Iṣe Apo 27:33-38
Iṣe Apo 27:33-38 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ki ẹ jẹun diẹ: nitori eyi ni fun igbala nyin: nitori irun kan kì yio re kuro li ori ẹnikan nyin. Nigbati o si wi nkan wọnyi, ti o si mu akara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun niwaju gbogbo wọn: nigbati o si bù u, o bẹ̀rẹ si ijẹ. Nigbana ni gbogbo wọn si daraya, awọn pẹlu si gbà onjẹ. Gbogbo wa ti mbẹ ninu ọkọ̀ na si jẹ ọrinlugba ọkàn o dí mẹrin. Nigbati nwọn jẹun yó tan, nwọn kó nkan danù kuro ninu ọkọ̀, nwọn si kó alikama dà si omi.
Iṣe Apo 27:33-38 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun. Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun. Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276). Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i.
Iṣe Apo 27:33-38 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò gé kúrò lórí ẹnìkan nínú yín.” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ. Nígbà náà ni gbogbo wọ́n sì dárayá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ, Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó-dínmẹ́rin (276). Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi.