Iṣe Apo 18:1-18

Iṣe Apo 18:1-18 Bibeli Mimọ (YBCV)

LẸHIN nkan wọnyi, Paulu jade kuro ni Ateni, o si lọ si Korinti; O si ri Ju kan ti a npè ni Akuila, ti a bí ni Pontu, ti o ti Itali de nilọ̃lọ̃, pẹlu Priskilla aya rẹ̀; nitoriti Klaudiu paṣẹ pe, ki gbogbo awọn Ju ki o jade kuro ni Romu: o si tọ̀ wọn wá. Ati itori ti iṣe oniṣẹ ọnà kanna, o ba wọn joko, o si nṣiṣẹ: nitori agọ́ pipa ni iṣẹ ọnà wọn. O si nfọ̀rọ̀ we ọrọ fun wọn ninu sinagogu li ọjọjọ isimi, o si nyi awọn Ju ati awọn Hellene li ọkàn pada. Nigbati Sila on Timotiu si ti Makedonia wá, ọrọ na ká Paulu lara, o nfi hàn, o sọ fun awọn Ju pe, Jesu ni Kristi na. Nigbati nwọn si wà li òdi, ti nwọn si nsọrọ-odi, o gbọ̀n aṣọ rẹ̀, o si wi fun wọn pe, Ẹ̀jẹ nyin mbẹ lori ara nyin; ọrùn emi mọ́: lati isisiyi lọ emi o tọ̀ awọn Keferi lọ. O si lọ kuro nibẹ̀, o wọ̀ ile ọkunrin kan ti a npè ni Titu Justu, ẹniti o nsìn Ọlọrun ti ile rẹ̀ fi ara mọ́ sinagogu tímọ́tímọ́. Ati Krispu, olori sinagogu, o gbà Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ile rẹ̀; ati ọ̀pọ ninu awọn ara Korinti, nigbati nwọn gbọ́, nwọn gbagbọ́, a si baptisi wọn. Oluwa si sọ fun Paulu li oru li ojuran pe, Má bẹ̀ru, sá mã sọ, má si ṣe pa ẹnu rẹ mọ́: Nitoriti emi wà pẹlu rẹ, kò si si ẹniti yio dide si ọ lati pa ọ lara: nitori mo li enia pupọ ni ilu yi. O si joko nibẹ̀ li ọdún kan on oṣù mẹfa, o nkọ́ni li ọ̀rọ Ọlọrun lãrin wọn. Nigbati Gallioni si jẹ bãlẹ Akaia, awọn Ju fi ọkàn kan dide si Paulu, nwọn si mu u wá siwaju itẹ idajọ. Nwọn wipe, ọkunrin yi nyi awọn enia li ọkàn pada, lati mã sin Ọlọrun lodi si ofin. Nigbati Paulu nfẹ ati dahùn, Gallioni wi fun awọn Ju pe, Ibaṣepe ọ̀ran buburu tabi ti jagidijagan kan ni, bi ọ̀rọ ti ri, ẹnyin Ju, emi iba gbè nyin: Ṣugbọn bi o ba ṣe ọ̀ran nipa ọ̀rọ ati orukọ, ati ti ofin nyin ni, ki ẹnyin ki o bojuto o fun ara nyin, nitoriti emi kò fẹ ṣe onidajọ nkan bawọnni. O si lé wọn kuro ni ibi itẹ idajọ. Gbogbo awọn Hellene si mu Sostene, olori sinagogu, nwọn si lù u niwaju itẹ idajọ. Gallioni kò si ṣú si nkan wọnyi. Paulu si duro si i nibẹ̀ li ọjọ pipọ, nigbati o si dágbere fun awọn arakunrin, o ba ti ọkọ̀ lọ si Siria, ati Priskilla ati Akuila pẹlu rẹ̀; o ti fá ori rẹ̀ ni Kenkrea: nitoriti o ti jẹjẹ.

