Iṣe Apo 2:44-47
Iṣe Apo 2:44-47 Bibeli Mimọ (YBCV)
Gbogbo awọn ti o si gbagbọ́ wà ni ibikan, nwọn ni ohun gbogbo ṣọkan; Nwọn si ntà ohun ini ati ẹrù wọn, nwọn si npín wọn fun olukuluku, gẹgẹ bi ẹnikẹni ti ṣe alaini. Nwọn si nfi ọkàn kan duro li ojojumọ́ ninu tẹmpili ati ni bibu akara ni ile, nwọn nfi inu didùn ati ọkàn kan jẹ onjẹ wọn. Nwọn nyin Ọlọrun, nwọn si ni ojurere lọdọ enia gbogbo. Oluwa si nyàn kún wọn li ojojumọ awọn ti a ngbalà.
Iṣe Apo 2:44-47 Yoruba Bible (YCE)
Gbogbo àwọn onigbagbọ wà ní ibìkan náà. Wọ́n jọ ní ohun gbogbo ní àpapọ̀. Wọ́n ta gbogbo ohun tí wọ́n ní, wọ́n sì pín owó tí wọ́n rí láàrin ara wọn, gẹ́gẹ́ bí ẹnìkọ̀ọ̀kan ti ṣe aláìní sí. Wọ́n ń fi ọkàn kan lọ sí Tẹmpili lojoojumọ. Wọ́n jọ ń jẹun láti ilé dé ilé. Wọ́n jọ ń jẹun pẹlu ayọ̀ ati pẹlu ọkàn kan. Wọ́n ń fi ìyìn fún Ọlọrun. Gbogbo àwọn eniyan ni ó fẹ́ràn wọn. Lojoojumọ ni àwọn tí wọ́n rí ìgbàlà ń dara pọ̀ mọ́ wọn.
Iṣe Apo 2:44-47 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Gbogbo àwọn tí ó sì gbàgbọ́ wà ni ibìkan, wọn ní ohun gbogbo sọ́kàn; Wọn si ń ta ohun ìní àti ẹrù wọn, wọn sì ń pín wọn fún olúkúlùkù, gẹ́gẹ́ bí ẹnikẹ́ni tí í ṣe aláìní sí. Wọ́n fi ọkàn kan dúró lójoojúmọ́ nínú tẹmpili. Wọ́n ń bu àkàrà ní ilé wọn, wọn ń fi inú dídùn àti ọkàn òtítọ́ jẹ oúnjẹ wọn. Wọ́n yín Ọlọ́run, wọn sì rí ojúrere lọ́dọ̀ ènìyàn gbogbo, Olúwa sí ń yàn kún wọn lójoojúmọ́, àwọn tí à ń gbàlà.