Iṣe Apo 16:22-36

Iṣe Apo 16:22-36 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn. Nigbati nwọn si lù wọn pupọ, nwọn sọ wọn sinu tubu, nwọn kìlọ fun onitubu ki o pa wọn mọ́ daradara: Nigbati o gbọ́ irú ikilọ bẹ̃, o sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, o si kàn ãbà mọ wọn li ẹsẹ. Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn. Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ. Nigbati onitubu si tají, ti o si ri pe, awọn ikẹkun tubu ti ṣí silẹ, o fà idà rẹ̀ yọ, o si fẹ pa ara rẹ̀, o ṣebi awọn ara tubu ti sá lọ. Ṣugbọn Paulu kọ kàrá, wipe, Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi. Nigbati o si bere iná, o bẹ́ sinu ile, o nwariri, o wolẹ niwaju Paulu on Sila. O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là? Nwọn si wi fun u pe, Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu. Nwọn si sọ ọ̀rọ Oluwa fun u, ati fun gbogbo awọn ará ile rẹ̀. O si mu wọn ni wakati na li oru, o wẹ̀ ọgbẹ wọn; a si baptisi rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀ lojukanna. O si mu wọn wá si ile rẹ̀, o si gbé onjẹ kalẹ niwaju wọn, o si yọ̀ gidigidi pẹlu gbogbo awọn ará ile rẹ̀, nitori o gbà Ọlọrun gbọ. Ṣugbọn nigbati ilẹ mọ́, awọn onidajọ rán awọn ọlọpa pe, Da awọn enia wọnni silẹ. Onitubu si sọ ọrọ na fun Paulu, wipe, Awọn onidajọ ranṣẹ pe ki a dá nyin silẹ: njẹ nisisiyi ẹ jade ki ẹ si mã lọ li alafia.

Iṣe Apo 16:22-36 Yoruba Bible (YCE)

Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila. Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú. Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni. Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.” Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila. Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.”

Iṣe Apo 16:22-36 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì Paulu àti Sila. Àwọn olórí sí fà wọ́n ní aṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fi ọ̀gọ̀ lù wọ́n. Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára: Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀. Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!” Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.” Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà. Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídàájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.” Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Paulu, wí pé, “Àwọn onídàájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da ìwọ àti Sila sílẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.”