Iṣe Apo 20:18-21
Iṣe Apo 20:18-21 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nigbati nwọn si de ọdọ rẹ̀, o wi fun wọn pe, Ẹnyin tikaranyin mọ̀, lati ọjọ ikini ti mo ti de Asia, bi emi ti ba nyin gbé, ni gbogbo akoko na, Bi mo ti nfi ìrẹlẹ ọkàn gbogbo sìn Oluwa, ati omije pipọ, pẹlu idanwò, ti o bá mi, nipa ìdena awọn Ju: Bi emi kò ti fà sẹhin lati sọ ohunkohun ti o ṣ'anfani fun nyin, ati lati mã kọ́ nyin ni gbangba ati lati ile de ile, Ti mo nsọ fun awọn Ju, ati fun awọn Hellene pẹlu, ti ironupiwada sipa Ọlọrun, ati ti igbagbọ́ sipa Jesu Kristi Oluwa wa.
Iṣe Apo 20:18-21 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí wọ́n dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sọ fún wọn pé, “Ẹ mọ̀ bí mo ti lo gbogbo àkókò mi láàrin yín láti ìgbà tí mo ti kọ́kọ́ dé ilẹ̀ Esia. Ẹ mọ̀ bí mo ti fi ìrẹ̀lẹ̀ ati omi ojú sin Oluwa ní ọ̀nà gbogbo ninu àwọn ìṣòro tí mo fara dà nítorí ọ̀tẹ̀ tí àwọn Juu dì sí mi. Ẹ mọ̀ pé n kò dánu dúró láti sọ ohunkohun fun yín tí yóo ṣe yín ní anfaani; mò ń kọ yín ní gbangba ati ninu ilé yín. Mò ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu ati àwọn Giriki pé kí wọn yipada sí Ọlọrun, kí wọn ní igbagbọ ninu Oluwa Jesu.
Iṣe Apo 20:18-21 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nígbà tí wọ́n sì dé ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin tìkára yín mọ̀, láti ọjọ́ kìn-ín-ní tí mo tí dé Asia, bí mo ti bá yín gbé, ní gbogbo àkókò náà. Bí mo ti ń fi ìrẹ̀lẹ̀ inú gbogbo sin Olúwa, àti omijé púpọ̀, pẹ̀lú ìdánwò, tí ó bá mi, nípa rìkíṣí àwọn Júù: Bí èmí kò ti fàsẹ́yìn láti sọ ohunkóhun tí ó ṣàǹfààní fún un yín, àti láti máa kọ́ ọ yín ní gbangba àti láti ilé dé ilé. Tí mo ń sọ fún àwọn Júù, àti fún àwọn Giriki pẹ̀lú, ní ti ìrònúpìwàdà sí Ọlọ́run, àti ti ìgbàgbọ́ nínú Jesu Kristi Olúwa wa.