Iṣe Apo 8:26-40

Iṣe Apo 8:26-40 Bibeli Mimọ (YBCV)

Angẹli Oluwa si sọ fun Filippi, pe, Dide ki o si ma lọ si ìha gusu li ọ̀na ti o ti Jerusalemu lọ si Gasa, ti iṣe ijù. Nigbati o si dide, o lọ; si kiyesi i, ọkunrin kan ara Etiopia, iwẹfa ọlọlá pipọ lọdọ Kandake ọbabirin awọn ara Etiopia, ẹniti iṣe olori gbogbo iṣura rẹ̀, ti o si ti wá si Jerusalemu lati jọsin, On si npada lọ, o si joko ninu kẹkẹ́ rẹ̀, o nkà iwe woli Isaiah. Ẹmí si wi fun Filippi pe, Lọ ki o si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹkẹ́ yi. Filippi si sure lọ, o gbọ́, o nkà iwe woli Isaiah, o si bi i pe, Ohun ti iwọ nkà nì, o yé ọ? O si dahùn wipe, Yio ha ṣe yé mi, bikoṣepe ẹnikan tọ́ mi si ọna? O si bẹ̀ Filippi ki o gòke wá, ki o si ba on joko. Ibi iwe-mimọ́ ti o si nkà na li eyi, A fà a bi agutan lọ fun pipa; ati bi ọdọ-agutan iti iyadi niwaju olurẹrun rẹ̀, bẹ̃ni kò yà ẹnu rẹ̀: Ni irẹsilẹ rẹ̀ a mu idajọ kuro: tani yio sọ̀rọ iran rẹ̀? nitori a gbà ẹmí rẹ̀ kuro li aiye. Iwẹfa si da Filippi lohùn, o ni, Mo bẹ̀ ọ, ti tani woli na sọ ọ̀rọ yi? ti ara rẹ̀, tabi ti ẹlomiran? Filippi si yà ẹnu rẹ̀, o si bẹ̀rẹ lati ibi iwe-mimọ́ yi, o si wasu Jesu fun u. Bi nwọn si ti nlọ li ọ̀na, nwọn de ibi omi kan: iwẹfa na si wipe, Wò o, omi niyi; kili o dá mi duro lati baptisi? Filippi si wipe, Bi iwọ ba gbagbọ́ tọkàntọkan, a le baptisi rẹ. O si dahùn o ni, Mo gbagbọ́ pe Jesu Kristi, Ọmọ Ọlọrun ni. O si paṣẹ ki kẹkẹ́ duro jẹ: awọn mejeji si sọkalẹ lọ sinu omi, ati Filippi ati iwẹfa; o si baptisi rẹ̀. Nigbati nwọn si jade kuro ninu omi, Ẹmí Oluwa ta Filippi pá, iwẹfa kò si ri i mọ́: nitoriti o mbá ọ̀na rẹ̀ lọ, o nyọ̀. Ni Asotu li a si ri Filippi; bi o si ti nkọja lọ, o nwasu ihinrere ni gbogbo ilu, titi o fi de Kesarea.

Iṣe Apo 8:26-40 Yoruba Bible (YCE)

Angẹli Oluwa sọ fún Filipi pé, “Dìde kí o lọ sí apá gúsù, ní ọ̀nà tí ó lọ láti Jerusalẹmu sí Gasa.” (Aṣálẹ̀ ni ọ̀nà yìí gbà lọ.) Ni Filipi bá dìde lọ. Ó bá rí ọkunrin ará Etiopia kan. Ó jẹ́ ìwẹ̀fà onípò gíga kan lábẹ́ Kandake, ọbabinrin Etiopia. Òun ni akápò ìjọba. Ó ti lọ ṣe ìsìn ní Jerusalẹmu, ó wá ń pada lọ sílé. Ó jókòó ninu ọkọ̀ ẹlẹ́ṣin rẹ̀, ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ẹ̀mí sọ fún Filipi pé, “Lọ síbi ọkọ nnì kí o súnmọ́ ọn.” Nígbà tí Filipi sáré, tí ó súnmọ́ ọn, ó gbọ́ tí ó ń ka ìwé wolii Aisaya. Ó bi í pé, “Ǹjẹ́ ohun tí ò ń kà yé ọ?” Ó dáhùn pé, “Ó ṣe lè yé mi láìjẹ́ pé ẹnìkan bá ṣe àlàyé rẹ̀ fún mi?” Ó bá bẹ Filipi pé kí ó gòkè wọ inú ọkọ̀, kí ó jókòó ti òun. Apá ibi tí ó ń kà nìyí: “Bí aguntan tí a mú lọ sí ilé ìpẹran, tí à ń fà níwájú àwọn tí ń rẹ́ irun rẹ̀, kò fọhùn, bẹ́ẹ̀ ni kò ya ẹnu rẹ̀. A rẹ̀ ẹ́ sílẹ̀. A kò ṣe ẹ̀tọ́ nípa ọ̀ràn rẹ̀. Ẹnikẹ́ni kò ní lè sọ nípa ìran rẹ̀. Nítorí a pa á run kúrò lórí ilẹ̀ alààyè.” Ìwẹ̀fà náà sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́, ọ̀rọ̀ ta ni wolii Ọlọrun yìí ń sọ, ọ̀rọ̀ ara rẹ̀ ni tabi ọ̀rọ̀ ẹlòmíràn?” Filipi bá tẹnu bọ ọ̀rọ̀. Ó bẹ̀rẹ̀ láti ibi àkọsílẹ̀ yìí, ó waasu ìyìn rere Jesu fún un. Bí wọn tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé odò kan. Ìwẹ̀fà náà sọ pé, “Wo omi. Kí ló dé tí o ò fi kúkú rì mí bọmi?” [ Filipi sọ fún un pé, “Bí o bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ẹ̀tọ́ ni.” Ó dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Ọmọ Ọlọrun ni Jesu Kristi.”] Ìwẹ̀fà náà bá pàṣẹ pé kí ọkọ̀ dúró. Òun ati Filipi bá sọ̀kalẹ̀, wọ́n lọ sinu odò, Filipi bá rì í bọmi. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò ninu odò. Ẹ̀mí Oluwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà náà kò sì rí i mọ́. Ó bá ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ pẹlu ayọ̀. Ní Asotu ni a tún ti rí Filipi. Ó ń waasu ní gbogbo àwọn ìlú tí ó gbà kọjá títí ó fi dé Kesaria.

