,” ni OLúWA wí.