Iṣe Apo 16:11-40
Iṣe Apo 16:11-40 Bibeli Mimọ (YBCV)
Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli; Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan. Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ. Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ. Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa. O si ṣe, bi awa ti nlọ si ibi adura na, ọmọbinrin kan ti o li ẹmi afọṣẹ, pade wa, ẹniti o fi afọṣẹ mu ère pipọ fun awọn oluwa rẹ̀ wá: On na li o ntọ̀ Paulu ati awa lẹhin, o si nkigbe, wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ni iranṣẹ Ọlọrun Ọgá-ogo, ti nkede ọ̀na igbala fun nyin. O si nṣe eyi li ọjọ pipọ. Ṣugbọn nigbati inu Paulu bajẹ, ti o si yipada, o wi fun ẹmí na pe, Mo paṣẹ fun ọ li orukọ Jesu Kristi kí o jade kuro lara rẹ̀. O si jade ni wakati kanna. Nigbati awọn oluwa rẹ̀ si ri pe, igbẹkẹle ère wọn pin, nwọn mu Paulu on Sila, nwọn si wọ́ wọn lọ si ọjà tọ̀ awọn ijoye lọ; Nigbati nwọn si mu wọn tọ̀ awọn onidajọ lọ, nwọn wipe, Awọn ọkunrin wọnyi ti iṣe Ju, nwọn nyọ ilu wa lẹnu jọjọ; Nwọn si nkọni li àṣa ti kò yẹ fun wa, awa ẹniti iṣe ara Romu, lati gbà, ati lati tẹle. Ọpọ enia si jumọ dide si wọn: awọn olori si fà wọn li aṣọ ya, nwọn si paṣẹ pe, ki a fi ọgọ lù wọn. Nigbati nwọn si lù wọn pupọ, nwọn sọ wọn sinu tubu, nwọn kìlọ fun onitubu ki o pa wọn mọ́ daradara: Nigbati o gbọ́ irú ikilọ bẹ̃, o sọ wọn sinu tubu ti inu lọhun, o si kàn ãbà mọ wọn li ẹsẹ. Ṣugbọn larin ọganjọ Paulu on Sila ngbadura, nwọn si nkọrin iyìn si Ọlọrun: awọn ara tubu si ntẹti si wọn. Lojiji iṣẹlẹ nla si ṣẹ̀, tobẹ̃ ti ipilẹ ile tubu mi titi: lọgan gbogbo ilẹkun si ṣí, ìde gbogbo wọn si tu silẹ. Nigbati onitubu si tají, ti o si ri pe, awọn ikẹkun tubu ti ṣí silẹ, o fà idà rẹ̀ yọ, o si fẹ pa ara rẹ̀, o ṣebi awọn ara tubu ti sá lọ. Ṣugbọn Paulu kọ kàrá, wipe, Máṣe pa ara rẹ lara: nitori gbogbo wa mbẹ nihinyi. Nigbati o si bere iná, o bẹ́ sinu ile, o nwariri, o wolẹ niwaju Paulu on Sila. O si mu wọn jade, o ni, Alàgba, kini ki emi ki o ṣe ki ng le là? Nwọn si wi fun u pe, Gbà Jesu Kristi Oluwa gbọ́, a o si gbà ọ là, iwọ ati awọn ará ile rẹ pẹlu. Nwọn si sọ ọ̀rọ Oluwa fun u, ati fun gbogbo awọn ará ile rẹ̀. O si mu wọn ni wakati na li oru, o wẹ̀ ọgbẹ wọn; a si baptisi rẹ̀, ati gbogbo awọn enia rẹ̀ lojukanna. O si mu wọn wá si ile rẹ̀, o si gbé onjẹ kalẹ niwaju wọn, o si yọ̀ gidigidi pẹlu gbogbo awọn ará ile rẹ̀, nitori o gbà Ọlọrun gbọ. Ṣugbọn nigbati ilẹ mọ́, awọn onidajọ rán awọn ọlọpa pe, Da awọn enia wọnni silẹ. Onitubu si sọ ọrọ na fun Paulu, wipe, Awọn onidajọ ranṣẹ pe ki a dá nyin silẹ: njẹ nisisiyi ẹ jade ki ẹ si mã lọ li alafia. Ṣugbọn Paulu wi fun wọn pe, Nwọn lù wa ni gbangba, nwọn si sọ wa sinu tubu li aijẹbi, awa ẹniti iṣe ara Romu: nisisiyi nwọn si fẹ ti wa jade nikọ̀kọ? agbẹdọ; ṣugbọn ki awọn tikarawọn wá mu wa jade. Awọn ọlọpa si sọ ọrọ wọnyi fun awọn onidajọ: ẹ̀ru si bà wọn, nigbati nwọn gbọ́ pe ara Romu ni nwọn. Nwọn si wá, nwọn ṣìpẹ fun wọn, nwọn si mu wọn jade, nwọn si bẹ̀ wọn pe, ki nwọn ki o jade kuro ni ilu na. Nwọn si jade ninu tubu, nwọn si wọ̀ ile Lidia lọ: nigbati nwọn si ti ri awọn arakunrin, nwọn tù wọn ninu, nwọn si jade kuro.
Iṣe Apo 16:11-40 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli. Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ. Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà. Ní ọjọ́ kan, bí a ti ń lọ sí ibi adura, a pàdé ọdọmọbinrin kan tí ó ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ. Ó ti ń mú èrè pupọ wá fún àwọn olówó rẹ̀ nípa àfọ̀ṣẹ rẹ̀. Ó ń tẹ̀lé Paulu ati àwa náà, ó ń kígbe pé, “Àwọn ọkunrin yìí ni iranṣẹ Ọlọrun Ọ̀gá Ògo; àwọn ni wọ́n ń waasu ọ̀nà ìgbàlà fun yín.” Ó ń ṣe báyìí fún ọjọ́ pupọ. Nígbà tí ara Paulu kò gbà á mọ́, ó yipada, ó sọ fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu, jáde kúrò ninu rẹ̀.” Ni ó bá jáde lẹ́sẹ̀ kan náà. Nígbà tí àwọn olówó ọdọmọbinrin náà rí i pé ọ̀nà oúnjẹ wọ́n ti dí, wọ́n ki Paulu ati Sila mọ́lẹ̀, wọ́n fà wọ́n lọ sọ́dọ̀ àwọn aláṣẹ ní ọjà. Wọ́n mú wọn wá siwaju àwọn adájọ́. Wọ́n ní, “Juu ni àwọn ọkunrin wọnyi, wọ́n sì ń da ìlú wa rú. Wọ́n ń kọ́ àwọn eniyan ní àṣà tí kò tọ́ fún wa láti gbà tabi láti ṣe nítorí ará Romu ni wá.” Ni àwọn eniyan bá bẹ̀rẹ̀ sí lu Paulu ati Sila. Àwọn adájọ́ fa aṣọ ya mọ́ wọn lára, wọ́n pàṣẹ pé kí wọ́n nà wọ́n. Nígbà tí wọ́n ti nà wọ́n dáradára, wọ́n bá sọ wọ́n sẹ́wọ̀n. Wọ́n pàṣẹ fún ẹni tí ó ń ṣọ́ àwọn ẹlẹ́wọ̀n pé kí ó ṣọ́ wọn dáradára. Nígbà tí ó ti gba irú àṣẹ báyìí, ó sọ wọ́n sinu àtìmọ́lé ti inú patapata, ó tún fi ààbà kan ẹsẹ̀ wọn mọ́ igi. Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, Paulu ati Sila ń gbadura, wọ́n ń kọrin sí Ọlọrun. Àwọn ẹlẹ́wọ̀n yòókù ń dẹtí sí wọn. Lójijì ni ilẹ̀ mì tìtì, tóbẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé ẹ̀wọ̀n mì. Lọ́gán gbogbo ìlẹ̀kùn ṣí; gbogbo ẹ̀wọ̀n tí a fi de àwọn ẹlẹ́wọ̀n sì tú. Nígbà tí ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n jí lójú oorun, tí ó rí i pé ìlẹ̀kùn ilé ẹ̀wọ̀n ti ṣí, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣebí àwọn ẹlẹ́wọ̀n ti sálọ ni. Paulu bá kígbe pè é, ó ní, “Má ṣe ara rẹ léṣe, nítorí gbogbo wa wà níhìn-ín.” Ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá bèèrè iná, ó pa kuuru wọ inú iyàrá, ó ń gbọ̀n láti orí dé ẹsẹ̀. Ó wólẹ̀ níwájú Paulu ati Sila. Ó mú wọn jáde, ó ní, “Ẹ̀yin alàgbà, kí ni ó yẹ kí n ṣe kí n lè là?” Wọ́n dá a lóhùn pé, “Gba Jesu Oluwa gbọ́, ìwọ ati ìdílé rẹ yóo sì là.” Wọ́n bá sọ ọ̀rọ̀ Oluwa fún òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀. Ní òru náà, ó mú wọn, ó wẹ ọgbẹ́ wọn. Lójú kan náà òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì ṣe ìrìbọmi. Ó bá mú wọn wọ ilé, ó fún wọn ní oúnjẹ. Inú òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ dùn pupọ nítorí ó ti gba Ọlọrun gbọ́. Nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn adájọ́ rán àwọn iranṣẹ sí ẹni tí ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n pé, kí ó dá àwọn eniyan náà sílẹ̀. Ẹni tí ó ń ṣọ́ ilé ẹ̀wọ̀n náà bá lọ jíṣẹ́ fún Paulu pé, “Àwọn adájọ́ ti ranṣẹ pé kí á da yín sílẹ̀. Ẹ jáde kí ẹ máa lọ ní alaafia.” Ṣugbọn Paulu sọ fún wọn pé, “Wọ́n nà wá ní gbangba láì ká ẹ̀bi mọ́ wa lọ́wọ́, bẹ́ẹ̀ ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wá. Wọ́n sọ wá sẹ́wọ̀n, wọ́n wá fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀. Rárá o! Kí àwọn fúnra wọn wá kó wa jáde.” Àwọn iranṣẹ tí àwọn adájọ́ rán wá lọ ròyìn ọ̀rọ̀ wọnyi fún wọn. Ẹ̀rù bà wọ́n nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ọmọ-ìbílẹ̀ Romu ni wọ́n jẹ́. Wọ́n bá wá, wọ́n bẹ̀ wọ́n. Wọ́n sìn wọ́n jáde, wọ́n bá rọ̀ wọ́n pé kí wọ́n kúrò ninu ìlú. Nígbà tí wọ́n jáde kúrò lẹ́wọ̀n, wọ́n lọ sí ilé Lidia. Lẹ́yìn tí wọ́n rí àwọn onigbagbọ, tí wọ́n sì gbà wọ́n níyànjú, wọ́n kúrò níbẹ̀.
Iṣe Apo 16:11-40 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli; Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókan. Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀. Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidia, elése àlùkò, ará ìlú Tiatira, ẹni tí ó sin Ọlọ́run, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísí ohun tí a tí ẹnu Paulu sọ. Nígbà tí a sí bamitiisi rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtítọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá. Bí àwa tí n lọ sí ibi àdúrà náà, ọmọbìnrin kan tí o ní ẹ̀mí àfọ̀ṣẹ, pàdé wa, ẹni tí ó fi àfọ̀ṣẹ mú èrè púpọ̀ wá fún àwọn ọ̀gá rẹ̀: Òun náà ni ó ń tọ Paulu àti àwa lẹ́hìn, ó sì ń kígbe, pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí ni ìránṣẹ́ Ọlọ́run Ọ̀gá-ògo, tí ń kéde ọ̀nà ìgbàlà fún yin!” Ó sì ń ṣe èyí lọ́jọ́ púpọ̀, ṣùgbọ́n nígbà tí inú Paulu bàjẹ́, tí ó sì yípadà, ó wí fún ẹ̀mí náà pé, “Mo pàṣẹ fún ọ ní orúkọ Jesu Kristi kí o jáde kúrò lára rẹ̀!” Ó sí jáde ni wákàtí kan náà. Nígbà tí àwọn ọ̀gá rẹ̀ sì rí i pé, ìgbẹ́kẹ̀lé èrè wọn pin, wọ́n mú Paulu àti Sila, wọn sì wọ́ wọn lọ sí ọjà tọ àwọn aláṣẹ lọ; Nígbà tí wọ́n sì mú wọn tọ àwọn onídàájọ́ lọ, wọ́n wí pé, “Àwọn ọkùnrin wọ̀nyí tí í ṣe Júù, wọ́n ń yọ ìlú wa lẹ́nu jọjọ; Wọ́n sì ń kọ́ni ní àṣà tí kò yẹ fún wa, àwa ẹni tí í ṣe ara Romu, láti gbà àti láti tẹ̀lé.” Ọ̀pọ̀ ènìyàn sí jùmọ̀ dìde sì Paulu àti Sila. Àwọn olórí sí fà wọ́n ní aṣọ ya, wọ́n sí pàṣẹ pé, ki a fi ọ̀gọ̀ lù wọ́n. Nígbà tí wọ́n sì lù wọ́n púpọ̀, wọ́n sọ wọ́n sínú túbú, wọ́n kìlọ̀ fún onítúbú kí ó pa wọ́n mọ́ dáradára: Nígbà tí ó gbọ́ irú ìkìlọ̀ bẹ́ẹ̀, ó sọ̀ wọ́n sínú túbú tí inú lọ́hùn, ó sí kan àbà mọ wọ́n lẹ́sẹ̀. Ṣùgbọ́n láàrín ọ̀gànjọ́ Paulu àti Sila ń gbàdúrà, wọ́n sì ń kọrin ìyìn si Ọlọ́run: àwọn ara túbú sì ń tẹ́tí sí wọn. Lójijì ilẹ̀ mímì ńlá sì mi, tó bẹ́ẹ̀ tí ìpìlẹ̀ ilé túbú mì tìtì: lọ́gán, gbogbo ìlẹ̀kùn sì ṣí, ìdè gbogbo wọn sì tú sílẹ̀. Nígbà tí onítúbú si tají, tí o sì ri pé, àwọn ìlẹ̀kùn túbú tí ṣí sílẹ̀, ó fa idà rẹ̀ yọ, ó sì fẹ́ pa ara rẹ̀, ó ṣe bí àwọn ara túbú ti sálọ. Ṣùgbọ́n Paulu gbé ohun rẹ̀ sókè, wí pé, “Má ṣe pa ara rẹ lára: nítorí gbogbo wa ń bẹ níhìn-ín yìí!” Nígbà tí ó sì béèrè iná, ó bẹ́ wọ inú ilé, ó ń wárìrì, ó wólẹ̀ níwájú Paulu àti Sila. Ó sì mú wọn jáde, ó ní, “Alàgbà, kín ni ki èmi ṣe ki n lè là?” Wọ́n sì wí fún un pé, “Gbá Jesu Kristi Olúwa gbọ́, a ó sì gbà ọ́ là, ìwọ àti àwọn ará ilé rẹ pẹ̀lú.” Wọ́n sì sọ ọ̀rọ̀ Olúwa fún un, àti fún gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀. Ó sì mú wọn ní wákàtí náà lóru, ó wẹ ọgbẹ́ wọn; a sì bamitiisi rẹ̀, àti gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀ lójúkan náà. Ó sì mú wọn wá sí ilé rẹ̀, ó sì gbé oúnjẹ kalẹ̀ níwájú wọn, ó sì yọ̀ gidigidi pẹ̀lú gbogbo àwọn ará ilé rẹ̀, nítorí ó gba Ọlọ́run gbọ́. Ṣùgbọ́n nígbà tí ilẹ̀ mọ́, àwọn onídàájọ́ rán àwọn ọlọ́pàá pé, “Tú àwọn ènìyàn náà sílẹ̀.” Onítúbú sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Paulu, wí pé, “Àwọn onídàájọ́ ránṣẹ́ pé kí á da ìwọ àti Sila sílẹ̀. Ǹjẹ́ nísinsin yìí ẹ jáde kí ẹ sì máa lọ ní àlàáfíà.” Ṣùgbọ́n Paulu wí fún wọn pé, “Wọ́n lù wá ni gbangba, wọ́n sì sọ wá sínú túbú ni àìjẹ̀bi, àwa ẹni tí ì ṣe ara Romu. Ṣe nísinsin yìí wọ́n fẹ́ tì wá jáde níkọ̀kọ̀? Rara! Ṣùgbọ́n kí àwọn tìkára wọn wá mú wa jáde!” Àwọn ọlọ́pàá sì sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí fún àwọn onídàájọ́: ẹ̀rù sì bà wọ́n, nígbà tí wọ́n gbọ́ pé ará Romu ni Paulu àti Sila. Wọ́n sì wá, wọ́n ṣìpẹ̀ lọ́dọ̀ wọ́n, wọn sì mú wọn jáde, wọ́n sì bẹ̀ wọ́n pé, ki wọn jáde kúrò ni ìlú náà. Paulu àti Sila sì jáde nínú túbú, wọ́n sì wọ ilé Lidia lọ: nígbà tí wọn sì tí rí àwọn arákùnrin, wọ́n tù wọ́n nínú, wọn sì jáde kúrò.