Iṣe Apo 2:36-41
Iṣe Apo 2:36-41 Bibeli Mimọ (YBCV)
Njẹ ki gbogbo ile Israeli ki o mọ̀ dajudaju pe, Ọlọrun ti fi Jesu na, ti ẹnyin kàn mọ agbelebu, jẹ Oluwa ati Kristi. Nigbati nwọn si gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ, nwọn si sọ fun Peteru ati awọn aposteli iyokù pe, Ará, kini ki awa ki o ṣe? Peteru si wi fun wọn pe, Ẹ ronupiwada, ki a si baptisi olukuluku nyin li orukọ Jesu Kristi fun idariji ẹ̀ṣẹ nyin, ẹnyin o si gbà ẹbun Ẹmi Mimọ́. Nitori fun nyin ni ileri na, ati fun awọn ọmọ nyin, ati fun gbogbo awọn ti o jìna rére, ani gbogbo awọn ti Oluwa Ọlọrun wa ó pè. Ati ọ̀rọ pupọ miran li o fi njẹri ti o si nfi ngbà wọn niyanju wipe, Ẹ gbà ara nyin là lọwọ iran arekereke yi. Nitorina awọn ti o si fi ayọ̀ gbà ọ̀rọ rẹ̀ a baptisi wọn: li ọjọ na a si kà ìwọn ẹgbẹdogun ọkàn kún wọn.
Iṣe Apo 2:36-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ǹjẹ́ kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájúdájú pé: Ọlọ́run ti fi Jesu náà, ti ẹ̀yin kàn mọ́ àgbélébùú, ṣe Olúwa àti Kristi.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, ọkàn wọn gbọgbẹ́, wọn sì wí fún Peteru àti àwọn aposteli yòókù pé, “Ará, kín ni àwa yóò ṣe?” Peteru sì wí fún wọn pé, “Ẹ ronúpìwàdà, kí a sì bamitiisi olúkúlùkù yín ní orúkọ Jesu Kristi fún ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ yín. Ẹ̀yin yóò sì gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ Nítorí fún yín ni ìlérí náà, àti fún àwọn ọmọ yín, àti fún gbogbo àwọn tí ó jìnnà réré, àní gbogbo àwọn tí Olúwa Ọlọ́run wa yóò pè.” Pẹ̀lú ọ̀rọ̀ púpọ̀ mìíràn ni ó fi ń kìlọ̀ tí ó sì ń fi ń rọ̀ wọ́n wí pé, “Ẹ gba ara yín là lọ́wọ́ ìran àrékérekè yìí.” Nítorí náà àwọn tí ó fi ayọ̀ gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ a bamitiisi wọn, lọ́jọ́ náà a sì kà ìwọ̀n ẹgbẹ̀rún mẹ́ta ọkàn kún wọn.
Iṣe Apo 2:36-41 Yoruba Bible (YCE)
“Nítorí náà kí gbogbo ilé Israẹli mọ̀ dájú pé Jesu yìí tí ẹ̀yin kàn mọ́ agbelebu ni Ọlọrun ti fi ṣe Oluwa ati Mesaya!” Nígbà tí àwọn eniyan gbọ́, ọ̀rọ̀ náà gún wọn lọ́kàn. Wọ́n wá bi Peteru ati àwọn aposteli yòókù pé, “Ẹ̀yin ará, kí ni kí á wá ṣe?” Peteru dá wọn lóhùn pé, “Ẹ ronupiwada, kí á ṣe ìrìbọmi fún ẹnìkọ̀ọ̀kan yín ní orúkọ Kristi. A óo sì dárí ẹ̀ṣẹ̀ yín jì yín, ẹ óo wá gba ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́. Nítorí ẹ̀yin ni a ṣe ìlérí yìí fún, ati àwọn ọmọ yín ati gbogbo àwọn tí wọ́n wà ní ọ̀nà jíjìn; a ṣe é fún gbogbo ẹni tí Oluwa Ọlọrun wa bá pè.” Ó tún bá wọn sọ̀rọ̀ pupọ, ó ń rọ̀ wọ́n gidigidi, pé, “Ẹ gba ara yín kúrò ninu ìyà tí ìran burúkú yìí yóo jẹ.” A ṣe ìrìbọmi fún àwọn tí wọ́n gba ọ̀rọ̀ náà. Ní ọjọ́ náà àwọn ẹgbẹẹdogun (3,000) eniyan ni a kà kún ọmọ ìjọ.