Iṣe Apo 21:1-17
Iṣe Apo 21:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí a dágbére fún wọn tán, ọkọ̀ ṣí. A wá lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ keji a dé Rodọsi. Láti ibẹ̀ a lọ sí Patara. A rí ọkọ̀ ojú omi kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ sọdá lọ sí Fonike. Ni a bá wọ̀ ọ́, ọkọ̀ bá ṣí. Nígbà tí à ń wo Kipru lókèèrè, a gba ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ibẹ̀ kọjá, a bá ń bá ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Siria. A gúnlẹ̀ ní ìlú Tire, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ já ẹrù ọkọ̀ sí. A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura. Ni a bá dágbére fún ara wa, a wọ inú ọkọ̀, àwọn sì pada lọ sí ilé wọn. Láti Tire, a bá ń bá ìrìn àjò wa lọ títí a fi dé Tolemaisi. Níbẹ̀ a lọ kí àwọn onigbagbọ, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ keji, a gbéra, a lọ sí Kesaria. A wọ ilé Filipi, ajíyìnrere, ọ̀kan ninu àwọn meje tí àwọn ìjọ Jerusalẹmu yàn ní ijọ́sí. Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a dé sí. Ó ní ọmọbinrin mẹrin. Wundia ni wọ́n, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. A wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí à ń wí yìí ni Agabu aríran kan dé láti Judia. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.” Nígbà tí a gbọ́ ohun tí Agabu wí, àwa ati àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ bẹ Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.” Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.” Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀.
Iṣe Apo 21:1-17 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si ṣe, nigbati awa kuro lọdọ wọn, ti a sì ṣikọ̀, awa ba ọ̀na tàra wá si Kosi, ni ijọ keji a si lọ si Rodu, ati lati ibẹ̀ lọ si Patara: Nigbati awa si ri ọkọ̀ kan ti nrekọja lọ si Fenike, awa wọ̀ ọkọ̀, a si ṣí. Nigbati awa si ti ri Kipru li òkere, ti awa fi i si ọwọ́ òsi, awa gbé ori ọkọ̀ le Siria, a si gúnlẹ ni Tire: nitori nibẹ̀ li ọkọ̀ yio gbé kó ẹrù silẹ. Nigbati a si ri awọn ọmọ-ẹhin, awa duro nibẹ̀ ni ijọ meje: awọn ẹniti o tipa Ẹmí wi fun Paulu pe, ki o máṣe lọ si Jerusalemu. Nigbati a si ti lò ọjọ wọnni tan, awa jade, a si mu ọ̀na wa pọ̀n; gbogbo nwọn si sìn wa, pẹlu awọn obinrin ati awọn ọmọde titi awa fi jade si ẹhin ilu: nigbati awa si gunlẹ li ebute, awa si gbadura. Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn. Nigbati a si ti pari àjo wa lati Tire, awa de Ptolemai; nigbati a si kí awọn ará, awa si ba wọn gbé ni ijọ kan. Ni ijọ keji awa lọ kuro, a si wá si Kesarea: nigbati awa si wọ̀ ile Filippi Efangelisti, ọkan ninu awọn meje nì; awa si wọ̀ sọdọ rẹ̀. Ọkunrin yi si li ọmọbinrin mẹrin, wundia, ti ima sọtẹlẹ. Bi a si ti wà nibẹ̀ li ọjọ pipọ, woli kan ti Judea sọkalẹ wá, ti a npè ni Agabu. Nigbati o si de ọdọ wa, o mu amure Paulu, o si de ara rẹ̀ li ọwọ́ on ẹsẹ, o si wipe, Bayi li Ẹmí Mimọ́ wi, Bayi li awọn Ju ti o wà ni Jerusalemu yio de ọkunrin ti o ni amure yi, nwọn o si fi i le awọn Keferi lọwọ. Nigbati a si ti gbọ́ nkan wọnyi, ati awa, ati awọn ará ibẹ̀ na bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe gòke lọ si Jerusalemu. Nigbana ni Paulu dahùn wipe, Ewo li ẹnyin nṣe yi, ti ẹnyin nsọkun, ti ẹ si nmu ãrẹ̀ ba ọkàn mi; nitori emi mura tan, kì iṣe fun didè nikan, ṣugbọn lati kú pẹlu ni Jerusalemu, nitori orukọ Jesu Oluwa. Nigbati a kò le pa a li ọkàn dà, awa dakẹ, wipe, Ifẹ ti Oluwa ni ki a ṣe. Lẹhin ijọ wọnni, awa palẹmọ, a si gòke lọ si Jerusalemu. Ninu awọn ọmọ-ẹhin lati Kesarea ba wa lọ, nwọn si mu Mnasoni ọmọ-ẹhin lailai kan pẹlu wọn, ará Kipru, lọdọ ẹniti awa ó gbé wọ̀. Nigbati awa si de Jerusalemu, awọn arakunrin si fi ayọ̀ gbà wa.
Iṣe Apo 21:1-17 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí a dágbére fún wọn tán, ọkọ̀ ṣí. A wá lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ keji a dé Rodọsi. Láti ibẹ̀ a lọ sí Patara. A rí ọkọ̀ ojú omi kan níbẹ̀ tí ó fẹ́ sọdá lọ sí Fonike. Ni a bá wọ̀ ọ́, ọkọ̀ bá ṣí. Nígbà tí à ń wo Kipru lókèèrè, a gba ẹ̀gbẹ́ ọ̀tún ibẹ̀ kọjá, a bá ń bá ọkọ̀ lọ sí ilẹ̀ Siria. A gúnlẹ̀ ní ìlú Tire, nítorí níbẹ̀ ni wọ́n fẹ́ já ẹrù ọkọ̀ sí. A bá àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kan níbẹ̀, a bá dúró tì wọ́n níbẹ̀ fún ọjọ́ meje. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu yìí sọ ohun tí Ẹ̀mí Mímọ́ fihàn wọ́n fún Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí ọjọ́ tí a óo gbé níbẹ̀ pé, a gbéra láti máa bá ìrìn àjò wa lọ. Gbogbo wọn ati àwọn iyawo wọn ati àwọn ọmọ wọn sìn wá dé ẹ̀yìn odi. A bá kúnlẹ̀ lórí iyanrìn ní èbúté, a gbadura. Ni a bá dágbére fún ara wa, a wọ inú ọkọ̀, àwọn sì pada lọ sí ilé wọn. Láti Tire, a bá ń bá ìrìn àjò wa lọ títí a fi dé Tolemaisi. Níbẹ̀ a lọ kí àwọn onigbagbọ, a sì dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ keji, a gbéra, a lọ sí Kesaria. A wọ ilé Filipi, ajíyìnrere, ọ̀kan ninu àwọn meje tí àwọn ìjọ Jerusalẹmu yàn ní ijọ́sí. Lọ́dọ̀ rẹ̀ ni a dé sí. Ó ní ọmọbinrin mẹrin. Wundia ni wọ́n, wọn a sì máa sọ àsọtẹ́lẹ̀. A wà níbẹ̀ fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí à ń wí yìí ni Agabu aríran kan dé láti Judia. Nígbà tí ó wá sọ́dọ̀ wa, ó mú ọ̀já ìgbànú Paulu, ó fi de ara rẹ̀ tọwọ́-tẹsẹ̀. Ó ní, “Ẹ gbọ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti wí: Báyìí ni àwọn Juu yóo di ọkunrin tí ó ni ọ̀já ìgbànú yìí ní Jerusalẹmu; wọn yóo sì fà á lé àwọn tí kì í ṣe Juu lọ́wọ́.” Nígbà tí a gbọ́ ohun tí Agabu wí, àwa ati àwọn tí ó ń gbé ibẹ̀ bẹ Paulu pé kí ó má lọ sí Jerusalẹmu. Ṣugbọn Paulu dáhùn pé, “Kí ló dé tí ẹ̀ ń sunkún, tí ẹ̀ ń mú ìrẹ̀wẹ̀sì ọkàn bá mi? Mo ti múra ẹ̀wọ̀n ati ikú pàápàá ní Jerusalẹmu nítorí orúkọ Oluwa Jesu.” Nígbà tí a kò lè yí i lọ́kàn pada, a bá dákẹ́. A ní, “Ìfẹ́ Oluwa ni kí ó ṣẹ.” Lẹ́yìn tí a gbé ọjọ́ bíi mélòó kan ni Kesaria, a palẹ̀ mọ́, a bá gbọ̀nà, ó di Jerusalẹmu. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu ní Kesaria bá wa lọ. Wọ́n mú wa lọ sọ́dọ̀ ẹni tí a óo dé sí ilé rẹ̀, Minasoni ará Kipru kan báyìí tí ó ti di onigbagbọ tipẹ́tipẹ́. Nígbà tí a dé Jerusalẹmu, àwọn onigbagbọ gbà wá tayọ̀tayọ̀.
Iṣe Apo 21:1-17 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn tí àwa ti kúrò lọ́dọ̀ wọn, tí a sì ṣíkọ̀, àwa bá ọ̀nà wa lọ tààrà sí Kosi. Ní ọjọ́ kejì a sì lọ sí Rodu, àti gba ibẹ̀ lọ sí Patara: A rí ọkọ̀ ojú omi kan tí ń rékọjá lọ sí Fonisia, a wọ inú ọkọ̀ náà, a sì ṣíkọ̀. Nígbà tí àwa sì ń wo Saipurọsi lókèèrè, a sì fi í sí ọwọ́ òsì, a fi orí ọ́kọ̀ le Siria, a sì gúnlẹ̀ ni Tire; nítorí níbẹ̀ ni ọkọ̀ yóò tí já ẹrù sílẹ̀. Nígbà tí a sì ti rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn níbẹ̀, a dúró ní ọ̀dọ̀ wọn níbẹ̀ fún ọjọ́ méje: àwọn ẹni tí ó ti ipá Ẹ̀mí wí fún Paulu pé, kí ó má ṣe lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà tí a sì tí lo ọjọ́ wọ̀nyí tan, àwa jáde, a sì mu ọ̀nà wá pọ̀n; gbogbo wọn sì sìn wá, pẹ̀lú àwọn obìnrin àti àwọn ọmọdé títí àwa fi jáde sí ẹ̀yìn ìlú, nígbà tí àwa sì gúnlẹ̀ ní èbúté, a sì gbàdúrà. Nígbà tí a sì ti dágbére fún ara wa, a bọ́ sí ọkọ̀; bẹ́ẹ̀ ni àwọn sì padà lọ sí ilé wọn. Nígbà tí a sì ti parí àjò wa láti Tire, àwa dé Pitolemai; nígbà ti a sì kí àwọn ará, a sì bá wọn gbé ní ọjọ́ kan. Ní ọjọ́ kejì a lọ kúrò, a sì wá sí Kesarea; nígbà tí á sì wọ ilé Filipi efangelisti tí ó jẹ́ ọ̀kan nínú àwọn méje; àwa sì wọ̀ sọ́dọ̀ rẹ̀. Ọkùnrin yìí sì ní ọmọbìnrin mẹ́rin, wúńdíá, tí wọ́n máa ń sọtẹ́lẹ̀. Bí a sì tí wà níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, wòlíì kan tí Judea sọ̀kalẹ̀ wá, tí a ń pè ní Agabu. Nígbà tí ó sì dé ọ̀dọ̀ wa, ó mú àmùrè Paulu, ó sì de ara rẹ̀ ní ọwọ́ àti ẹsẹ̀, ó sì wí pé, “Báyìí ni Ẹ̀mí Mímọ́ wí: ‘Báyìí ni àwọn Júù tí ó wà ní Jerusalẹmu yóò de ọkùnrin tí ó ní àmùrè yìí, wọn ó sì fi í lé àwọn aláìkọlà lọ́wọ́.’ ” Nígbà tí a sì tí gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, àti àwa, àti àwọn ará ibẹ̀ náà bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Nígbà náà ni Paulu dáhùn wí pé, “Èwo ni ẹ̀yin ń ṣe yìí, tí ẹ̀yin ń sọkún, tí ẹ sì ń mú àárẹ̀ bá ọkàn mi; nítorí èmí tí múra tan, kì í ṣe fún dídè nìkan, ṣùgbọ́n láti kú pẹ̀lú ni Jerusalẹmu, nítorí orúkọ Jesu Olúwa.” Nígbà tí a kò lè pa á ní ọkàn dà, a dákẹ́ wí pé, “Ìfẹ́ tí Olúwa ni kí ó ṣe!” Lẹ́yìn ọjọ́ wọ̀nyí, a palẹ̀mọ́, a sì gòkè lọ sí Jerusalẹmu. Nínú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn láti Kesarea bá wa lọ, wọ́n sì mú wa lọ sí ilé Munasoni ọmọ-ẹ̀yìn àtijọ́ kan ara Saipurọsi, lọ́dọ̀ ẹni tí àwa yóò dé sí. Nígbà tí a sì dé Jerusalẹmu, àwọn arákùnrin sì fi ayọ̀ gbà wá