Iṣe Apo 18:1-18 Yoruba Bible (YCE)

Lẹ́yìn èyí, Paulu kúrò ní Atẹni, ó lọ sí Kọrinti. Ó rí Juu kan níbẹ̀, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Akuila, ará Pọntu. Òun ati Pirisila iyawo rẹ̀ ṣẹ̀ṣẹ̀ ti ilẹ̀ Itali dé ni, nítorí ọba Kilaudiu pàṣẹ pé kí gbogbo àwọn Juu kúrò ní ìlú Romu. Paulu bá lọ sọ́dọ̀ wọn. Nítorí pé iṣẹ́ kan náà ni wọ́n ń ṣe, Paulu lọ wọ̀ lọ́dọ̀ wọn, ó sì ń ṣiṣẹ́. Iṣẹ́ ọnà awọ tí wọ́n fi ń ṣe àgọ́ ni wọ́n ń ṣe. Ní gbogbo Ọjọ́ Ìsinmi, a máa bá àwọn eniyan sọ̀rọ̀; ó fẹ́ yí àwọn Juu ati Giriki lọ́kàn pada. Nígbà tí Sila ati Timoti dé láti Masedonia, Paulu wá fi gbogbo àkókò rẹ̀ sílẹ̀ fún iwaasu, ó ń tẹnu mọ́ ọn fún àwọn Juu pé Jesu ni Mesaya. Ṣugbọn nígbà tí àwọn kan takò ó, tí wọn ń sọ ìsọkúsọ, ó gbọn ẹ̀wù rẹ̀ sí wọn lójú, ó ní, “Ẹ̀jẹ̀ yín wà lọ́rùn yín. Ọwọ́ tèmi mọ́. Láti ìgbà yìí lọ èmi yóo lọ sọ́dọ̀ àwọn orílẹ̀-èdè mìíràn.” Ni ó bá kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ẹnìkan tí ó ń jẹ́ Titiu Jusitu, ẹnìkan tí ń sin Ọlọrun. Ilé rẹ̀ fẹ̀gbẹ́kẹ̀gbẹ́ pẹlu ilé ìpàdé àwọn Juu. Kirisipu, ẹni tí ń darí ètò ilé ìpàdé àwọn Juu gba Oluwa gbọ́ pẹlu gbogbo ilé rẹ̀. Bẹ́ẹ̀ ni pupọ ninu àwọn ará Kọrinti; nígbà tí wọ́n gbọ́ ọ̀rọ̀ Oluwa, wọ́n gbàgbọ́, wọ́n bá ṣe ìrìbọmi. Ní alẹ́ ọjọ́ kan, Paulu rí ìran kan. Ninu ìran náà Oluwa sọ fún un pé, “Má bẹ̀rù, máa waasu, má dákẹ́. Nítorí n óo wà pẹlu rẹ. Kò sí ẹni tí yóo fọwọ́ kàn ọ́ láti ṣe ọ́ níbi. Nítorí mo ní eniyan pupọ ninu ìlú yìí.” Paulu gbé ààrin wọn fún ọdún kan ati oṣù mẹfa, ó ń kọ́ wọn ní ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn nígbà tí Galio di gomina Akaya, àwọn Juu fi ohùn ṣọ̀kan láti dìde sí Paulu. Wọ́n bá mú un lọ sí kóòtù níwájú Galio. Wọ́n ní, “Ọkunrin yìí ń kọ́ àwọn eniyan láti sin Ọlọrun ní ọ̀nà tí ó lòdì sí òfin.” Bí Paulu ti fẹ́ lanu láti fèsì, Galio sọ fún àwọn Juu pé, “Ẹ̀yin Juu, bí ó bá jẹ́ ẹ̀ṣẹ̀ kan tabi ọ̀ràn burúkú kan ni ẹ mú wá, ǹ bá gbọ́ ohun tí ẹ ní sọ; ṣugbọn tí ó bá jẹ́ àríyànjiyàn nípa àwọn ọ̀rọ̀ tabi orúkọ, tabi òfin yín, ẹ lọ rí sí i fúnra yín. N kò fẹ́ dá irú ẹjọ́ bẹ́ẹ̀.” Ni ó bá lé wọn kúrò ní kóòtù. Ni gbogbo wọ́n bá mú Sositene, olórí ilé ìpàdé àwọn Juu, wọ́n ń lù ú níwájú kóòtù. Ṣugbọn Galio kò pé òun rí wọn. Paulu tún dúró fún ìgbà díẹ̀ sí i. Lẹ́yìn náà ó dágbére fún àwọn onigbagbọ, ó bá wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Siria; Pirisila ati Akuila bá a lọ. Paulu gé irun rẹ̀ ní ìlú Kẹnkiria nítorí pé ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́ kan.

Iṣe Apo 18:1-18 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Lẹ́yìn nǹkan wọ̀nyí, Paulu jáde kúrò ni Ateni lọ sí Kọrinti. Ó sì rí Júù kan tí a ń pè ní Akuila, tí a bí ni Pọntu, tí ó ti Itali dé ní lọ́ọ́lọ́ọ́, pẹ̀lú Priskilla aya rẹ̀; nítorí tí Kilaudiu pàṣẹ pé, kí gbogbo àwọn Júù jáde kúrò ní Romu. Ó sì tọ̀ wọ́n lọ láti rí wọn. Nítorí tí òun náà jẹ́ oníṣẹ̀-ọwọ́ kan náà, ó bá wọn jókòó, ó sì ń ṣiṣẹ́: nítorí àgọ́ pípa ni iṣẹ́ ọwọ́ wọn. Ó sì ń fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ pẹ̀lú wọn nínú Sinagọgu lọ́jọjọ́ ìsinmi, ó sì ń yí àwọn Júù àti àwọn Giriki lọ́kàn padà. Nígbà tí Sila àti Timotiu sì tí Makedonia wá, ọ̀rọ̀ náà ká Paulu lára, ó ń fihàn fún àwọn Júù pé, Jesu ni Kristi náà. Nígbà tí wọ́n sì sàtakò rẹ̀, tí wọ́n sì sọ̀rọ̀-òdì, ó gbọ́n aṣọ rẹ̀, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀jẹ̀ yin ń bẹ lórí ara yin; ọrùn mi mọ́: láti ìsinsin yìí lọ, èmi yóò tọ àwọn aláìkọlà lọ.” Ó sì lọ kúrò níbẹ̀, ó wọ ilé ọkùnrin kan tí a ń pé ní Titu Justu, ẹni tí o ń sin Ọlọ́run; ilé rẹ̀ sì wà lẹ́gbẹ̀ Sinagọgu tímọ́tímọ́. Krisipu, olórí Sinagọgu, sì gba Olúwa gbọ́ pẹ̀lú gbogbo ilé rẹ̀: àti ọ̀pọ̀ nínú àwọn ara Kọrinti, nígbà tí wọ́n gbọ́, wọ́n gbàgbọ́, a sì bamitiisi wọn. Olúwa sì sọ fún Paulu lóru ni ojúran pé, “Má bẹ̀rù, ṣá máa sọ, má sì ṣe pa ẹnu rẹ̀ mọ́: Nítorí tí èmí wà pẹ̀lú rẹ, kò sì sí ẹni tí yóò dìde sí ọ láti pa ọ lára: nítorí mo ní ènìyàn púpọ̀ ni ìlú yìí.” Ó sì jókòó níbẹ̀ ní ọdún kan àti oṣù mẹ́fà, ó ń kọ́ni ní ọ̀rọ̀ Ọlọ́run láàrín wọn. Nígbà tí Gallioni sì jẹ baálẹ̀ Akaia, àwọn Júù fi ìfìmọ̀ṣọ̀kan dìde sí Paulu wọn sì mú un wá síwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Wọ́n wí pé, “Ọkùnrin yìí ń yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, láti máa sin Ọlọ́run lòdì sí òfin.” Nígbà tí Paulu ń fẹ́ dáhùn, Gallioni wí fún àwọn Júù pé, “Ìbá ṣe pé ọ̀ràn búburú tàbí tí jàgídíjàgan kan ni, èmi ìbá gbè yín, ẹ̀yin Júù; Ṣùgbọ́n bí ó ti ṣe ọ̀ràn nípa ọ̀rọ̀ àti orúkọ, àti ti òfin yín ni, ki ẹ̀yin bojútó o fúnrayín; nítorí tí èmi kò fẹ́ ṣe onídàájọ́ nǹkan báwọ̀nyí.” Ó sì lé wọn kúrò ní ibi ìtẹ́ ìdájọ́. Gbogbo àwọn Giriki sì mú Sostene, olórí Sinagọgu, wọ́n sì lù ú níwájú ìtẹ́ ìdájọ́. Gallioni kò sì bìkítà fún nǹkan wọ̀nyí. Paulu sì dúró sí i níbẹ̀ lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà tí ó sì dágbére fún àwọn arákùnrin, ó bá ọkọ̀ ojú omi lọ si Siria, àti Priskilla àti Akuila pẹ̀lú rẹ̀; ó tí fá orí rẹ̀ ni Kenkerea: nítorí tí ó ti jẹ́ ẹ̀jẹ́.