Iṣe Apo 8:26-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Angẹli Olúwa sì sọ fún Filipi pé, “Dìde kí ó sì máa lọ sí ìhà gúúsù, sí ọ̀nà ijù, tí ó ti Jerusalẹmu lọ sí Gasa.” Nígbà tí ó sì dìde, ó lọ; sí kíyèsi, ọkùnrin kan ará Etiopia, ìwẹ̀fà ọlọ́lá púpọ̀ lọ́dọ̀ Kandake ọbabìnrin àwọn ara Etiopia, ẹni tí í ṣe olórí ìṣúra rẹ̀, tí ó sì ti wá sí Jerusalẹmu láti jọ́sìn, Òun sì ń padà lọ, ó sì jókòó nínú kẹ̀kẹ́ rẹ̀, ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah. Ẹ̀mí sì wí fún Filipi pé, “Lọ kí ó si da ara rẹ pọ̀ mọ́ kẹ̀kẹ́ yìí.” Filipi si súré lọ, ó gbọ́ ti ó ń ka ìwé wòlíì Isaiah, Filipi sì bí i pé, “Ohun tí ìwọ ń kà yìí ha yé ọ bí?” Ó sì dáhùn wí pé, “Yóò ha ṣe yé mi, bí kò ṣe pé ẹnìkan tọ́ mí sí ọ̀nà?” Ó sì bẹ Filipi kí ó gòkè wá, kí ó sì bá òun jókòó. Ibi ìwé mímọ́ tí ìwẹ̀fà náà ń kà náà ni èyí: “A fà á bí àgùntàn lọ fún pípa; àti bí ọ̀dọ́-àgùntàn tí ń dákẹ́ níwájú olùrẹ́run rẹ̀, bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ ni kò wí ohun kan. Nínú ìwà ìrẹ̀lẹ̀ rẹ̀ a fi ìdájọ́ òdodo dùn ún: Ta ni ó le sọ̀rọ̀ nípa ti àwọn ìran rẹ̀? Nítorí tí a gba ẹ̀mí rẹ̀ kúrò ní ayé.” Ìwẹ̀fà náà sì sọ fún Filipi pé, “Mo bẹ̀ ọ́ sọ fún mi, nípa ta ni wòlíì náà ń sọ ọ̀rọ̀ yìí, nípa ara rẹ̀ tàbí nípa ẹlòmíràn?” Filipi sí ya ẹnu rẹ̀, bẹ̀rẹ̀ láti ibi ìwé mímọ́ yìí, ó sí wàásù ìhìnrere ti Jesu fún un. Bí wọ́n sì tí ń lọ lọ́nà, wọ́n dé ibi omi kan; ìwẹ̀fà náà sì wí pé, “Wò ó, omi nìyí. Kín ni ó dá mi dúró láti bamitiisi?” Filipi sì wí pé, “Bí ìwọ bá gbàgbọ́ tọkàntọkàn, a lè bamitiisi rẹ.” Ìwẹ̀fà náà sì dáhùn pé, “Mo gbàgbọ́ pé Jesu Kristi Ọmọ Ọlọ́run ni.” Ó sì pàṣẹ kí kẹ̀kẹ́ dúró jẹ́; àwọn méjèèjì Filipi àti Ìwẹ̀fà sì sọ̀kalẹ̀ lọ sínú omi, Filipi sì bamitiisi rẹ̀. Nígbà tí wọ́n sí jáde kúrò nínú omi Ẹ̀mí Olúwa gbé Filipi lọ, ìwẹ̀fà kò sì rí i mọ́; nítorí tí ó ń bá ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó ń yọ̀. Filipi sì bá ara rẹ̀ ní ìlú Asotu, bí ó ti ń kọjá lọ, o wàásù ìhìnrere ní gbogbo ìlú, títí ó fi dé Kesarea.