Iṣe Apo 16:30-34
Iṣe Apo 16:30-34 Bibeli Mimọ (YBCV)
O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là? Nwọn si wi fun u pe, Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu. Nwọn si sọ ọ̀rọ Oluwa fun u, ati fun gbogbo awọn ará ile rẹ̀. O si mu wọn ni wakati na li oru, o wẹ̀ ọgbẹ wọn; a si baptisi rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀ lojukanna. O si mu wọn wá si ile rẹ̀, o si gbé onjẹ kalẹ niwaju wọn, o si yọ̀ gidigidi pẹlu gbogbo awọn ará ile rẹ̀, nitori o gbà Ọlọrun gbọ.
Iṣe Apo 16:30-34 Yoruba Bible (YCE)
Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́.
Iṣe Apo 16:30-34 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.” Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà. Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́.