Iṣe Apo 17:1-15

Iṣe Apo 17:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Nígbà tí wọn sì ti kọjá Amfipoli àti Apollonia, wọ́n wá sí Tẹsalonika, níbi tí Sinagọgu àwọn Júù wà: Àti Paulu, gẹ́gẹ́ bí ìṣe rẹ̀, ó wọlé tọ̀ wọ́n lọ, ni ọjọ́ ìsinmi mẹ́ta ó sì ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ nínú ìwé mímọ́. Ó ń túmọ̀, ó sì ń fihàn pé, Kristi kò lè ṣàìmá jìyà, kí o sì jíǹde kúrò nínú òkú; àti pé, “Jesu yìí ẹni tí èmi ń wàásù fún yin, òun ni Kristi náà.” A sì yí nínú wọn lọ́kàn padà, wọ́n sì darapọ̀ mọ́ Paulu àti Sila: bákan náà ní ọ̀pọ̀lọpọ̀ nínú àwọn olùfọkànsìn Helleni àti nínú àwọn obìnrin ọlọ́lá, kì í ṣe díẹ̀. Ṣùgbọ́n àwọn Júù jowú, wọn sì fa àwọn jàgídíjàgan nínú àwọn ọmọ ènìyàn mọ́ra, wọ́n ko ẹgbẹ́ jọ, wọ́n sì ń dá ìlú rú; wọ́n sì kọlu ilé Jasoni, wọ́n ń fẹ́ láti mú Paulu àti Sila jáde tọ àwọn ènìyàn lọ. Nígbà tí wọn kò sì rí wọn, wọ́n wọ́ Jasoni, àti àwọn arákùnrin kan tọ àwọn olórí ìlú lọ, wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn wọ̀nyí tí o tí dorí ayé kodò títí de ìhín yìí pẹ̀lú. Àwọn ẹni tí Jasoni gbà sí ọ̀dọ̀: gbogbo àwọn wọ̀nyí ni o sí ń hùwà lòdì sí àṣẹ Kesari, wí pé, ọba mìíràn kan wà tí í ṣe Jesu.” Àwọn ènìyàn àti àwọn olórí ìlú kò ní ìfọ̀kànbalẹ̀ nígbà tí wọ́n gbọ́ nǹkan wọ̀nyí. Nígbà tí wọ́n sì gbà onídùúró lọ́wọ́ Jasoni àti àwọn ìyókù, wọ́n fi wọ́n sílẹ̀ lọ. Lọ́gán àwọn arákùnrin sì rán Paulu àti Sila lọ ṣí Berea lóru. Nígbà tí wọ́n sí dé ibẹ̀, wọ́n wọ inú Sinagọgu àwọn Júù lọ. Àwọn Júù Berea sì ní ìyìn ju àwọn tí Tẹsalonika lọ, ní tí pé wọn fi tọkàntọkàn gbà ọ̀rọ̀ náà. Wọ́n sì ń wá inú ìwé mímọ́ lójoojúmọ́ bí nǹkan wọ̀nyí bá rí bẹ́ẹ̀. Nítorí náà púpọ̀ nínú wọn gbàgbọ́; àti nínú àwọn obìnrin Giriki ọlọ́lá, àti nínú àwọn ọkùnrin ti kì í ṣe díẹ̀. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn Júù tí Tẹsalonika mọ̀ pé, Paulu ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Berea, wọ́n wá síbẹ̀ pẹ̀lú, wọ́n rú àwọn ènìyàn sókè. Nígbà náà ni àwọn arákùnrin rán Paulu jáde lọ́gán láti lọ títí de etí Òkun: ṣùgbọ́n Sila àti Timotiu dúró ní Berea. Àwọn tí ó sin Paulu wá sì mú un lọ títí dé Ateni; nígbà tí wọ́n sì gba àṣẹ lọ́dọ̀ rẹ̀ wá fún Sila àti Timotiu pé, ki wọn ó yára tọ òun wá, wọ́n lọ.

Iṣe Apo 17:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Wọ́n kọjá ní Amfipoli ati Apolonia kí wọn tó dé Tẹsalonika. Ilé ìpàdé àwọn Juu kan wà níbẹ̀. Gẹ́gẹ́ bí àṣà Paulu, ó wọ ibẹ̀ tọ̀ wọ́n lọ. Fún ọ̀sẹ̀ mẹta ni ó fi ń bá wọn fi ọ̀rọ̀ wé ọ̀rọ̀ láti inú Ìwé Mímọ́. Ó ń ṣe àlàyé fún wọn, ó tún ń tọ́ka sí àkọsílẹ̀ inú Ìwé Mímọ́ láti fihàn pé dandan ni kí Mesaya jìyà, kí ó jinde kúrò ninu òkú. Lẹ́yìn náà ó sọ fún wọn pé, Mesaya yìí náà ni Jesu tí òun ń sọ̀rọ̀ rẹ̀ fún wọn. Àwọn kan ninu wọn gbàgbọ́, wọ́n fara mọ́ Paulu ati Sila. Ọ̀pọ̀ ninu wọn jẹ́ Giriki, wọ́n ń sin Ọlọrun; pupọ ninu àwọn obinrin sì jẹ́ eniyan pataki-pataki. Ṣugbọn ara ta àwọn Juu nígbà tí wọ́n rí i pé àwọn eniyan pupọ gba ọ̀rọ̀ Paulu ati Sila. Wọ́n bá lọ mú ninu àwọn tí wọ́n ń fẹsẹ̀ wọ́lẹ̀ kiri, àwọn jàgídíjàgan, wọ́n kó wọn jọ. Wọ́n bá dá ìrúkèrúdò sílẹ̀ ninu ìlú. Wọ́n lọ ṣùrù bo ilé Jasoni, wọ́n ń wá Paulu ati Sila kí wọ́n lè fà wọ́n lọ siwaju àwọn ará ìlú. Nígbà tí wọn kò rí wọn, wọ́n fa Jasoni ati díẹ̀ ninu àwọn onigbagbọ lọ siwaju àwọn aláṣẹ ìlú. Wọ́n ń kígbe pé, “Àwọn tí wọn ń da gbogbo ayé rú nìyí; wọ́n ti dé ìhín náà. Jasoni sì ti gbà wọ́n sílé. Gbogbo wọn ń ṣe ohun tí ó lòdì sí àṣẹ Kesari. Wọ́n ní: ọba mìíràn wà, ìyẹn ni Jesu!” Ọkàn àwọn eniyan ati àwọn aláṣẹ ìlú dààmú nígbà tí wọ́n gbọ́ báyìí. Wọ́n bá gba owó ìdúró lọ́wọ́ Jasoni ati àwọn yòókù, wọ́n bá dá wọn sílẹ̀. Nígbà tí ilẹ̀ ṣú, àwọn onigbagbọ tètè ṣe ètò láti mú Paulu ati Sila lọ sí Beria. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n lọ sí ilé ìpàdé àwọn Juu. Àwọn yìí ṣe onínú rere ju àwọn Juu ti Tẹsalonika lọ. Wọ́n fi ìtara gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Lojoojumọ ni wọ́n ń wá inú Ìwé Mímọ́ wò láti rí bí àwọn ohun tí wọ́n kọ́ wọn rí bẹ́ẹ̀. Pupọ ninu wọn gbàgbọ́, ati pupọ ninu àwọn Giriki tí wọ́n jẹ́ eniyan pataki-pataki, lọkunrin ati lobinrin. Ṣugbọn nígbà tí àwọn Juu ní Tẹsalonika mọ̀ pé Paulu ti tún waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ní Beria, wọ́n wá sibẹ láti ṣe màdàrú ati láti dá rúkèrúdò sílẹ̀. Lẹsẹkẹsẹ ni àwọn onigbagbọ bá ṣe ètò fún Paulu láti lọ sí èbúté. Ṣugbọn Sila ati Timoti dúró ní Beria. Àwọn tí ó sin Paulu lọ mú un dé Atẹni. Wọ́n wá gba ìwé pada fún Sila ati Timoti pé kí wọ́n tètè wá bá a.

Iṣe Apo 17:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

NIGBATI nwọn si ti kọja Amfipoli ati Apollonia, nwọn wá si Tessalonika, nibiti sinagogu awọn Ju wà: Ati Paulu, gẹgẹbi iṣe rẹ̀, o wọle tọ̀ wọn lọ, li ọjọ isimi mẹta o si mba wọn fi ọ̀rọ we ọ̀rọ ninu iwe-mimọ́, O ntumọ, o si nfihàn pe, Kristi kò le ṣaima jìya, ki o si jinde kuro ninu okú; ati pe, Jesu yi, ẹniti emi nwasu fun nyin, on ni Kristi na. A si yi ninu wọn lọkàn pada, nwọn si darapọ̀ mọ́ Paulu on Sila; ati ninu awọn olufọkansìn Hellene ọ̀pọ pupọ, ati ninu awọn obinrin ọlọlá, kì iṣe diẹ. Ṣugbọn awọn Ju jowu, nwọn si fà awọn jagidijagan ninu awọn ijajẹ enia mọra, nwọn gbá ẹgbẹ jọ, nwọn si nrú ilu; nwọn si kọlù ile Jasoni, nwọn nfẹ mu wọn jade tọ̀ awọn enia wá. Nigbati nwọn kò si ri wọn, nwọn wọ́ Jasoni, ati awọn arakunrin kan tọ̀ awọn olori ilu lọ, nwọn nkigbe pe, Awọn wọnyi ti o ti yi aiye po wá si ihinyi pẹlu; Awọn ẹniti Jasoni gbà si ọdọ: gbogbo awọn wọnyi li o si nhuwa lodi si aṣẹ Kesari, wipe, ọba miran kan wà, Jesu. Awọn enia ati awọn olori ilu kò ni ibalẹ aiya nigbati nwọn gbọ́ nkan wọnyi. Nigbati nwọn si gbà ogò lọwọ Jasoni ati awọn iyokù, nwọn jọwọ lọ. Lọgan awọn arakunrin si rán Paulu on Sila lọ si Berea li oru: nigbati nwọn si de ibẹ̀, nwọn wọ̀ inu sinagogu awọn Ju lọ. Awọn wọnyi si ni iyìn jù awọn ti Tessalonika lọ, niti pe nwọn fi tọkantọkan gbà ọ̀rọ na, nwọn si nwá inu iwe-mimọ́ lojojumọ́ bi nkan wọnyi ri bẹ̃. Nitorina pipọ ninu wọn gbagbọ́; ati ninu awọn obinrin Hellene ọlọlá, ati ninu awọn ọkunrin, kì iṣe diẹ. Ṣugbọn nigbati awọn Ju ti Tessalonika mọ̀ pe, Paulu nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni Berea, nwọn si wá sibẹ̀ pẹlu, nwọn rú awọn enia soke. Nigbana li awọn arakunrin rán Paulu jade lọgan lati lọ titi de okun: Ṣugbọn Sila on Timotiu duro sibẹ̀. Awọn ti o sin Paulu wá si mu u lọ titi de Ateni; nigbati nwọn si gbà aṣẹ lọdọ rẹ̀ tọ̀ Sila on Timotiu wá pe, ki nwọn ki o yára tọ̀ on wá, nwọn lọ.