Iṣe Apo 27:21-44
Iṣe Apo 27:21-44 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn wà ni aijẹun li ọjọ pipọ, nigbana Paulu dide larin wọn, o ni, Alàgba, ẹnyin iba ti gbọ́ ti emi, ki a máṣe ṣikọ̀ kuro ni Krete, ewu ati òfo yi kì ba ti ba wa. Njẹ nisisiyi mo gbà nyin niyanju, ki ẹ tújuka: nitori kì yio si òfo ẹmí ninu nyin, bikoṣe ti ọkọ̀. Nitori angẹli Ọlọrun, ti ẹniti emi iṣe, ati ẹniti emi nsìn, o duro tì mi li oru aná, O wipe, Má bẹ̀ru, Paulu; iwọ kò le ṣaima duro niwaju Kesari: si wo o, Ọlọrun ti fi gbogbo awọn ti o ba ọ wọkọ̀ pọ̀ fun ọ. Njẹ nitorina, alàgba, ẹ daraya: nitori mo gbà Ọlọrun gbọ́ pe, yio ri bẹ̃ gẹgẹ bi a ti sọ fun mi. Ṣugbọn a ó gbá wa jù si erekuṣu kan. Ṣugbọn nigbati o di oru ijọ kẹrinla, ti awa ngbá sihin sọhún ni Adria, larin ọganjọ awọn atukọ̀ tànmã pe, awọn sunmọ eti ilẹ kan; Nigbati nwọn si wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn li ogún àgbaká: nigbati nwọn si sún siwaju diẹ, nwọn si tún wọ̀n okun, nwọn ri i o jìn ni àgbaká mẹ̃dogun. Nigbati nwọn bẹ̀ru ki nwọn ki o máṣe gbá lù ibi okuta, nwọn sọ idakọró mẹrin silẹ ni idi ọkọ̀, nwọn nreti ojumọ́. Ṣugbọn nigbati awọn atukọ̀ nwá ọ̀na ati sá kuro ninu ọkọ̀, ti nwọn si ti sọ igbaja kalẹ si oju okun bi ẹnipe nwọn nfẹ sọ idakọró silẹ niwaju ọkọ̀, Paulu wi fun balogun ọrún ati fun awọn ọmọ-ogun pe, Bikoṣepe awọn wọnyi ba duro ninu ọkọ̀ ẹnyin kì yio le là. Nigbana li awọn ọmọ-ogun ke okùn igbaja, nwọn jọwọ rẹ̀ ki o ṣubu sọhún. Nigbati ilẹ nmọ́ bọ̀, Paulu bẹ̀ gbogbo wọn ki nwọn ki o jẹun diẹ, o wipe, Oni li o di ijẹrinla ti ẹnyin ti nreti, ti ẹ kò dẹkun gbãwẹ, ti ẹ kò si jẹun. Nitorina mo bẹ̀ nyin, ki ẹ jẹun diẹ: nitori eyi ni fun igbala nyin: nitori irun kan kì yio re kuro li ori ẹnikan nyin. Nigbati o si wi nkan wọnyi, ti o si mu akara, o dupẹ lọwọ Ọlọrun niwaju gbogbo wọn: nigbati o si bù u, o bẹ̀rẹ si ijẹ. Nigbana ni gbogbo wọn si daraya, awọn pẹlu si gbà onjẹ. Gbogbo wa ti mbẹ ninu ọkọ̀ na si jẹ ọrinlugba ọkàn o dí mẹrin. Nigbati nwọn jẹun yó tan, nwọn kó nkan danù kuro ninu ọkọ̀, nwọn si kó alikama dà si omi. Nigbati ilẹ si mọ, nwọn kò mọ̀ ilẹ na: ṣugbọn nwọn ri apa odò kan ti o li ebute, nibẹ̀ ni nwọn gbero, bi nwọn o ba le tì ọkọ̀ si. Nigbati nwọn si ké idakọró kuro, nwọn jọ̀wọ wọn sinu okun, lẹsẹkanna nwọn tu ide ọkọ̀, nwọn si ta igbokun iwaju ọkọ̀ si afẹfẹ, nwọn wa kọju si ilẹ. Nigbati nwọn si de ibiti okun meji pade, nwọn fi ori ọkọ̀ sọlẹ; iwaju rẹ̀ si kàn mọlẹ ṣinṣin, o duro, kò le yi, ṣugbọn agbara riru omi bẹrẹ si fọ́ idi ọkọ̀ na. Ero awọn ọmọ-ogun ni ki a pa awọn onde, ki ẹnikẹni wọn ki o má ba wẹ̀ jade sá lọ. Ṣugbọn balogun ọrún nfẹ gbà Paulu là, o kọ̀ ero wọn; o si paṣẹ fun awọn ti o le wẹ̀ ki nwọn ki o kọ́ bọ si okun lọ si ilẹ, Ati awọn iyokù, omiran lori apako, ati omiran lori ẹfọkọ̀. Bẹ̃li o si ṣe ti gbogbo wọn yọ, li alafia de ilẹ.
Iṣe Apo 27:21-44 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn tí wọ́n ti wà fún ọpọlọpọ ọjọ́, láì jẹun, Paulu dìde dúró láàrin wọn, ó ní, “Ẹ̀yin eniyan, ẹ̀ bá ti gbọ́ tèmi kí ẹ má ṣíkọ̀ ní Kirete. Irú ewu ati òfò yìí ìbá tí sí. Ṣugbọn bí ó ti rí yìí náà, mo gbà yín níyànjú pé kí ẹ ṣara gírí. Ẹ̀mí ẹnikẹ́ni ninu yín kò ní ṣòfò; ọkọ̀ nìkan ni yóo ṣòfò. Nítorí ní alẹ́ àná, angẹli Ọlọrun mi, tí mò ń sìn dúró tì mí, ó ní, ‘Má bẹ̀rù, Paulu. Dandan ni kí o dé iwájú Kesari. Mo fẹ́ kí o mọ̀ pé Ọlọrun ti fi ẹ̀mí gbogbo àwọn ẹni tí ó wọkọ̀ pẹlu rẹ jíǹkí rẹ.’ Nítorí náà ẹ̀yin eniyan, ẹ ṣara gírí, nítorí mo gba Ọlọrun gbọ́ pé bí ó ti sọ fún mi ni yóo rí. Ṣugbọn ọkọ̀ wa yóo fàyà sọlẹ̀ ní erékùṣù kan.” Nígbà tí ó di alẹ́ kẹrinla tí afẹ́fẹ́ ti ń ti ọkọ̀ wa kiri ninu òkun Adiria, àwọn atukọ̀ fura ní òru pé a kò jìnnà sí ilẹ̀. Wọ́n sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ogoji mita. Nígbà tí a sún díẹ̀, wọ́n tún sọ ìwọ̀n sinu òkun, wọ́n rí i pé ó jìn tó ọgbọ̀n mita. Wọ́n wá ń bẹ̀rù pé kí ọkọ̀ má forí sọ òkúta. Wọ́n bá ju irin ìdákọ̀ró mẹrin sinu omi ní ẹ̀yìn ọkọ̀; wọ́n bá ń gbadura pé kí ilẹ̀ tètè mọ́. Àwọn atukọ̀ ń wá bí wọn yóo ti ṣe sálọ kúrò ninu ọkọ̀. Wọ́n bá sọ ọkọ̀ kékeré sórí òkun bí ẹni pé wọ́n fẹ́ sọ ìdákọ̀ró tí ó wà níwájú ọkọ̀ sinu òkun. Paulu wá sọ fún balogun ọ̀rún ati àwọn ọmọ-ogun náà pé, “Bí àwọn ará ibí yìí kò bá dúró ninu ọkọ̀, kò sí bí ẹ ti ṣe lè là.” Àwọn ọmọ-ogun bá gé okùn tí wọ́n fi so ọkọ̀ kékeré náà, wọ́n jẹ́ kí ìgbì gbé e lọ. Nígbà tí ilẹ̀ fẹ́rẹ̀ mọ́, Paulu gbà wọ́n níyànjú pé kí gbogbo wọn jẹun. Ó ní, “Ó di ọjọ́ mẹrinla lónìí, tí ọkàn yín kò tíì balẹ̀ tí ẹ̀ ń gbààwẹ̀; tí ẹ kò jẹ ohunkohun. Nítorí náà, mo bẹ̀ yín, ẹ jẹun; èyí ṣe pataki bí ẹ ò bá fẹ́ kú. Irun orí ẹnikẹ́ni kò tilẹ̀ ní ṣòfò.” Nígbà tí ó ti sọ báyìí tán, òun náà mú burẹdi, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọrun níwájú gbogbo wọn, ó bù ú, ó bá bẹ̀rẹ̀ sí jẹ ẹ́. Ni gbogbo wọn bá ṣara gírí, àwọn náà bá jẹun. Gbogbo àwa tí a wà ninu ọkọ̀ náà jẹ́ igba ó lé mẹrindinlọgọrin (276). Nígbà tí wọ́n jẹun yó tán, wọ́n da ọkà tí ó kù sinu òkun láti mú kí ọkọ̀ lè fúyẹ́ sí i. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, wọ́n rí èbúté ṣugbọn wọn kò mọ ibẹ̀. Wọ́n wá ṣe akiyesi ibìkan tí òkun ti wọ ààrin ilẹ̀ tí ó ní iyanrìn. Wọ́n rò pé bóyá àwọn lè tukọ̀ dé èbúté ibẹ̀. Wọ́n bá já àwọn ìdákọ̀ró, wọ́n jẹ́ kí wọ́n rì sinu omi. Ní àkókò yìí kan náà, wọ́n tú okùn lára àwọn ajẹ̀ tí wọ́n fi ń tukọ̀. Wọ́n wá ta aṣọ-ọkọ̀ tí ó wà lókè patapata níwájú ọkọ̀. Atẹ́gùn wá ń fẹ́ ọkọ̀ lọ sí èbúté. Ṣugbọn ọkọ̀ rọ́lu ilẹ̀ níbi tí òkun kò jìn, ni ó bá dúró gbọnin. Iwájú ọkọ̀ wọ inú iyanrìn, kò ṣe é yí. Ẹ̀yìn ọkọ̀ kò kanlẹ̀, ìgbì