Iṣe Apo 16:22-26
Iṣe Apo 16:22-26 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì Paulu àti Sila. Àwọn olórí sí fà wọ́n ní aṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fi ọ̀gọ̀ lù wọ́n. Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára: Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀.
Iṣe Apo 16:22-26 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn. Nigbati nwọn si lù wọn pupọ, nwọn sọ wọn sinu tubu, nwọn kìlọ fun onitubu ki o pa wọn mọ́ daradara: Nigbati o gbọ́ irú ikilọ bẹ̃, o sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, o si kàn ãbà mọ wọn li ẹsẹ. Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn. Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ.
Iṣe Apo 16:22-26 Yoruba Bible (YCE)
Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila. Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú.