Iṣe Apo 19:1-41

Iṣe Apo 19:1-41 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si ṣe, nigbati Apollo ti wà ni Korinti, ti Paulu kọja lọ niha ẹkùn oke, o wá si Efesu: o si ri awọn ọmọ-ẹhin kan; O wi fun wọn pe, Ẹnyin ha gbà Ẹmí Mimọ́ na nigbati ẹnyin gbagbọ́? Nwọn si wi fun u pe, Awa kò gbọ́ rara bi Ẹmí Mimọ́ kan wà. O si wipe, Njẹ baptismu wo li a ha baptisi nyin si? Nwọn si wipe, Si baptismu ti Johanu. Paulu si wipe, Nitõtọ, ni Johanu fi baptismu ti ironupiwada baptisi, o nwi fun awọn enia pe, ki nwọn ki o gbà ẹniti mbọ̀ lẹhin on gbọ, eyini ni Kristi Jesu. Nigbati nwọn si gbọ́, a baptisi wọn li orukọ Jesu Oluwa. Nigbati Paulu si gbe ọwọ́ le wọn, Ẹmí Mimọ́ si bà le wọn; nwọn si nfọ̀ ède miran, nwọn si nsọ asọtẹlẹ. Iye awọn ọkunrin na gbogbo to mejila. Nigbati o si wọ̀ inu sinagogu lọ, o fi igboiya sọ̀rọ li oṣù mẹta, o nfi ọ̀rọ̀ we ọ̀rọ̀, o si nyi wọn lọkan pada si nkan ti iṣe ti ijọba Ọlọrun. Ṣugbọn nigbati ọkàn awọn miran ninu wọn di lile, ti nwọn kò si gbagbọ́, ti nwọn nsọ̀rọ ibi si Ọna na niwaju ijọ enia, o lọ kuro lọdọ wọn, o si yà awọn ọmọ-ẹhin sọtọ̀, o si nsọ asọye li ojojumọ́ ni ile-iwe Tirannu. Eyi nlọ bẹ̃ fun iwọn ọdún meji; tobẹ̃ ti gbogbo awọn ti ngbe Asia gbọ́ ọ̀rọ Jesu Oluwa, ati awọn Ju ati awọn Hellene. Ọlọrun si ti ọwọ́ Paulu ṣe iṣẹ aṣẹ akanṣe, Tobẹ̃ ti a fi nmu gèle ati ibantẹ́ ara rẹ̀ tọ̀ awọn olokunrun lọ, arùn si fi wọn silẹ, ati awọn ẹmi buburu si jade kuro lara wọn. Ṣugbọn awọn Ju kan alarinkiri, alẹmi-èṣu-jade, dawọle e li adabọwọ ara wọn, lati pè orukọ Jesu Oluwa si awọn ti o li ẹmi buburu, wipe, Awa fi orukọ Jesu ti Paulu nwasu fi nyin bu. Awọn meje kan si wà, ọmọ ẹnikan ti a npè ni Skefa, Ju, ati olori kan ninu awọn alufa, ti nwọn ṣe bẹ̃. Ẹmi buburu na si dahùn, o ni, Jesu emi mọ̀, Paulu emi si mọ̀; ṣugbọn tali ẹnyin? Nigbati ọkunrin ti ẹmi buburu wà lara rẹ̀ si fò mọ́ wọn, o ba wọn dimú, o bori wọn, bẹ̃ni nwọn sá jade kuro ni ile na ni ìhoho ati ni ifarapa. Ihìn yi si di mimọ̀ fun gbogbo awọn Ju ati awọn ara Hellene pẹlu ti o ṣe atipo ni Efesu; ẹ̀ru si ba gbogbo wọn, a si gbé orukọ Jesu Oluwa ga. Ọ̀pọ awọn ti nwọn gbagbọ́ si wá, nwọn jẹwọ, nwọn si fi iṣẹ wọn hàn. Kì isi ṣe diẹ ninu awọn ti nṣe àlúpàyídà li o kó iwe wọn jọ, nwọn dáná sun wọn loju gbogbo enia: nwọn si ṣírò iye wọn, nwọn si ri i, o jẹ ẹgbã-mẹdọgbọ̀n iwọn fadaka. Bẹ̃li ọ̀rọ Oluwa si gbilẹ si i gidigidi, o si gbilẹ. Njẹ bi nkan wọnyi ti pari tan, Paulu pinnu rẹ̀ li ọkàn pe, nigbati on ba kọja ni Makedonia ati Akaia, on ó lọ si Jerusalemu, o wipe, Lẹhin igba ti mo ba de ibẹ̀, emi kò le ṣaima ri Romu pẹlu. Nigbati o si ti rán meji ninu awọn ti nṣe iranṣẹ fun u lọ si Makedonia, Timotiu ati Erastu, on tikararẹ̀ duro ni Asia ni igba diẹ na. Li akokò na èmìmì diẹ ki o wà nitori Ọna na. Nitori ọkunrin kan ti a npè ni Demetriu, alagbẹdẹ fadaka, ti ima fi fadaka ṣe ile-oriṣa fun Diana, o mu ère ti kò mọ̀ ni iwọn fun awọn oniṣọnà wá; Nigbati o pè wọn jọ, ati irú awọn ọlọnà bẹ̃, o ni, Alàgba, ẹnyin mọ̀ pe nipa iṣẹ-ọna yi li awa fi li ọrọ̀ wa. Ẹnyin si ri, ẹ si gbọ́ pe, kì iṣe ni Efesu nikanṣoṣo ni, ṣugbọn o fẹrẹ ṣe gbogbo Asia, ni Paulu yi nyi ọ̀pọ enia li ọkàn pada, ti o si ndari wọn wipe, Ohun ti a fi ọwọ́ ṣe, kì iṣe ọlọrun. Ki si iṣe pe kìki iṣẹ-ọnà wa yi li o wà li ewu ati di asan; ṣugbọn ile Diana oriṣa nla yio si di gigàn pẹlu, ati gbogbo ọla nla rẹ̀ yio si run, ẹniti gbogbo Asia ati gbogbo aiye mbọ. Nigbati nwọn gbọ́ ọ̀rọ wọnyi, nwọn kún fun ibinu, nwọn kigbe, wipe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. Gbogbo ilu na si kún fun irukerudò: nwọn fi ọkàn kan rọ́ sinu ile ibĩṣire, nwọn si mu Gaiu ati Aristarku ara Makedonia, awọn ẹgbẹ ajọrin Paulu. Nigbati Paulu si nfẹ wọ̀ ãrin awọn enia lọ, awọn ọmọ-ẹhin kò jẹ fun u. Awọn olori kan ara Asia, ti iṣe ọrẹ́ rẹ̀, ranṣẹ si i, nwọn bẹ̀ ẹ pe, ki o máṣe fi ara rẹ̀ wewu ninu ile ibiṣire. Njẹ awọn kan nwi ohun kan, awọn miran nwi omiran: nitori ajọ di rudurudu; ati ọ̀pọ enia ni kò mọ̀ itori ohun ti nwọn tilẹ fi wọjọ pọ̀ si. Nwọn si fà Aleksanderu kuro li awujọ, awọn Ju tì i ṣaju. Aleksanderu si juwọ́ si wọn, on iba si wi ti ẹnu rẹ̀ fun awọn enia. Ṣugbọn nigbati nwọn mọ̀ pe Ju ni, gbogbo wọn li ohùn kan, niwọn wakati meji ọjọ, kigbe pe, Oriṣa nla ni Diana ti ara Efesu. Nigbati akọwe ilu si mu ki ijọ enia dakẹ, o ni, Ẹnyin ará Efesu, tali ẹniti o wà ti kò mọ̀ pe, ilu ara Efesu ni iṣe olusin Diana oriṣa nla, ati ti ere ti o ti ọdọ Jupiteri bọ́ silẹ? Njẹ bi a ko ti le sọrọ odi si nkan wọnni, o yẹ ki ẹ dakẹ, ki ẹnyin ki o máṣe fi iwara ṣe ohunkohun. Nitoriti ẹnyin mu awọn ọkunrin wọnyi wá, nwọn kò kó ile oriṣa, bẹ̃ni nwọn kò sọrọ-odi si oriṣa wa. Njẹ nitorina bi Demetriu, ati awọn oniṣọnà ti o wà pẹlu rẹ̀, ba li ọ̀rọ kan si ẹnikẹni, ile-ẹjọ ṣí silẹ, awọn onidajọ si mbẹ: jẹ ki nwọn ki o lọ ifi ara wọn sùn. Ṣugbọn bi ẹ ba nwadi ohun kan nipa ọ̀ran miran, a ó pari rẹ̀ ni ajọ ti o tọ́. Nitori awa sá wà li ewu ati pè bi lẽrè nitori ariwo oni yi, kò sa nidi, ati nitori eyi awa kì yio le dahun fun iwọjọ yi. Nigbati o si ti sọ bẹ̃ tan, o tú ijọ na ká.

Iṣe Apo 19:1-41 Yoruba Bible (YCE)

Nígbà tí Apolo wà ní Kọrinti, Paulu gba ọ̀nà ilẹ̀ la àwọn ìlú tí ó wà ní àríwá Antioku kọjá títí ó fi dé Efesu. Ó rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu mélòó kan níbẹ̀. Ó bi wọ́n pé, “Ǹjẹ́ ẹ gba Ẹ̀mí Mímọ́ nígbà tí ẹ gba Jesu gbọ́?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Rárá o! A kò tilẹ̀ gbọ́ ọ rí pé nǹkankan wà tí ń jẹ́ Ẹ̀mí Mímọ́.” Paulu tún bi wọ́n pé, “Ìrìbọmi ti ta ni ẹ ṣe?” Wọ́n ní, “Ìrìbọmi ti Johanu ni.” Paulu bá sọ pé, “Ìrìbọmi pé a ronupiwada ni Johanu ṣe. Ó ń sọ fún àwọn eniyan pé kí wọ́n gba ẹni tí ó ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́. Ẹni náà ni Jesu.” Nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbà fún Paulu, ó sì rì wọ́n bọmi lórúkọ Oluwa Jesu. Nígbà tí Paulu gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé wọn, wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí fi èdè mìíràn sọ̀rọ̀, wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Gbogbo àwọn ọkunrin náà tó mejila. Paulu wọ inú ilé ìpàdé lọ. Fún oṣù mẹta ni ó fi ń sọ̀rọ̀ pẹlu ìgboyà; ó ń fi ọ̀rọ̀ yé àwọn eniyan nípa ìjọba Ọlọrun, ó ń gbìyànjú láti yí wọn lọ́kàn pada. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan ṣe agídí, tí wọn kò gba ọ̀rọ̀ rẹ̀ gbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ burúkú sí ọ̀nà Oluwa níwájú gbogbo àwùjọ, Paulu yẹra kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó kó àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu lọ sí gbọ̀ngàn Tirani, ó sì ń bá wọn sọ̀rọ̀ níbẹ̀ lojoojumọ. Báyìí ló ṣe fún ọdún meji, tí ó fi jẹ́ pé gbogbo àwọn tí ń gbé Esia: ati Juu ati Giriki, ni ó gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa. Ọlọrun fún Paulu lágbára láti ṣe iṣẹ́ ìyanu tóbẹ́ẹ̀ tí àwọn eniyan fi ń mú ìdikù tabi aṣọ-iṣẹ́ tí ó ti kan ara Paulu, lọ fi lé àwọn aláìsàn lára, àìsàn wọn sì ń fi wọ́n sílẹ̀, ẹ̀mí burúkú sì ń jáde kúrò lára wọn. Àwọn Juu kan tí wọ́n ti ń kiri láti ìlú dé ìlú, tí wọn ń lé ẹ̀mí burúkú jáde kúrò ninu àwọn eniyan, fẹ́ máa ṣe bíi Paulu nípa pípe orúkọ Oluwa Jesu lé àwọn tí ó ní ẹ̀mí burúkú lórí. Wọ́n á máa wí pé, “Mo pàṣẹ fun yín lórúkọ Jesu tí Paulu ń ròyìn nípa rẹ̀.” Àwọn Juu meje kan tí wọn jẹ́ ọmọ Sikefa Olórí Alufaa wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀. Ẹni tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá bi wọ́n pé, “Mo mọ Jesu; mo sì mọ Paulu. Tiyín ti jẹ́?” Ni ọkunrin tí ẹ̀mí burúkú wà ninu rẹ̀ bá fò mọ́ wọn; ó gbé ìjà ńlá kò wọ́n, ó sì ṣẹgun gbogbo wọn, ó ṣe wọ́n léṣe tóbẹ́ẹ̀ tí wọ́n fi sá jáde ninu ilé náà ní ìhòòhò, tàwọn ti ọgbẹ́ lára. Gbogbo àwọn Juu ati àwọn Giriki tí ó ń gbé Efesu ni wọ́n gbọ́ nípa ọ̀rọ̀ yìí. Ẹ̀rù ba gbogbo wọn; wọ́n sì gbé orúkọ Jesu Oluwa ga. Pupọ ninu àwọn onigbagbọ ni wọ́n jẹ́wọ́ ohun tí wọ́n ti ṣe, tí wọ́n tún tú àṣírí idán tí wọn ń pa. Àwọn mélòó kan ninu àwọn oníṣẹ́ òkùnkùn kó ìwé idán wọn jọ, wọ́n bá dáná sun wọ́n lójú gbogbo eniyan. Nígbà tí wọ́n ṣírò iye owó àwọn ìwé ọ̀hún, wọ́n rí i pé ó tó ọ̀kẹ́ meji ààbọ̀ (50,000) owó fadaka. Báyìí ni ọ̀rọ̀ Oluwa fi agbára hàn; ó ń tàn kálẹ̀, ó sì ń lágbára. Lẹ́yìn gbogbo nǹkan wọnyi, Paulu pinnu lọ́kàn rẹ̀ láti gba Masedonia lọ sí Akaya, kí ó wá ti ibẹ̀ lọ sí Jerusalẹmu. Ó ní, “Nígbà tí mo bá dé ibẹ̀, ó yẹ kí n fojú ba Romu náà.” Ó bá rán àwọn meji ninu àwọn olùrànlọ́wọ́ rẹ̀, Timoti ati Erastu, lọ sí Masedonia ṣugbọn òun alára dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i ní Esia. Ní àkókò náà, rògbòdìyàn bẹ́ sílẹ̀, tí kì í ṣe kékeré, nípa ọ̀nà Oluwa. Ọkunrin kan wà tí ń jẹ́ Demeteriu, alágbẹ̀dẹ fadaka. A máa fi fadaka ṣe ilé ìsìn ti oriṣa Atẹmisi; èyí a sì máa mú èrè pupọ wá fún àwọn tí ń ṣe iṣẹ́ ọnà yìí. Demeteriu wá pe àpèjọ àwọn alágbẹ̀dẹ fadaka ati àwọn tí iṣẹ́ wọn fara jọra. Ó ní, “Ẹ̀yin eniyan wa, ẹ mọ̀ pé ninu iṣẹ́ yìí ni a ti ń rí èrè wa. Ẹ wá rí i, ẹ tún ti gbọ́ pé kì í ṣe ní Efesu nìkan ni, ṣugbọn ó fẹ́rẹ̀ jẹ́ pé ní gbogbo Esia ni Paulu yìí ti ń yí ọ̀pọ̀ eniyan lọ́kàn pada. Ó ní àwọn ohun tí a fọwọ́ ṣe kì í ṣe oriṣa! Ewu wà fún wa pé, iṣẹ́ wa yóo di ohun tí eniyan kò ní kà sí mọ́. Ṣugbọn èyí nìkan kọ́, ewu tí ó tún wà ni pé, ilé ìsìn oriṣa ńlá wa, Atẹmisi, yóo di ohun tí ẹnikẹ́ni kò ní ṣújá mọ́. Láìpẹ́ kò sí ẹni tí yóo gbà pé oriṣa wa tóbi mọ́, oriṣa tí gbogbo Esia ati gbogbo àgbáyé ń sìn!” Nígbà tí wọ́n gbọ́, inú bí wọn pupọ. Wọ́n bá bẹ̀rẹ̀ sí kígbe, wọ́n ń wí pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Ni gbogbo ìlú bá dàrú. Wọ́n mú Gaiyu ati Arisitakọsi ará Masedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu ninu ìrìn àjò rẹ̀, gbogbo wọn bá rọ́ lọ sí ilé-ìṣeré. Paulu fẹ́ wọ ibẹ̀ lọ bá àwọn èrò ṣugbọn àwọn ọmọ-ẹ̀yìn Jesu kò gbà fún un. Àwọn ọ̀rẹ́ Paulu kan tí wọ́n jẹ́ ìjòyè ní agbègbè Esia ranṣẹ lọ bẹ̀ ẹ́ pé kí ó má yọjú sí ilé-ìṣeré nítorí gbogbo àwùjọ ti dàrú. Bí àwọn kan ti ń kígbe bákan, bẹ́ẹ̀ ni àwọn mìíràn ń kígbe bá mìíràn. Ọpọlọpọ kò tilẹ̀ mọ ìdí rẹ̀ tí wọ́n fi péjọ! Àwọn mìíràn rò pé Alẹkisanderu ni ó dá gbogbo rẹ̀ sílẹ̀, nítorí òun ni àwọn Juu tì siwaju. Alẹkisanderu fúnra rẹ̀ gbọ́wọ́ sókè, ó fẹ́ bá àwọn èrò sọ̀rọ̀. Nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Juu ni, wọ́n figbe ta, wọ́n ń pariwo fún ìwọ̀n wakati meji. Wọ́n ń kígbe pé, “Oriṣa ńlá ni Atẹmisi, oriṣa àwọn ará Efesu!” Akọ̀wé ìgbìmọ̀ ìlú ló mú kí wọ́n dákẹ́. Ó wá sọ pé, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni kò mọ̀ pé ìlú Efesu ni ó ń tọ́jú ilé ìsìn Atẹmisi oriṣa ńlá, ati òkúta rẹ̀ tí ó bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run? Kò sí ẹni tí ó lè wí pé kì í ṣe bẹ́ẹ̀. Ó yẹ kí ẹ fara balẹ̀ nígbà náà; kí a má fi ìwàǹwára ṣe ohunkohun. Nítorí àwọn ọkunrin tí ẹ mú wá yìí, kò ja ilé oriṣa lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ ìsọkúsọ sí oriṣa wa. Bí Demeteriu ati àwọn oníṣẹ́ ọnà tí ó wà pẹlu rẹ̀ bá ní ẹ̀sùn kan sí ẹnikẹ́ni, kóòtù wà; àwọn gomina sì ń bẹ. Ẹ jẹ́ kí wọ́n lọ pe ara wọn lẹ́jọ́ níbẹ̀. Bí ẹ bá tún ní ọ̀rọ̀ mìíràn tí ó jù yìí lọ, a óo máa yanjú rẹ̀ ní ìgbà tí a bá ń ṣe ìpàdé. Nítorí bí a ò bá ṣọ́ra, a óo dé ilé ẹjọ́ fún ìrúkèrúdò ọjọ́ òní, kò sì sí ohun tí a lè sọ pé ó fà á bí wọ́n bá bi wá.” Lẹ́yìn tí ó ti sọ báyìí tán, ó tú àwọn eniyan náà ká.

Iṣe Apo 19:1-41 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà ti Apollo wà ni Kọrinti, ti Paulu kọjá lọ sí apá òkè ìlú, ó sì wá sí Efesu: o sì rí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kan; o wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin ha gba Ẹ̀mí Mímọ́ náà nígbà tí ẹ̀yin gbàgbọ́?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Àwa kò gbọ́ rárá pé Ẹ̀mí Mímọ́ kan wà.” Ó sì wí pé, “Ǹjẹ́ irú bamitiisi wo ni a bamitiisi yín sí?” Wọ́n sì wí pé, “Sí bamitiisi tí Johanu.” Paulu sí wí pé, “Nítòótọ́, ní Johanu fi bamitiisi tí ìrònúpìwàdà bamitiisi, ó ń wí fún àwọn ènìyàn pé, kí wọ́n gba ẹni tí ń bọ̀ lẹ́yìn òun gbọ́, èyí sì ni Kristi Jesu.” Nígbà tí wọ́n sì gbọ́, a bamitiisi wọn lórúkọ Jesu Olúwa. Nígbà tí Paulu sì gbé ọwọ́ lé wọn, Ẹ̀mí Mímọ́ sì bà lé wọn: wọ́n sì ń fọ́ èdè mìíràn, wọ́n sì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀. Iye àwọn ọkùnrin náà gbogbo tó méjìlá. Nígbà tí ó sì wọ inú Sinagọgu lọ ó fi ìgboyà sọ̀rọ̀ ni oṣù mẹ́ta, ó ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀, ó sì ń yí wọn lọ́kàn padà sí