wá bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ọ bí ó ti ń bì lù ú. Àwọn ọmọ-ogun wá ń gbèrò pé kí àwọn pa àwọn ẹlẹ́wọ̀n, kí wọn má baà lúwẹ̀ẹ́ sálọ. Ṣugbọn balogun ọ̀rún kò jẹ́ kí àwọn ọmọ-ogun ṣe ìfẹ́ inú wọn, nítorí pé ó fẹ́ mú Paulu gúnlẹ̀ ní alaafia. Ó pàṣẹ pé kí àwọn tí ó bá lè lúwẹ̀ẹ́ kọ́kọ́ bọ́ sómi, kí wọ́n lúwẹ̀ẹ́ lọ sí èbúté. Kí àwọn yòókù wá tẹ̀lé wọn, kí wọ́n dì mọ́ pákó tabi kí wọ́n dì mọ́ ara ọkọ̀ tí ó ti fọ́. Báyìí ni gbogbo wa ṣe gúnlẹ̀ ní alaafia.
Iṣe Apo 27:21-44 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa. Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀. Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná. Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari: Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’ Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi. Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.” Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrín Òkun Adria, láàrín ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ funra pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan: Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀. Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!” Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèkéé, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún. Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun. Nítorí náà mo bẹ̀ yín, kí ẹ jẹun díẹ̀, nítorí èyí ni fún ìgbàlà yín: nítorí irun kan kí yóò gé kúrò lórí ẹnìkan nínú yín.” Nígbà tí ó sì wí nǹkan wọ̀nyí, tí ó sì mú àkàrà, ó dúpẹ́ lọ́wọ́ Ọlọ́run níwájú gbogbo wọn: nígbà tí ó si bù ú, ó bẹ̀rẹ̀ sí i jẹ. Nígbà náà ni gbogbo wọ́n sì dárayá, àwọn pẹ̀lú sì gba oúnjẹ, Gbogbo wa tí ń bẹ nínú ọkọ̀-òkun náà sì jẹ́ ọ̀rìnlúgba ènìyàn ó-dínmẹ́rin (276). Nígbà tí wọn jẹun yó tan, wọn bẹ̀rẹ̀ sí mu ọkọ̀-òkun náà fúyẹ́, nípa kíkó alikama dà sí omi. Nígbà tí ilẹ̀ sí mọ́, wọn kò mọ́ ilẹ̀ náà; ṣùgbọ́n wọn rí apá odò kan tí ó ní èbúté, níbẹ̀ ni wọ́n gbèrò, bóyá ó le ṣe é ṣe láti mu ọkọ̀ gúnlẹ̀. Nígbà tí wọ́n sì gé ìdákọ̀ró kúrò, wọn jù wọn sínú Òkun, lẹ́sẹ̀kan náà wọn tú ìdè-ọkọ̀, wọn sì ta ìgbokùn iwájú ọkọ̀ sí afẹ́fẹ́, wọn sì wakọ̀ kọjú sí etí Òkun. Nígbà tí wọ́n sì dé ibi tí Òkun méjì pàdé, wọn fi orí ọkọ̀ sọlẹ̀: iwájú rẹ̀ sì kàn mọ́lẹ̀ ṣinṣin, ó dúró, kò lè yí, ṣùgbọ́n agbára rírú omi bẹ̀rẹ̀ sí fọ́ ìdí ọkọ̀ náà. Èrò àwọn ọmọ-ogun ni ki a pa àwọn òǹdè, kí ẹnikẹ́ni wọn má ba à wẹ̀ jáde sálọ. Ṣùgbọ́n balógun ọ̀rún ń fẹ́ gba Paulu là, ó kọ èrò wọn, ó sì pàṣẹ fún àwọn tí ó lè wẹ̀ kí wọn bọ́ sí Òkun lọ sì ilẹ̀. Àti àwọn ìyókù, òmíràn lórí pátákó, àti òmíràn lórí àwọn igi tí ó ya kúrò lára ọkọ̀. Bẹ́ẹ̀ ni ó ṣe tí gbogbo wọn yọ, ní àlàáfíà dé ilẹ̀.