Iṣe Apo 17:1-9

Iṣe Apo 17:1-9 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn. Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki. Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú. Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà. Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!” Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí. Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀.

Iṣe Apo 17:1-9 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà: Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ.