Iṣe Apo 2:22-23
Iṣe Apo 2:22-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ wọnyi: Jesu ti Nasareti, ọkunrin ti a fi hàn fun nyin lati ọdọ Ọlọrun wá, nipa iṣẹ agbara ati ti iyanu, ati ti àmi ti Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe lãrin nyin, bi ẹnyin tikaranyin ti mọ̀ pẹlu: Ẹniti a ti fi le nyin lọwọ nipa ipinnu ìmọ ati imọtẹlẹ Ọlọrun; on li ẹnyin mu, ti ẹ ti ọwọ awọn enia buburu kàn mọ agbelebu, ti ẹ si pa.
Iṣe Apo 2:22-23 Yoruba Bible (YCE)
“Ẹ̀yin ará, ọmọ Israẹli, ẹ fetí sí ọ̀rọ̀ mi. Jesu ará Nasarẹti ni ẹni tí Ọlọrun ti fihàn fun yín pẹlu iṣẹ́ agbára, iṣẹ́ ìyanu, iṣẹ́ abàmì tí Ọlọrun ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrin yín. Ẹ̀yin fúnra yín sì mọ̀ bẹ́ẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí ìfẹ́ Ọlọrun ati ètò tí Ọlọrun ti ṣe tẹ́lẹ̀, a fi í le yín lọ́wọ́, ẹ jẹ́ kí àwọn aláìbìkítà fún Òfin kàn án mọ́ agbelebu, ẹ sì pa á.
Iṣe Apo 2:22-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
“Ẹ̀yin ènìyàn Israẹli, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí; Jesu tí Nasareti, ọkùnrin tí a mọ̀ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá nípa iṣẹ́ agbára àti tí ìyanu, àti ààmì ti Ọlọ́run ti ọwọ́ rẹ̀ ṣe láàrín yín, bí ẹ̀yin tìkára yín ti mọ̀ pẹ̀lú. Ẹni tí a ti fi lé yín lọ́wọ́ nípa ìpinnu ìmọ̀ àti ìmọ̀tẹ́lẹ̀ Ọlọ́run; àti ẹ̀yin pẹ̀lú, pẹ̀lú ìrànlọ́wọ́ àwọn ènìyàn búburú kàn mọ́ àgbélébùú, tí a sì pa á.