Iṣe Apo 26:1-32

Iṣe Apo 26:1-32 Bibeli Mimọ (YBCV)

AGRIPPA si wi fun Paulu pe, A fun ọ làye lati sọ ti ẹnu rẹ. Nigbana ni Paulu nawọ́, o si sọ ti ẹnu rẹ̀ pe: Agrippa ọba, inu emi tikarami dùn nitoriti emi o wi ti ẹnu mi loni niwaju rẹ, niti gbogbo nkan ti awọn Ju nfi mi sùn si. Pãpã bi iwọ ti mọ̀ gbogbo iṣe ati ọ̀ran ti mbẹ lãrin awọn Ju dajudaju, nitorina emi bẹ̀ ọ ki iwọ ki o fi sũru gbọ temi. Iwà aiye mi lati igba ewe mi, bi o ti ri lati ibẹrẹ, lãrin orilẹ-ede mi ati ni Jerusalemu, ni gbogbo awọn Ju mọ̀. Nitori nwọn mọ̀ mi lati ipilẹṣẹ, bi nwọn ba fẹ́ jẹri pe, gẹgẹ bi ẹya ìsin wa ti o le julọ, Farisi li emi. Ati nisisiyi nitori ireti ileri ti Ọlọrun ti ṣe fun awọn baba wa ni mo ṣe duro nihin fun idajọ. Ileri eyiti awọn ẹ̀ya wa mejejila ti nfi itara sin Ọlọrun lọsan ati loru ti nwọn nreti ati ri gba. Nitori ireti yi li awọn Ju ṣe nfi mi sùn, Agrippa Ọba. Ẽṣe ti ẹnyin fi rò o si ohun ti a kò le gbagbọ́ bi Ọlọrun ba jí okú dide? Emi tilẹ rò ninu ara mi nitõtọ pe, o yẹ ki emi ki o ṣe ọpọlọpọ ohun òdi si orukọ Jesu ti Nasareti. Eyi ni mo si ṣe ni Jerusalemu: awọn pipọ ninu awọn enia mimọ́ ni mo há mọ́ inu tubu, nigbati mo ti gbà aṣẹ lọdọ awọn olori alufa; nigbati nwọn si npa wọn, mo li ohùn si i. Nigbapipọ ni mo ṣẹ́ wọn niṣẹ ninu gbogbo sinagogu, mo ndù u lati mu wọn sọ ọrọ-odi; nigbati mo ṣoro si wọn gidigidi, mo ṣe inunibini si wọn de àjeji ilu. Ninu rẹ̀ na bi mo ti nlọ si Damasku ti emi ti ọlá ati aṣẹ ikọ̀ lati ọdọ awọn olori alufa lọ, Li ọsangangan, Ọba, mo ri imọlẹ kan lati ọrun wá, o jù riràn õrùn lọ, o mọlẹ yi mi ká, ati awọn ti o mba mi rè ajo. Nigbati gbogbo wa si ṣubu lulẹ, mo gbọ́ ohùn ti nfọ̀ si mi ni ède Heberu pe, Saulu, Saulu, ẽṣe ti iwọ fi nṣe inunibini si mi? Ohun irora ni fun ọ lati tapá si ẹgún. Emi si wipe, Iwọ tani, Oluwa? Oluwa si wipe, Emi ni Jesu ti iwọ nṣe inunibini si. Ṣugbọn dide, ki o si fi ẹsẹ rẹ tẹlẹ: nitori eyi ni mo ṣe farahàn ọ lati yàn ọ ni iranṣẹ ati ẹlẹri, fun ohun wọnni ti iwọ ti ri, ati ohun wọnni ti emi ó fi ara hàn fun ọ; Emi o ma gbà ọ lọwọ awọn enia, ati lọwọ awọn Keferi, ti emi rán ọ si nisisiyi, Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi. Nitorina, Agrippa ọba, emi kò ṣe aigbọran si iran ọ̀run na. Ṣugbọn mo kọ́ sọ fun awọn ti o wà ni Damasku, ati ni Jerusalemu, ati já gbogbo ilẹ Judea, ati fun awọn Keferi, ki nwọn ki o ronupiwada, ki nwọn si yipada si Ọlọrun, ki nwọn mã ṣe iṣẹ ti o yẹ si ironupiwada. Nitori nkan wọnyi li