Iṣe Apo 7:30-50
Iṣe Apo 7:30-50 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ogoji ọdún si pé, angẹli Oluwa farahàn a ni ijù, li òke Sinai, ninu ọwọ́ iná ni igbẹ́. Nigbati Mose si ri i, ẹnu yà a si iran na: nigbati o si sunmọ ọ lati wò o fín, ohùn Oluwa kọ si i, Wipe, Emi li Ọlọrun awọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, ati Ọlọrun Isaaki, ati Ọlọrun Jakọbu. Mose si warìri, kò si daṣa lati wò o mọ́. Oluwa si wi fun u pe, Tú bata rẹ kuro li ẹsẹ rẹ: nitori ibi ti iwọ gbé duro nì ilẹ mimọ́ ni. Ni riri mo ti ri ipọnju awọn enia mi ti mbẹ ni Egipti, mo si ti gbọ́ gbigbin wọn, mo si sọkalẹ wá lati gbà wọn. Wá nisisiyi, emi o si rán ọ lọ si Egipti. Mose na yi ti nwọn kọ̀, wipe, Tali o fi ọ jẹ olori ati onidajọ? on na li Ọlọrun rán lọ lati ọwọ́ angẹli, ti o farahàn a ni igbẹ́, lati ṣe olori ati oludande. On li o mu wọn jade, lẹhin igbati o ṣe iṣẹ iyanu ati iṣẹ àmi ni ilẹ Egipti, ati li Okun pupa, ati li aginjù li ogoji ọdún. Eyi ni Mose na ti o wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Woli kan li Oluwa Ọlọrun nyin yio gbé dide fun nyin ninu awọn arakunrin nyin, bi emi; on ni ki ẹ gbọ́ tirẹ. Eyi na li ẹniti o wà ninu ijọ ni ijù pẹlu angẹli na ti o ba a sọ̀rọ li òke Sinai, ati pẹlu awọn baba wa: ẹniti o gbà ọ̀rọ ìye lati fifun wa: Ẹniti awọn baba wa kò fẹ gbọ́ tirẹ, ṣugbọn nwọn tì i kuro lọdọ wọn, nwọn si yipada li ọkàn wọn si Egipti; Nwọn wi fun Aaroni pe, Dà oriṣa fun wa ti yio ma tọ̀na ṣaju wa: nitori bi o ṣe ti Mose yi ti o mu wa ti ilẹ Egipti jade wá, a kò mọ̀ ohun ti o ṣe e. Nwọn si yá ere ẹgbọ̀rọ malu ni ijọ wọnni, nwọn si rubọ si ere na, nwọn si nyọ̀ ninu iṣẹ ọwọ́ ara wọn. Ọlọrun si pada, o fi wọn silẹ lati mã sìn ogun ọrun; bi a ti kọ ọ ninu iwe awọn woli pe, Ẹnyin ara ile Israeli, ẹnyin ha mu ẹran ti a pa ati ẹbọ fun mi wá bi li ogoji ọdun ni iju? Ẹnyin si tẹwọgbà agọ́ Moloku, ati irawọ oriṣa Remfani, aworan ti ẹnyin ṣe lati mã bọ wọn: emi ó si kó nyin lọ rekọja Babiloni. Awọn baba wa ni agọ ẹri ni ijù, bi ẹniti o ba Mose sọrọ ti paṣẹ pe, ki o ṣe e gẹgẹ bi apẹrẹ ti o ti ri; Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi; Ẹniti o ri ojurere niwaju Ọlọrun, ti o si tọrọ lati ri ibugbe fun Ọlọrun Jakọbu. Ṣugbọn Solomoni kọ́ ile fun u. Ṣugbọn Ọgá-ogo kì igbé ile ti a fi ọwọ kọ́; gẹgẹ bi woli ti wipe, Ọrun ni itẹ́ mi, aiye si li apoti itisẹ mi: irú ile kili ẹnyin o kọ́ fun mi? li Oluwa wi; tabi ibo ni ibi isimi mi? Ọwọ́ mi kọ́ ha ṣe gbogbo nkan wọnyi?

Iṣe Apo 7:30-50 Yoruba Bible (YCE)
“Lẹ́yìn ogoji ọdún, angẹli kán yọ sí i ninu ìgbẹ́ tí ń jóná ní aṣálẹ̀ lẹ́bàá òkè Sinai. Nígbà tí Mose rí ìran náà, ẹnu yà á. Nígbà tí ó súnmọ́ ọn pé kí òun wò ó fínnífínní, ó gbọ́ ohùn Oluwa tí ó sọ pé, ‘Èmi ni Ọlọrun àwọn baba rẹ, Ọlọrun Abrahamu, Ọlọrun Isaaki, ati ti Jakọbu.’ Mose bá bẹ̀rẹ̀ sí gbọ̀n. Kò tó ẹni tí í wò ó. Oluwa tún sọ fún un pé, ‘Bọ́ sálúbàtà tí ó wà lẹ́sẹ̀ rẹ, nítorí ilẹ̀ mímọ́ ni ibi tí o dúró sí. Mo ti rí gbogbo ìrora tí àwọn eniyan mi ń jẹ ní Ijipti. Mo ti gbọ́ ìkérora wọn, mo sì ṣetán láti yọ wọ́n. Ó yá nisinsinyii. N óo rán ọ lọ sí Ijipti.’ “Mose yìí kan náà, tí wọ́n kọ̀, tí wọ́n sọ fún pé, ‘Ta ni ó fi ọ́ ṣe olórí ati onídàájọ́?’ Òun ni Ọlọrun rán angẹli sí, tí ó farahàn án ninu ìgbẹ́ tí ń jó, láti jẹ́ olórí ati olùdáǹdè. Mose yìí ni aṣaaju wọn, tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ní ilẹ̀ Ijipti ní Òkun Pupa ati ní ilẹ̀ aṣálẹ̀ fún ogoji ọdún. Mose yìí ni ó sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọrun yóo gbé wolii kan bí èmi dìde fun yín láàrin àwọn arakunrin yín.’ Mose náà ni ó bá angẹli sọ̀rọ̀ ní òkè Sinai nígbà tí wọ́n wà ninu àwùjọ ní aṣálẹ̀, tí ó tún bá àwọn baba wa sọ̀rọ̀. Òun ni ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti ọ̀dọ̀ Ọlọrun tí ó fi fún wa. “Ṣugbọn àwọn baba wa kò fẹ́ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́. Wọ́n tì í kúrò lọ́dọ̀ wọn; ọkàn wọn tún pada sí Ijipti. Wọ́n sọ fún Aaroni pé, ‘Ṣe oriṣa fún wa kí á rí ohun máa bọ, kí ó máa tọ́ wa sí ọ̀nà. A kò mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ sí Mose tí ó kó wa jáde láti ilẹ̀ Ijipti.’ Wọ́n bá ṣe ère ọmọ mààlúù kan ní àkókò náà, wọ́n rúbọ sí i. Wọ́n bá ń ṣe àríyá lórí ohun tí wọ́n fi ọwọ́ wọn ṣe. Ọlọrun bá pada lẹ́yìn wọn, ó fi wọ́n sílẹ̀ láti máa sin ìràwọ̀ ojú ọ̀run, gẹ́gẹ́ bí ó ti wà ní àkọsílẹ̀ ninu ìwé àwọn wolii pé, ‘Ẹ̀yin ọmọ Israẹli, ǹjẹ́ ẹ mú ẹran wá fi rúbọ sí mi fún ogoji ọdún ní aṣálẹ̀? Ṣebí àtíbàbà Moleki ni ẹ gbé rù, ati ìràwọ̀ Refani oriṣa yín, àwọn ère tí ẹ ṣe láti máa foríbalẹ̀ fún? N óo le yín lọ sí ìgbèkùn, ẹ óo kọjá Babiloni.’ “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí kan ní aṣálẹ̀. Ọlọrun bá Mose sọ̀rọ̀, ó sì pàṣẹ fún un pé kí ó ṣe àgọ́ yìí gẹ́gẹ́ bí àwòrán tí òun ti fihàn án tẹ́lẹ̀. Àwọn baba wa tí wọ́n tẹ̀lé Joṣua gba ilẹ̀ àwọn orílẹ̀-èdè tí Ọlọrun lé kúrò níwájú wọn, lẹ́yìn náà wọ́n gbé àgọ́ náà wá. Àgọ́ yìí sì wà pẹlu wa títí di àkókò Dafidi. Dafidi bá ojurere Ọlọrun pàdé; ó wá bèèrè pé kí Ọlọrun jẹ́ kí òun kọ́ ilé fún òun, Ọlọrun Jakọbu. Ṣugbọn Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. “Bẹ́ẹ̀ ni Ọba tí ó ga jùlọ kì í gbé ilé tí a fi ọwọ́ kọ́. Gẹ́gẹ́ bí wolii nì ti sọ: ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni tìmùtìmù ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé wo ni ẹ̀ báà kọ́ fún mi? Bẹ́ẹ̀ ni Oluwa wí. Níbo ni ẹ̀ báà palẹ̀ mọ́ fún mi pé kí n ti máa sinmi? Ṣebí èmi ni mo fọwọ́ mi ṣe gbogbo nǹkan wọnyi?’
Iṣe Apo 7:30-50 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Nígbà tí ogójì ọdún sì pé, angẹli Olúwa fi ara han Mose ní ijù, ní òkè Sinai, nínú ọ̀wọ́-iná nínú igbó. Nígbà tí Mose sì rí i, ẹnu yà á sí ìran náà; nígbà tí ó sì súnmọ́ ọn láti wò ó fín, ohùn Olúwa kọ sí i, Wí pé ‘Èmi ni Ọlọ́run àwọn baba rẹ, Ọlọ́run Abrahamu àti Ọlọ́run Isaaki, àti Ọlọ́run Jakọbu,’ Mose sì wárìrì pẹ̀lú ìbẹ̀rù, kò sì dáṣà láti wò ó mọ́. “Olúwa sì wí fún un pé, ‘bọ́ bàtà rẹ kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ, nítorí ibi tí ìwọ dúró sí i nì ilẹ̀ mímọ́ ni. Ní rí rí mo ti rí ìpọ́njú àwọn ènìyàn mi tí ń bẹ ni Ejibiti, mo sì ti gbọ́ ìkérora wọn, Mo sì sọ̀kalẹ̀ wá láti gbà wọ́n. Wá nísinsin yìí, Èmi ó sì rán ọ lọ sí ilẹ̀ Ejibiti.’ “Mose náà yìí tí wọ́n kọ̀, wí pé, ‘Ta ni ó fi jẹ olórí àti onídàájọ́?’ Òun náà ni Ọlọ́run rán lọ láti ọwọ́ angẹli, tí ó farahàn án ní pápá, láti ṣe olórí àti olùdáǹdè. Òun ni ó mú wọn jáde, lẹ́yìn ìgbà tí ó ṣe iṣẹ́ ìyanu àti iṣẹ́ ààmì ní ilẹ̀ Ejibiti, àti ni Òkun pupa, àti ni aginjù ní ogójì ọdún. “Èyí ni Mose náà ti ó wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ọlọ́run yóò gbé wòlíì kan bí èmi dìde nínú àwọn ènìyàn yín.’ Èyí náà ni ẹni tí ó wà nínú ìjọ ní ijù pẹ̀lú angẹli náà tí ó bá a sọ̀rọ̀ ní orí òkè Sinai, àti pẹ̀lú àwọn baba wa; ẹni ti ó gba ọ̀rọ̀ ìyè láti fi fún wa. “Ṣùgbọ́n àwọn baba wa kò fẹ́ gbọ́ tirẹ̀. Dípò bẹ́ẹ̀, wọ́n kọ̀ ọ́ sílẹ̀, àti pé nínú ọkàn wọn, wọn fẹ́ yípadà lọ sí ilẹ̀ Ejibiti; Wọ́n wí fún Aaroni pé, ‘Dá òrìṣà fún wa tí yóò máa tọ́nà ṣáájú wa; nítorí bí ó ṣe ti Mose yìí tí ó mú wa jáde wá láti ilẹ̀ Ejibiti, a kò mọ̀ ohun tí ó ṣe é.’ Wọ́n sì yá ère ẹgbọrọ màlúù ni ọjọ́ wọ̀nyí. Wọ́n sì rú ẹbọ sí ère náà, wọ́n sì ń yọ̀ nínú ohun tí wọ́n fi ọwọ́ ara wọn ṣe. Ọlọ́run sì padà, ó fi wọn sílẹ̀ láti máa sin ogun ọ̀run: òòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀. Èyí wà ní ìbámu pẹ̀lú bí a ti kọ ọ́ nínú ìwé àwọn wòlíì pé: “ ‘Ẹ̀yin ha mú ẹran tí a pa àti ẹbọ wa fún mi ní ogójì ọdún ní ijù bí, ìwọ ilé Israẹli? Ẹ̀yin sì tẹ́wọ́gbà àgọ́ Moleki, àti ìràwọ̀ Refani òrìṣà yín, àwòrán tí ẹ̀yin ṣe láti máa bọ wọ́n. Nítorí náà èmi yóò kó yín lọ sí ìgbèkùn rékọjá Babeli.’ “Àwọn baba wa ní àgọ́ ẹ̀rí pẹ̀lú wọn ní ijù. Èyí tí a ṣe gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run tí ó ba Mose sọ̀rọ̀ pé kí ó ṣe é, gẹ́gẹ́ bí àpẹẹrẹ tí ó ti rí. Ti àwọn baba wa tí ó tẹ̀lé wọn sí mú bá Joṣua wá sí ilẹ̀ ìní àwọn aláìkọlà, tí Ọlọ́run lè jáde kúrò níwájú àwọn baba wa, títí dí àkókò Dafidi. Ẹni tí ó rí ojúrere níwájú Ọlọ́run, tí ó sì tọrọ láti rí ibùgbé fún Ọlọ́run Jakọbu. Ṣùgbọ́n Solomoni ni ó kọ́ ilé fún un. “Ṣùgbọ́n Ọ̀gá-ògo kì í gbé ilé ti a fi ọwọ́ kọ́: gẹ́gẹ́ bí wòlíì ti wí pé: “ ‘Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Irú ilé kín ní ẹ̀yin yóò kọ́ fún mi? ni Olúwa wí. Tàbí níbo ni yóò jẹ́ ibi ìsinmi mi? Ọwọ́ mi kò ha ṣe gbogbo nǹkan wọ̀nyí.’