Iṣe Apo 19:21-41

Iṣe Apo 19:21-41 Bibeli Mimọ (YBCV)

Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu. Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na. Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na. Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá; Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa. Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun. Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ. Nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn kún fun ibinu, nwọn kigbe, wipe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu. Nigbati Paulu si nfẹ wọ̀ ãrin awọn enia lọ, awọn ọmọ-ẹhin kò jẹ fun u. Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire. Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si. Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia. Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ? Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun. Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa. Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn. Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́. Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi. Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

Iṣe Apo 19:21-41 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.” Ó bá rán àwọn meji ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Timoti ati Erastu, lọ sí Masedonia ṣugbọn òun alára dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i ní Esia. Ní àkókò náà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tí kì í ṣe kékeré, nípa ọ̀nà Oluwa. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Demeteriu, alágbẹ̀dẹ fadaka. A máa fi fadaka ṣe ilé ìsìn ti oriṣa Atẹmisi; èyí a sì máa mú èrè pupọ wá fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà yìí. Demeteriu wá pe àpèjọ àwọn alágbẹ̀dẹ fadaka ati àwọn tí iṣẹ́ wọn fara jọra. Ó ní, “Ẹ̀yin eniyan wa, ẹ mọ̀ pé ninu iṣẹ́ yìí ni a ti ń rí èrè wa. Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa! Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!” Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré. Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un. Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú. Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ! Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run? Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun. Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa. Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀. Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé. Nítorí bí a ò bá ṣọ́ra, a óo dé ilé ẹjọ́ fún ìrúkèrúdò ọjọ́ òní, kò sì sí ohun tí a lè sọ pé ó fà á bí wọ́n bá bi wá.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó tú àwọn eniyan náà ká.

Iṣe Apo 19:21-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia. Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!” Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò. Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un. Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà. Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀. Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!” Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀? Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun. Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa. Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́. Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.” Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.