awọn Ju ṣe mu mi ni tẹmpili, ti nwọn si fẹ pa mi. Ṣugbọn bi mo si ti ri iranlọwọ gbà lọdọ Ọlọrun, mo duro titi o fi di oni, mo njẹri fun ati ewe ati àgba, emi kò sọ ohun miran bikoṣe ohun ti awọn woli ati Mose ti wipe yio ṣẹ: Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi. Bi o si ti nsọ t'ẹnu rẹ̀, Festu wi li ohùn rara pe, Paulu, ori rẹ bajẹ; ẹkọ́ akọjù ba ọ li ori jẹ. Ṣugbọn Paulu wipe, Ori mi kò bajẹ, Festu ọlọlá julọ; ṣugbọn ọ̀rọ otitọ ati ti ìwa airekọja li emi nsọ jade. Nitori ọba mọ̀ nkan gbogbo wọnyi, niwaju ẹniti emi nsọ̀rọ li aibẹ̀ru: nitori mo gbagbọ pe ọkan ninu nkan wọnyi kò pamọ fun u, nitoriti a kò ṣe nkan yi ni ìkọkọ. Agrippa ọba, iwọ gbà awọn woli gbọ́? Emi mọ̀ pe, iwọ gbagbọ́. Agrippa si wi fun Paulu pe, Pẹlu ọrọ iyanju diẹ si i, iwọ iba sọ mi di Kristiani. Paulu si wipe, Iba wu Ọlọrun, yala pẹlu ãpọn diẹ tabi pipọ pe, ki o maṣe iwọ nikan, ṣugbọn ki gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ mi loni pẹlu le di iru enia ti emi jẹ laisi ẹwọn wọnyi. Nigbati o si sọ nkan wọnyi tan, ọba dide, ati bãlẹ, ati Bernike, ati awọn ti o ba wọn joko: Nigbati nwọn lọ si apakan, nwọn ba ara wọn sọ pe, ọkunrin yi kò ṣe nkankan ti o yẹ si ikú tabi si ẹ̀wọn. Agrippa si wi fun Festu pe, A ba dá ọkunrin yi silẹ ibamaṣepe kò ti fi ọ̀ran rẹ̀ lọ Kesari.

Iṣe Apo 26:1-32 Yoruba Bible (YCE)

Agiripa wá yíjú sí Paulu, ó ní, “Ọ̀rọ̀ kàn ọ́. Sọ tìrẹ.” Paulu bá nawọ́, ó bẹ̀rẹ̀ sí ro ẹjọ́ tirẹ̀. Ó ní: “Agiripa Ọba Aláyélúwà, mo ka ara mi sí olóríire pé níwájú yín ni n óo ti dáhùn sí gbogbo ẹjọ́ tí àwọn Juu pè mí lónìí, pàápàá nítorí ẹ mọ gbogbo àṣà àwọn Juu dáradára, ẹ sì mọ àríyànjiyàn tí ó wà láàrin wọn. Nítorí náà mo bẹ̀ yín kí ẹ fi sùúrù gbọ́ ọ̀rọ̀ mi. “Gbogbo àwọn Juu ni wọ́n mọ̀ bí mo ti lo ìgbésí ayé mi láti ìbẹ̀rẹ̀ ní ìgbà èwe mi nígbà tí mò ń gbé Jerusalẹmu láàrin àwọn ọmọ orílẹ̀-èdè wa. Ó ti pẹ́ tí wọ́n ti mọ̀ mí. Bí wọn bá fẹ́, wọ́n lè jẹ́rìí sí i pé ọ̀nà àwọn Farisi ni mo tẹ̀lé ninu ẹ̀sìn ìbílẹ̀ wa, ọ̀nà yìí ló sì le jù. Wàyí ò! Ohun tí ó mú mi dúró nílé ẹjọ́ nisinsinyii ni pé mo ní ìrètí pé ìlérí tí Ọlọrun ṣe fún àwọn baba wa yóo ṣẹ. Ìrètí yìí ni àwọn ẹ̀yà mejila tí ó wà ní orílẹ̀-èdè wa ní, tí wọ́n ṣe ń fi ìtara sin Ọlọrun tọ̀sán-tòru. Nítorí ohun tí à ń retí yìí ni àwọn Juu fi ń rojọ́ mi, Kabiyesi! Kí ló ṣe wá di ohun tí ẹnikẹ́ni ninu yín kò lè gbàgbọ́ pé Ọlọrun a máa jí òkú dìde?” “Nígbà kan rí èmi náà rò pé ó jẹ mí lógún láti tako orúkọ Jesu ará Nasarẹti. Kí ni n ò ṣe tán? Mo ṣe díẹ̀ ní Jerusalẹmu. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni mo tì mọ́lé, lẹ́yìn tí mo ti gba àṣẹ lọ́wọ́ àwọn olórí alufaa. Wọn á máa pa wọ́n báyìí, èmi náà á sì ní bẹ́ẹ̀ gan-an ló yẹ wọ́n. Mò ń lọ láti ilé ìpàdé kan dé ekeji, mo sì ń jẹ wọ́n níyà, bóyá wọn a jẹ́ fẹnu wọn gbẹ̀ṣẹ̀. Ẹ̀tanú náà pọ̀ sí wọn tó bẹ́ẹ̀ tí mo fi lé wọn dé ìlú òkèèrè pàápàá. “Irú eré báyìí ni mò ń sá tí mò fi ń lọ sí Damasku ní ọjọ́ kan, pẹlu ìwé àṣẹ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí alufaa. Kabiyesi, bí mo ti ń lọ lọ́nà lọ́sàn-án gangan, mo rí ìmọ́lẹ̀ láti ọ̀run tí ó mọ́lẹ̀ ju ti oòrùn lọ, tí ó tàn yí èmi ati àwọn tí ń bá mi lọ ká. Bí gbogbo wa ti ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn kan tí ó ń bá mi sọ̀rọ̀ ní èdè Heberu. Ó ní, ‘Saulu! Saulu! Kí ló dé tí o fi ń ṣe inúnibíni sí mi? O óo fara pa bí o bá ta igi ẹlẹ́gùn-ún nípàá.’ Mo wá bèèrè pé, ‘Ìwọ ta ni, Oluwa?’ Oluwa bá dáhùn ó ní, ‘Èmi ni Jesu tí ò ń ṣe inúnibíni sí. Dìde nàró. Ohun tí mo fi farahàn ọ́ nìyí: mo ti yàn ọ́ láti jẹ́ iranṣẹ mi, kí o lè jẹ́rìí ohun tí o rí, ati ohun tí n óo fihàn ọ́. N óo gbà ọ́ lọ́wọ́ àwọn eniyan Israẹli ati àwọn orílẹ̀-èdè yòókù tí n óo rán ọ sí. Kí á lè là wọ́n lójú, kí á sì lè yí wọn pada láti inú òkùnkùn sinu ìmọ́lẹ̀, kí á lè gbà wọ́n lọ́wọ́ àṣẹ Satani, kí á sì fi wọ́n lé ọwọ́ Ọlọrun; kí wọ́n lè ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ nípa gbígbà mí gbọ́; kí wọ́n sì lè ní ogún pẹlu àwọn tí a ti yà sọ́tọ̀ fún Ọlọrun.’ “Nítorí náà, Agiripa Ọba Aláyélúwà, n kò ṣe àìgbọràn sí ìran tí ó ti ọ̀run wá. Ṣugbọn mo kọ́kọ́ waasu fún àwọn tó wà ní Damasku, lẹ́yìn náà mo waasu fún àwọn tó wà ní Jerusalẹmu, ati ní gbogbo ilẹ̀ Judia, ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu. Mò ń kéde pé kí wọ́n ronupiwada, kí wọ́n yipada sí Ọlọrun, kí wọn máa ṣe ohun tí ó yẹ ẹni tí ó ti ronupiwada. Ìdí nìyí tí àwọn Juu fi mú mi ninu Tẹmpili, tí wọn ń fẹ́ pa mí. Ṣugbọn Ọlọrun ràn mí lọ́wọ́. Títí di ọjọ́ òní mo ti dúró láti jẹ́rìí fún àwọn mẹ̀kúnnù ati àwọn eniyan pataki. N kò sọ ohunkohun yàtọ̀ sí ohun tí àwọn wolii ati Mose sọ pé yóo ṣẹlẹ̀. Èyí ni pé Mesaya níláti jìyà; àtipé òun ni yóo kọ́ jí dìde kúrò ninu òkú tí yóo sì kéde iṣẹ́ ìmọ́lẹ̀ fún àwọn eniyan Ọlọrun ati fún àwọn tí kì í ṣe Juu.” Bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀ báyìí, Fẹstu ké mọ́ ọn pé, “Paulu, orí rẹ dàrú! Ìwé àmọ̀jù ti dà ọ́ lórí rú.” Paulu dáhùn ó ní, “Fẹstu