nǹkan tí i ṣe tí ìjọba Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n nígbà tí ọkàn àwọn mìíràn nínú wọn di líle, tí wọn kò sì gbàgbọ́, tí wọn ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọ̀nà náà níwájú ìjọ ènìyàn, ó lọ kúrò lọ́dọ̀ wọn, ó sì ya àwọn ọmọ-ẹ̀yìn sọ́tọ̀, ó sì ń sọ àsọyé lójoojúmọ́ ni ilé ìwé Tirannusi. Èyí n lọ bẹ́ẹ̀ fún ìwọ̀n ọdún méjì; tó bẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn tí ń gbé Asia gbọ́ ọ̀rọ̀ Jesu Olúwa, àti àwọn Júù àti àwọn Giriki. Ọlọ́run sì tí ọwọ́ Paulu ṣe àwọn àkànṣe iṣẹ́ ìyanu, tó bẹ́ẹ̀ tí a fi ń mú aṣọ àti aṣọ ìnuwọ́ rẹ̀ tọ àwọn ọlọkùnrùn lọ, ààrùn sì fi wọ́n sílẹ̀, àwọn ẹ̀mí búburú sì jáde kúrò lára wọn. Ṣùgbọ́n àwọn Júù kan n lọ káàkiri láti máa le ẹ̀mí èṣù jáde, wọn dáwọ́lé àdábọwọ́ ara wọn, láti pé orúkọ Jesu Olúwa sí àwọn tí ó ni ẹ̀mí búburú, wí pé, “Àwa fi orúkọ Jesu tí Paulu ń wàásù fi yín bú.” Àwọn méje kan sì wà, tí wọn ń ṣe bẹ́ẹ̀, àwọn ọmọ ẹnìkan tí a ń pè ni Sikẹfa, tí í ṣe olórí àlùfáà gíga láàrín àwọn Júù. Ẹ̀mí búburú náà sì dáhùn, ó ní “Jesu èmi mọ̀ ọ́n, mo sì mọ Paulu pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ta ni ẹ̀yin?” Nígbà tí ọkùnrin tí ẹ̀mí búburú náà wà lára rẹ̀ sì fò mọ́ wọn, ó pa kúúrù mọ́ wọn, ó sì borí wọn, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sá jáde kúrò ní ilé náà ní ìhòhò pẹ̀lú ni ìfarapa. Ìròyìn yìí sì di mí mọ̀ fún gbogbo àwọn Júù àti àwọn ará Giriki pẹ̀lú tí ó ṣe àtìpó ní Efesu; ẹ̀rù sì ba gbogbo wọn, a sì gbé orúkọ Jesu Olúwa ga. Ọ̀pọ̀ àwọn tí wọ́n gbàgbọ́ sì wá, wọ́n jẹ́wọ́, wọ́n sì fi iṣẹ́ wọn hàn. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn tí ń ṣe alálúpàyídà ni ó kó ìwé wọn jọ, wọ́n dáná sun wọ́n lójú gbogbo ènìyàn. Wọ́n sì ṣírò iye wọn, wọ́n sì rí i, ó jẹ́ ẹgbàá-mẹ́dọ́gbọ̀n ìwọ̀n fàdákà. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀rọ̀ Olúwa gbèrú tí o sí gbilẹ̀ si í gidigidi. Ǹjẹ́ bí nǹkan wọ̀nyí tí parí tan, Paulu pinnu nínú ọkàn rẹ̀ pé, nígbà tí òun bá kọjá ní Makedonia àti Akaia, òun ó lọ sí Jerusalẹmu, ó wí pé, “Lẹ́yìn ìgbà tí mo bá dé ibẹ̀, èmi kò lè ṣàìmá dé Romu pẹ̀lú.” Nígbà tí ó sì tí rán méjì nínú àwọn tí ń ṣe ìránṣẹ́ fún un lọ sí Makedonia, Timotiu àti Erastu, òun tìkára rẹ̀ dúró díẹ̀ ní ilẹ̀ Asia. Ní àkókò náà ìrúkèrúdò díẹ̀ kan wà nítorí ọ̀nà náà. Nítorí ọkùnrin kan tí a ń pè ní Demetriusi, alágbẹ̀dẹ fàdákà, tí o máa ń fi fàdákà ṣe ilé òrìṣà fún Artemisi, ó mú ère tí kò mọ níwọ̀n wá fún àwọn oníṣọ̀nà; Nígbà tí ó pè wọ́n jọ, àti irú àwọn oníṣẹ́-ọnà bẹ́ẹ̀, ó wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin mọ̀ pé nípa iṣẹ́ ọnà yìí ni àwa fi ní ọrọ̀ wa. Ẹ̀yin sì rí i, ẹ sì gbọ́ pé, kì í ṣe ni Efesu nìkan ṣoṣo ni, ṣùgbọ́n ó fẹ́rẹ jẹ́ gbogbo Asia ni Paulu yìí ń yí ọ̀pọ̀ ènìyàn lọ́kàn padà, tí ó sì ń dárí wọn wí pé, ohun tí a fi ọwọ́ ṣe, kì í ṣe Ọlọ́run. Kì í sì ṣe pé kìkì iṣẹ́ ọnà wa yìí ni ó wà nínú ewu dídí asán; ṣùgbọ́n tẹmpili Artemisi òrìṣà ńlá yóò di gígàn pẹ̀lú, àti gbogbo ọláńlá rẹ̀ yóò sì run, ẹni tí gbogbo Asia àti gbogbo ayé ń bọ.” Nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí, wọ́n kún fún ìbínú, wọ́n kígbe, wí pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi ti ará Efesu!” Gbogbo ìlú náà sì kún fún ìrúkèrúdò: wọ́n sì fi ọkàn kan rọ́ wọn sí inú ilé ìṣeré, wọ́n sì mú Gaiu àti Aristarku ara Makedonia, àwọn ẹlẹgbẹ́ Paulu nínú ìrìnàjò. Nígbà ti Paulu sì ń fẹ́ wọ àárín àwọn ènìyàn lọ, àwọn ọmọ-ẹ̀yìn kọ̀ fún un. Àwọn olórí kan ara Asia, tí i ṣe ọ̀rẹ́ rẹ̀, ránṣẹ́ sí i, wọ́n bẹ̀ ẹ́ pé, kí ó má ṣe fi ara rẹ̀ wéwu nínú ilé ìṣeré náà. Ǹjẹ́ àwọn kan ń wí ohun kan, àwọn mìíràn ń wí òmíràn: nítorí àjọ di rúdurùdu; ọ̀pọ̀ ènìyàn ni kò sì mọ̀ ìdí ohun tí wọ́n tilẹ̀ fi péjọpọ̀. Àwọn kan nínú àwùjọ Júù ti Aleksanderu síwájú, wọn si pàṣẹ fun láti sọ̀rọ̀. Ó juwọ́ sí wọn láti dákẹ́ kí ó ba lè wí tẹnu rẹ̀ fun àwọn ènìyàn. Ṣùgbọ́n nígbà tí wọ́n mọ̀ pé Júù ni, gbogbo wọn ni ohùn kan, bẹ̀rẹ̀ sí kígbe fún bi wákàtí méjì pé, “Òrìṣà ńlá ni Artemisi tí ará Efesu!” Nígbà tí akọ̀wé ìlú sì mú kí ìjọ ènìyàn dákẹ́, “Ẹ̀yin ará Efesu, ta ni ẹni tí ó wà tí kò mọ̀ pé, ìlú Efesu ní í ṣe olùsìn Artemisi òrìṣà ńlá, àti tí ère tí ó ti ọ̀dọ̀ Jupiteri bọ́ sílẹ̀? Ǹjẹ́ bi a kò tilẹ̀ sọ̀rọ̀-òdì sí nǹkan wọ̀nyí, ó yẹ kí ẹ dákẹ́, kí ẹ̀yin má ṣe fi ìkanra ṣe ohunkóhun. Nítorí ti ẹ̀yin mú àwọn ọkùnrin wọ̀nyí wá, wọn kò ja ilé òrìṣà lólè, bẹ́ẹ̀ ni wọn kò sọ̀rọ̀-òdì sí òrìṣà wa. Ǹjẹ́ nítorí náà tí Demetriusi, àti àwọn oníṣẹ́-ọnà tí o wà pẹ̀lú rẹ̀ bá ní gbólóhùn asọ̀ kan sí ẹnikẹ́ni, ilé ẹjọ́ ṣí sílẹ̀, àwọn onídàájọ́ sì ń bẹ: jẹ́ kí wọn lọ fi ara wọn sùn. Ṣùgbọ́n bí ẹ ba ń wádìí ohun kan nípa ọ̀ràn mìíràn, a ó parí rẹ̀ ni àjọ tí ó tọ́. Nítorí àwa ṣa wà nínú ewu, nítorí rògbòdìyàn tí ó bẹ́ sílẹ̀ lónìí yìí; kò ṣáá ní ìdí kan tí rògbòdìyàn yìí fi bẹ́ sílẹ̀, nítorí èyí àwa kì yóò lè dáhùn fún ìwọ́jọ yìí.” Nígbà tí ó sì ti sọ bẹ́ẹ̀ tan, ó tú ìjọ náà ká.