Iṣe Apo 19:13-16
Iṣe Apo 19:13-16 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu. Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃. Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin? Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa.
Iṣe Apo 19:13-16 Yoruba Bible (YCE)
Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.” Àwọn Juu meje kan tí wọn jẹ́ ọmọ Sikefa Olórí Alufaa wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?” Ni ọkunrin tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá fò mọ́ wọn; ó gbé ìjà ńlá kò wọ́n, ó sì ṣẹgun gbogbo wọn, ó ṣe wọ́n léṣe tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá jáde ninu ilé náà ní ìhòòhò, tàwọn ti ọgbẹ́ lára.
Iṣe Apo 19:13-16 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.” Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù. Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa.