Iṣe Apo 9:1-9
Iṣe Apo 9:1-9 Bibeli Mimọ (YBCV)
ṢUGBỌN Saulu, o nmí ẹmi ikilọ ati pipa sibẹ si awọn ọmọ-ẹhin Oluwa, o tọ̀ olori alufa lọ; O bẽre iwe lọwọ rẹ̀ si Damasku si awọn sinagogu pe, bi on ba ri ẹnikẹni ti mbẹ li Ọna yi, iba ṣe ọkunrin, tabi obinrin, ki on le mu wọn ni didè wá si Jerusalemu. O si ṣe, bi o ti nlọ, o si sunmọ Damasku: lojijì lati ọrun wá, imọlẹ si mọlẹ yi i ka: O si ṣubu lulẹ, o gbọ́ ohùn ti o nfọ̀ si i pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? O si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi Jesu ni, ẹniti iwọ nṣe inunibini si: ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. O si nwarìri, ẹnu si yà a, o ni, Oluwa, kini iwọ nfẹ ki emi ki o ṣe? Oluwa si wi fun u pe, Dide, ki o si lọ si ilu na, a o sọ fun ọ li ohun ti iwọ o ṣe. Awọn ọkunrin ti nwọn si mba a re àjo duro, kẹ́kẹ pa mọ́ wọn li ẹnu, nwọn gbọ́ ohùn na, ṣugbọn nwọn kò ri ẹnikan. Saulu si dide ni ilẹ; nigbati oju rẹ̀ si là kò ri ohunkan: ṣugbọn nwọn fà a li ọwọ́, nwọn si mu u wá si Damasku. O si gbé ijọ mẹta li airiran, kò si jẹ, bẹ̃ni kò si mu.
Iṣe Apo 9:1-9 Yoruba Bible (YCE)
Ní gbogbo àkókò yìí, Saulu ń fi ikú dẹ́rùba àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Oluwa. Ó lọ sọ́dọ̀ Olórí Alufaa, ó gba ìwé lọ́dọ̀ rẹ̀ láti lọ sí àwọn ilé ìpàdé tí ó wà ní Damasku. Ìwé yìí fún un ní àṣẹ pé bí ó bá rí àwọn tí ń tẹ̀lé ọ̀nà ẹ̀sìn yìí, ìbáà ṣe ọkunrin ìbáà ṣe obinrin, kí ó dè wọ́n, kí ó sì fà wọ́n wá sí Jerusalẹmu. Bí ó ti ń lọ lọ́nà, tí ó súnmọ́ Damasku, iná kan mọ́lẹ̀ yí i ká lójijì; ó bá ṣubú lulẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó bi í pé, “Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Saulu bèèrè pé, “Ta ni ọ́, Oluwa?” Ẹni náà bá dáhùn pé, “Èmi ni Jesu, ẹni tí ò ń ṣe inúnibíni sí. Dìde nisinsinyii, kí o wọ inú ìlú lọ. A óo sọ ohun tí o níláti ṣe fún ọ.” Àwọn ọkunrin tí ó ń bá a rìn dúró. Wọn kò sọ ohunkohun. Wọ́n ń gbọ́ ohùn eniyan, ṣugbọn wọn kò rí ẹnìkankan. Saulu bá dìde nílẹ̀, ó la ojú sílẹ̀ ṣugbọn kò ríran. Wọ́n bá fà á lọ́wọ́ lọ sí Damasku. Fún ọjọ́ mẹta, kò ríran, kò jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò mu.
Iṣe Apo 9:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n síbẹ̀, Saulu sí ń tẹ̀síwájú nínú mímí-èémí ìhalẹ̀-mọ́ni àti ìpani sí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Olúwa. Ó tọ olórí àlùfáà lọ, ó béèrè ìwé lọ́wọ́ rẹ̀ sí Sinagọgu tí ń bẹ ní ìlú Damasku pé, bí òun bá rí ẹnikẹ́ni tí ń bẹ ni Ọ̀nà yìí, ìbá à ṣe ọkùnrin, tàbí obìnrin, kí òun lè mú wọn ní dídè wá sí Jerusalẹmu. Ó sì ṣe, bí ó ti ń lọ, ó sì súnmọ́ Damasku; lójijì, ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run wá mọ́lẹ̀ yí i ká. Ó sì ṣubú lulẹ̀, ó gbọ́ ohùn tí ó ń fọ̀ sí i pé, “Saulu, Saulu, èéṣe ti ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi?” Ó sì wí pé, “Ìwọ ta ni, Olúwa?” Olúwa sì wí pé, “Èmi ni Jesu, ẹni ti ìwọ ń ṣe inúnibíni sí; (ohùn ìrora ni fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún). Ó sì ń wárìrì, ẹnu sì yà á, ó ni Olúwa, kín ní ìwọ ń fẹ́ kí èmi ṣe? Olúwa sì wí fún pé, Dìde, kí o sì lọ sí ìlú náà, a ó sì sọ fún ọ nípa ohun tí ìwọ yóò ṣe.” Àwọn ọkùnrin tí wọ́n sì ń bá Saulu lọ àjò dúró, wọn kò sì le sọ ohun kan, wọn gbọ́ ohùn náà ṣùgbọ́n wọn kò rí ẹnìkan. Saulu sì dìde ní ilẹ̀; nígbà tí ojú rẹ̀ sì lá kò rí ohunkóhun; ṣùgbọ́n wọ́n fà á lọ́wọ́ wọ́n sì mú un wá sí Damasku. Ó sì gbé ọjọ́ mẹ́ta ni àìríran kò sì jẹ, bẹ́ẹ̀ ni kò sì mu.