ọlọ́lá, orí mi kò dàrú. Òtítọ́ ọ̀rọ̀ gan-an ni mò ń sọ. Gbogbo nǹkan wọnyi yé Kabiyesi, nítorí náà ni mo ṣe ń sọ ọ́ láìfòyà. Ó dá mi lójú pé kò sí ohun tí ó pamọ́ fún un ninu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí. Nítorí kì í ṣe ní kọ̀rọ̀ ni nǹkan wọnyi ti ṣẹlẹ̀. Agiripa Ọba Aláyélúwà, ṣé ẹ gba àwọn wolii gbọ́? Mo mọ̀ pé ẹ gbà wọ́n gbọ́.” Agiripa bá bi Paulu pé, “Kíákíá báyìí ni o rò pé o lè sọ mí di Kristẹni?” Paulu dáhùn, ó ní, “Ẹ̀bẹ̀ tí mò ń bẹ Ọlọrun ni pé, ó pẹ́ ni, ó yá ni, kí ẹ rí bí mo ti rí lónìí, láìṣe ti ẹ̀wọ̀n yìí. Kì í ṣe ẹ̀yin nìkan, ṣugbọn gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí.” Agiripa bá dìde pẹlu gomina ati Berenike ati gbogbo àwọn tí ó jókòó pẹlu wọn. Wọ́n bọ́ sápá kan, wọ́n ń sọ fún wọn pé, “Ọkunrin yìí kò ṣe ohunkohun tí ó fi jẹ̀bi ikú tabi ẹ̀wọ̀n.” Agiripa wá sọ fún Fẹstu pé, “À bá dá ọkunrin yìí sílẹ̀ bí kò bá jẹ́ pé ó ti ní kí á gbé ẹjọ́ òun lọ siwaju Kesari.”

Iṣe Apo 26:1-32 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Agrippa sì wí fún Paulu pé, “A fún ọ láààyè láti sọ tí ẹnu rẹ.” Nígbà náà ní Paulu ná ọwọ́, ó sì sọ ti ẹnu rẹ pé: “Agrippa ọba, inú èmi tìkára mi dùn nítorí tí èmi yóò wí ti ẹnu mi lónìí níwájú rẹ, ní ti gbogbo ẹ̀sùn tí àwọn Júù fi kan mi, pàápàá bí ìwọ tí mọ gbogbo àṣà àti ọ̀ràn tí ń bẹ́ láàrín àwọn Júù dájúdájú. Nítorí náà, èmi bẹ̀ ọ́ kí ìwọ fi sùúrù tẹ́tí gbọ́ tèmi. “Àwọn Júù mọ irú ìgbé ayé tí mo ń gbé láti ìgbà èwe mi, láti ìbẹ̀rẹ̀ ayé mi ní orílẹ̀-èdè mi àti ní Jerusalẹmu. Nítorí wọ́n mọ̀ mi láti ìpilẹ̀ṣẹ̀, bí wọ́n bá fẹ́ jẹ́rìí sí i, wí pé, gẹ́gẹ́ bí ẹ̀yà ìsìn wa tí ó lè jùlọ, Farisi ni èmi. Nísinsin yìí nítorí ìrètí ìlérí tí Ọlọ́run tí ṣe fún àwọn baba wa ni mo ṣe dúró níhìn-ín fún ìdájọ́. Ìlérí èyí tí àwọn ẹ̀yà wa méjèèjìlá tí ń fi ìtara sin Ọlọ́run lọ́sàn án àti lóru tí wọ́n ń retí àti rí i gbà. Ọba Agrippa, nítorí ìrètí yìí ni àwọn Júù ṣe ń fi mi sùn. Èéṣe tí ẹ̀yin fi rò o sí ohun tí a kò lè gbàgbọ́ bí Ọlọ́run bá jí òkú dìde? “Èmi tilẹ̀ rò nínú ará mi nítòótọ́ pé, ó yẹ ki èmi ṣe ọ̀pọ̀lọpọ̀ ohun lòdì sí orúkọ Jesu tí Nasareti. Èyí ni mo sì ṣe ni Jerusalẹmu. Pẹ̀lú àṣẹ tí mo tí gba lọ́dọ̀ àwọn olórí àlùfáà, mo sọ àwọn púpọ̀ nínú àwọn ènìyàn mímọ́ sí inú túbú, nígbà tí wọ́n sí ń pa wọ́n, mo ní ohùn sí i. Nígbà púpọ̀ ni mo ń fi ìyà jẹ wọ́n láti inú Sinagọgu dé inú Sinagọgu, mo ń fi tipá mú wọn láti sọ ọ̀rọ̀-òdì. Mo sọ̀rọ̀ lòdì sí wọn gidigidi, kódà mo wá wọn lọ sí ìlú àjèjì láti ṣe inúnibíni sí wọn. “Nínú irú ìrìnàjò yìí ní mo ń bá lọ sí Damasku pẹ̀lú ọlá àti àṣẹ ikọ̀ láti ọ̀dọ̀ àwọn olórí àlùfáà. Ni ọ̀sán gangan, ìwọ ọba Agrippa, bí mo ti wà ní ojú ọ̀nà, mo rí ìmọ́lẹ̀ kan láti ọ̀run wá, tí ó mọ́lẹ̀ ju oòrùn lọ, ó mọ́lẹ̀ yí mi ká, àti àwọn tí ń bá mi lọ sì àjò. Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’ “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’ “Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí. Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ: Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’ “Nítorí náà, Agrippa ọba, èmi kò ṣe àìgbọ́ràn sì ìran ọ̀run náà. Ṣùgbọ́n mo kọ́kọ́ sọ fún àwọn tí ó wà ní Damasku, àti ní Jerusalẹmu, àti já gbogbo ilẹ̀ Judea, àti fún àwọn kèfèrí, kí wọn ronúpìwàdà, kí wọ́n sì yípadà sí Ọlọ́run, kí wọn máa ṣe iṣẹ́ tí ó yẹ sì ìrònúpìwàdà. Nítorí nǹkan wọ̀nyí ni àwọn Júù ṣe gbá mi mú nínú tẹmpili, tí wọ́n sì ń fẹ́ pa mí. Ṣùgbọ́n bí mo sì tí ri ìrànlọ́wọ́ gbà láti ọ́dọ̀ Ọlọ́run, mo dúró títí ó fi di òní, mo ń jẹ́rìí fún èwe àti àgbà, èmi kò sọ ohun mìíràn bí kò ṣe ohun tí àwọn wòlíì àti Mose tí wí pé, yóò ṣẹ: Pé, Kristi yóò jìyà, àti pé òun ni yóò jẹ́ ẹni àkọ́kọ́ láti jíǹde kúrò nínú òkú, òun ni yóò sí kéde ìmọ́lẹ̀ fún àwọn ènìyàn àti fún àwọn aláìgbàgbọ́.” Bí ó sì ti ń sọ tẹnu rẹ̀, Festu wí ní ohùn rara pé, “Paulu! Orí rẹ dàrú; ẹ̀kọ́ àkọ́jù rẹ ti dà ọ́ ní orí rú!” Paulu dalóhùn wí pé, “Orí mi kò dàrú, Festu ọlọ́lá jùlọ; ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ òtítọ́ àti ọ̀rọ̀ òye ni èmi ń sọ jáde. Nítorí ọba mọ̀ gbogbo nǹkan wọ̀nyí, níwájú ẹni tí èmi ń sọ̀rọ̀ ni àìbẹ̀rù: nítorí mo gbàgbọ́ pé ọ̀kan nínú nǹkan wọ̀nyí kò pamọ́ fún un, nítorí tí a kò ṣe nǹkan yìí ní ìkọ̀kọ̀. Agrippa ọba, ìwọ gba àwọn wòlíì gbọ́ bí? Èmi mọ̀ pé ìwọ gbàgbọ́.” Agrippa sì wí fún Paulu pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lérò pé ìwọ le fi àkókò díẹ̀ yìí sọ mí di Kristiani?” Paulu sì dáhùn wí pé, “Ní àkókò kúkúrú tàbí gígùn, mo gbàdúrà sí Ọlọ́run pé kí ó má ṣe ìwọ nìkan, ṣùgbọ́n kí gbogbo àwọn tí ó gbọ́ ọ̀rọ̀ mi lónìí pẹ̀lú lè di irú ènìyàn tí èmi jẹ́ láìsí ẹ̀wọ̀n wọ̀nyí.” Nígbà tí ó sì sọ nǹkan wọ̀nyí tan, ọba dìde, àti baálẹ̀, àti Bernike, àti àwọn tí o bá wọn jókòó; Nígbà tí wọn wọ ìyẹ̀wù lọ, wọn bá ara wọn jíròrò, wọ́n sọ pé, “Ọkùnrin yìí kò ṣe nǹkan kan tí ó yẹ sí ikú tàbí sì ẹ̀wọ̀n.” Agrippa sì wí fún Festu pé, “A bà dá ọkùnrin yìí sílẹ̀ bí ó bá ṣe pe kò ì tí ì fi ọ̀ràn rẹ̀ lọ Kesari.”