Iṣe Apo 6:8-15
Iṣe Apo 6:8-15 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati Stefanu, ti o kún fun ore-ọfẹ ati agbara, o ṣe iṣẹ iyanu, ati iṣẹ ami nla lãrin awọn enia. Ṣugbọn awọn kan dide ninu awọn ti sinagogu, ti a npè ni ti awọn Libertine, ati ti ara Kirene, ati ti ara Aleksandria, ati ninu awọn ara Kilikia, ati ti Asia nwọn mba Stefanu jiyàn. Nwọn kò si le kò ọgbọ́n ati ẹmí ti o fi nsọrọ loju. Nigbana ni nwọn bẹ̀ abẹtẹlẹ awọn ọkunrin, ti nwọn nwipe, Awa gbọ́ ọkunrin yi nsọ ọrọ-odi si Mose ati si Ọlọrun. Nwọn si rú awọn enia soke, ati awọn àgbagba, ati awọn akọwe, nwọn dide si i, nwọn gbá a mu, nwọn mu u wá si ajọ igbimọ. Nwọn si mu awọn ẹlẹri eke wá, ti nwọn wipe, ọkunrin yi kò simi lati sọ ọ̀rọ-òdi si ibi mimọ́ yi, ati si ofin: Nitori awa gbọ́ o wipe, Jesu ti Nasareti yi yio fọ́ ibi yi, yio si pa iṣe ti Mose fifun wa dà. Ati gbogbo awọn ti o si joko ni ajọ igbimọ tẹjumọ́ ọ, nwọn nwò oju rẹ̀ bi ẹnipe oju angẹli.
Iṣe Apo 6:8-15 Yoruba Bible (YCE)
Stefanu ń ṣe iṣẹ́ ìyanu ati iṣẹ́ abàmì ńlá láàrin àwọn eniyan nítorí pé ẹ̀bùn ati agbára Ọlọrun pọ̀ lọ́wọ́ rẹ̀. Àwọn kan wá láti ilé ìpàdé kan tí à ń pè ní ti àwọn Olómìnira, ti àwọn ará Kurene ati àwọn ará Alẹkisandria; wọ́n tako Stefanu. Àwọn tí wọ́n wá láti Silisia ati láti Esia náà sì bẹ̀rẹ̀ sí bá a jiyàn. Ṣugbọn wọn kò lè fèsì sí irú ọgbọ́n ati ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀. Wọ́n bá rú àwọn eniyan nídìí, láti sọ pé, “A gbọ́ nígbà tí ó ń sọ ìsọkúsọ sí Mose ati sí Ọlọrun.” Wọ́n rú àwọn eniyan ati àwọn àgbààgbà ati àwọn amòfin nídìí, ni wọ́n bá mú un, wọ́n fà á lọ siwaju àwọn ìgbìmọ̀. Wọ́n wá àwọn ẹlẹ́rìí èké tí wọ́n sọ pé, “Ọkunrin yìí kò yé sọ̀rọ̀ lòdì sí Tẹmpili mímọ́ yìí ati sí òfin Mose. Nítorí a gbọ́ nígbà tí ó sọ pé Jesu ti Nasarẹti yóo wó ilé yìí, yóo yí àwọn àṣà tí Mose fún wa pada.” Gbogbo àwọn tí ó jókòó ní ìgbìmọ̀ tẹjú mọ́ ọn, wọ́n rí ojú rẹ̀ tí ó dàbí ojú angẹli.
Iṣe Apo 6:8-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Stefanu tí ó kún fún oore-ọ̀fẹ́ àti agbára, ó ṣe iṣẹ́ ìyanu, àti iṣẹ́ ààmì ńlá láàrín àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n àwọn kan dìde nínú àwọn ti ń ṣe ara Sinagọgu, tí a ń pè ní Libataini. Àwọn Júù Kirene àti ti Alekisandiria àti ti Kilikia, àti ti Asia wá, wọ́n ń bá Stefanu jiyàn, ṣùgbọ́n wọn kò sí lè ko ọgbọ́n àti Ẹ̀mí tí ó fi ń sọ̀rọ̀ lójú. Nígbà náà ni wọ́n fún àwọn ọkùnrin kan ní àbẹ̀tẹ́lẹ̀, kí wọn ń wí pé, “Àwa gbọ́ tí Stefanu ń sọ ọ̀rọ̀-òdì sí Mose àti sí Ọlọ́run.” Wọ́n sí ru àwọn ènìyàn sókè, àti àwọn alàgbà, àti àwọn olùkọ́ni ní òfin. Wọ́n dìde sí i, wọ́n gbá a mú, wọ́n sì mú un wá sí iwájú àjọ ìgbìmọ̀. Wọ́n sí mú àwọn ẹlẹ́rìí èké wá, tiwọn wí pé, “Ọkùnrin yìí kò sinmi láti sọ ọ̀rọ̀-òdì sí ibi mímọ́ yìí, àti sí òfin. Nítorí àwa gbọ́ o wí pé Jesu ti Nasareti yìí yóò fọ́ ibí yìí, yóò sì yí àṣà ti Mose fi fún wa padà.” Gbogbo àwọn tí ó sì jókòó ni àjọ ìgbìmọ̀ tẹjúmọ́ Stefanu, wọ́n sì rí ojú rẹ̀ dàbí ojú angẹli.