Iṣe Apo 3:1-8
Iṣe Apo 3:1-8 Bibeli Mimọ (YBCV)
NJẸ Peteru on Johanu jumọ ngòke lọ si tẹmpili ni wakati adura, ti iṣe wakati kẹsan ọjọ. Nwọn si gbé ọkunrin kan ti o yarọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti nwọn ima gbé kalẹ li ojojumọ́ li ẹnu-ọna tẹmpili ti a npè ni Daradara, lati mã ṣagbe lọwọ awọn ti nwọ̀ inu tẹmpili lọ; Nigbati o ri Peteru on Johanu bi nwọn ti fẹ wọ̀ inu tẹmpili, o ṣagbe. Peteru si tẹjumọ́ ọ, pẹlu Johanu, o ni, Wò wa. O si fiyesi wọn, o nreti ati ri nkan gbà lọwọ wọn. Peteru wipe, Fadakà ati wura emi kò ni; ṣugbọn ohun ti mo ni eyini ni mo fifun ọ: Li orukọ Jesu Kristi ti Nasareti, dide ki o si mã rin. O si fà a li ọwọ́ ọtún, o si gbé e dide: li ojukanna ẹsẹ rẹ̀ ati egungun kokosẹ rẹ̀ si mokun. O si nfò soke, o duro, o si bẹrẹ si rin, o si ba wọn wọ̀ inu tẹmpili lọ, o nrìn, o si nfò, o si nyìn Ọlọrun.
Iṣe Apo 3:1-8 Yoruba Bible (YCE)
Ní agogo mẹta ọ̀sán, Peteru ati Johanu gòkè lọ sí Tẹmpili ní àkókò adura. Ọkunrin kan wà tí wọn máa ń gbé wá sibẹ, tí ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá. Lojoojumọ, wọn á máa gbé e wá sí ẹnu ọ̀nà Tẹmpili tí à ń pè ní “Ẹnu Ọ̀nà Dáradára,” kí ó lè máa ṣagbe lọ́dọ̀ àwọn tí ń wọ inú Tẹmpili lọ. Nígbà tí ó rí Peteru ati Johanu tí wọ́n fẹ́ wọ inú Tẹmpili, ó ní kí wọ́n ta òun lọ́rẹ. Peteru ati Johanu tẹjú mọ́ ọn, Peteru ní, “Wò wá!” Ọkunrin náà bá ń wò wọ́n, ó ń retí pé wọn yóo fún òun ní nǹkan. Peteru bá sọ fún un pé, “N kò ní fadaka tabi wúrà, ṣugbọn n óo fún ọ ní ohun tí mo ní. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasarẹti, máa rìn.” Ó bá fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó gbé e dìde. Lẹsẹkẹsẹ ẹsẹ̀ rẹ̀ ati ọrùn-ẹsẹ̀ rẹ̀ bá mókun. Ó bá fò sókè, ó dúró, ó sì ń rìn. Ó bá tẹ̀lé wọn wọ inú Tẹmpili; ó ń rìn, ó ń fò sókè, ó sì ń yin Ọlọrun.
Iṣe Apo 3:1-8 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (BMYO)
Ní ọjọ́ kan Peteru àti Johanu jùmọ̀ ń gòkè lọ sí tẹmpili ní wákàtí àdúrà; tí í ṣe wákàtí mẹ́ta ọ̀sán. Wọn sì gbé ọkùnrin kan ti ó yarọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí wọ́n máa ń gbé kalẹ̀ lójoojúmọ́ ní ẹnu-ọ̀nà tẹmpili ti a ń pè ni Dáradára, láti máa ṣagbe lọ́wọ́ àwọn tí ń wọ inú tẹmpili lọ. Nígbà tí ó rí Peteru àti Johanu bí wọn tí fẹ́ wọ inú tẹmpili, ó ṣagbe. Peteru sì tẹjúmọ́ ọn, pẹ̀lú Johanu, ó ní “Wò wá!” Ó sì fiyèsí wọn, ó ń retí láti rí nǹkan láti gbà lọ́wọ́ wọn. Peteru wí pé, “Wúrà àti fàdákà èmi kò ní, ṣùgbọ́n ohun tí mo ní èyí náà ni mo fi fún ọ. Ní orúkọ Jesu Kristi ti Nasareti, dìde kí o sì máa rìn.” Ó sì fà á lọ́wọ́ ọ̀tún, ó sì gbé dìde; lójúkan náà ẹsẹ̀ rẹ̀ àti egungun kókósẹ̀ rẹ̀ sì mókun. Ó sì ń fò sókè, ó dúró, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí rìn, ó sì bá wọn wọ inú tẹmpili lọ, ó ń rìn, ó sì ń fò, ó sì yín Ọlọ́run.