Iṣe Apo 16:1-15

Iṣe Apo 16:1-15 Bibeli Mimọ (YBCV)

O si wá si Derbe on Listra: si kiyesi i, ọmọ-ẹhin kan wà nibẹ̀, ti a npè ni Timotiu, ọmọ obinrin kan ti iṣe Ju, ti o gbagbọ́; ṣugbọn Hellene ni baba rẹ̀: Ẹniti a rohin rẹ̀ rere lọdọ awọn arakunrin ti o wà ni Listra ati Ikonioni. On ni Paulu fẹ ki o ba on lọ; o si mu u, o si kọ ọ ni ilà, nitori awọn Ju ti o wà li àgbegbe wọnni: nitori gbogbo wọn mọ̀ pe, Hellene ni baba rẹ̀. Bi nwọn si ti nlà awọn ilu lọ, nwọn nfi awọn aṣẹ ti a ti pinnu le wọn lọwọ lati mã pa wọn mọ, lati ọdọ awọn aposteli ati awọn àgbagbà wá ti o wà ni Jerusalemu. Bẹ̃ni awọn ijọ si fẹsẹmulẹ ni igbagbọ́, nwọn si npọ̀ si i ni iye lojojumọ. Nwọn si là ẹkùn Frigia já, ati Galatia, ti a ti ọdọ Ẹmí Mimọ́ kọ̀ fun wọn lati sọ ọ̀rọ na ni Asia. Nigbati nwọn de ọkankan Misia, nwọn gbé e wò lati lọ si Bitinia: ṣugbọn Ẹmí Jesu kò gbà fun wọn. Nigbati nwọn si kọja lẹba Misia, nwọn sọkalẹ lọ si Troasi. Iran kan si hàn si Paulu li oru: ọkunrin kan ara Makedonia duro, o si mbẹ̀ ẹ, wipe, Rekọja wá si Makedonia, ki o si ran wa lọwọ. Nigbati o si ti ri iran na, lọgán awa mura lati lọ si Makedonia, a si gbà pe, Oluwa ti pè wa lati wasu ihinrere fun wọn. Nitorina nigbati awa ṣikọ̀ ni Troasi a ba ọ̀na tàra lọ si Samotrakea, ni ijọ keji a si de Neapoli; Lati ibẹ̀ awa si lọ si Filippi, ti iṣe ilu Makedonia, olu ilu ìha ibẹ, ilu labẹ Romani: awa si joko ni ilu yi fun ijọ melokan. Lọjọ isimi, awa si jade lọ si ẹhin odi ilu na, lẹba odò kan, nibiti a rò pe ibi adura wà; awa si joko, a si ba awọn obinrin ti o pejọ sọrọ. Ati obinrin kan ti orukọ rẹ̀ ijẹ Lidia, elesè àluko, ara ilu Tiatira, ẹniti o nsìn Ọlọrun, o gbọ́ ọ̀rọ wa: ọkàn ẹniti Oluwa ṣí, fetísi ohun ti a ti ẹnu Paulu sọ. Nigbati a si baptisi rẹ̀, ati awọn ará ile rẹ̀, o bẹ̀ wa, wipe, Bi ẹnyin ba kà mi li olõtọ si Oluwa, ẹ wá si ile mi, ki ẹ si wọ̀ nibẹ̀. O si rọ̀ wa.

Iṣe Apo 16:1-15 Yoruba Bible (YCE)

Paulu dé Dabe ati Listira. Onigbagbọ kan tí ń jẹ́ Timoti wà níbẹ̀. Ìyá rẹ̀ jẹ́ Juu tí ó gba Jesu gbọ́; ṣugbọn Giriki ni baba rẹ̀. Àwọn arakunrin ní Listira ati Ikoniomu ròyìn Timoti yìí dáradára. Òun ni ó wu Paulu láti mú lọ sí ìrìn-àjò rẹ̀, nítorí náà, ó mú un, ó kọ ọ́ nílà nítorí àwọn Juu tí ó wà ní agbègbè ibẹ̀; nítorí gbogbo wọn ni wọ́n mọ̀ pé Giriki ni baba rẹ̀. Bí wọ́n ti ń lọ láti ìlú dé ìlú, wọ́n ń sọ fún wọn nípa ìpinnu tí àwọn aposteli ati àwọn àgbààgbà ní Jerusalẹmu ṣe, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú pé kí wọ́n pa wọ́n mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ túbọ̀ ń lágbára sí i ninu igbagbọ, tí wọ́n sì ń pọ̀ sí i ní iye lojoojumọ. Wọ́n gba ilẹ̀ Firigia ati Galatia kọjá. Ẹ̀mí Mímọ́ kò gbà wọ́n láàyè láti lọ waasu ọ̀rọ̀ Oluwa ní Esia. Nígbà tí wọ́n súnmọ́ Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia. Ṣugbọn Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. Nígbà tí wọ́n ti la Misia kọjá, wọ́n dé Tiroasi. Nígbà tí ó di alẹ́, Paulu rí ìran kan. Ó rí ọkunrin kan ará Masedonia tí ó dúró, tí ó ń bẹ̀ ẹ́ pé, “Sọdá sí Masedonia níbí kí o wá ràn wá lọ́wọ́.” Gbàrà tí ó rí ìran náà, a wá ọ̀nà láti lọ sí Masedonia; a pinnu pé Ọlọrun ni ó pè wá láti lọ waasu fún wọn níbẹ̀. Nígbà tí a wọ ọkọ̀ láti Tiroasi, a lọ tààrà sí Samotirake. Ní ọjọ́ keji a gúnlẹ̀ ní Neapoli. Láti ibẹ̀, a lọ sí Filipi tíí ṣe olú-ìlú ilẹ̀ Masedonia. Àwọn ará Romu ni wọ́n tẹ ìlú yìí dó. A bá wà níbẹ̀ fún ọjọ́ mélòó kan. Ní Ọjọ́ Ìsinmi a jáde lọ sẹ́yìn odi ìlú lẹ́bàá odò, níbi tí a rò pé a óo ti rí ibi tí wọn máa ń gbadura. A bá jókòó, a bá àwọn obinrin tí ó péjọ níbẹ̀ sọ̀rọ̀. Obinrin kan wà níbẹ̀ tí ó ń jẹ́ Lidia, ará Tiatira, tí ó ń ta aṣọ àlàárì. Ó jẹ́ ẹnìkan tí ó ń sin Ọlọrun. Ó fetí sílẹ̀, Ọlọrun ṣí i lọ́kàn láti gba ohun tí Paulu ń sọ. Òun ati àwọn ará ilé rẹ̀ gba ìrìbọmi. Lẹ́yìn náà, ó bẹ̀ wá pé, bí a bá gbà pé òun jẹ́ onigbagbọ nítòótọ́, kí á máa bọ̀ ní ilé òun kí á máa bá àwọn gbé. Ó tẹnu mọ́ ọn títí a fi gbà.

Iṣe Apo 16:1-15 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ó sì wá sí Dabe àti Lysra: sí kíyèsi i, ọmọ-ẹ̀yìn kan wà níbẹ̀, tí a ń pè ní Timotiu, ọmọ obìnrin kan tí í ṣe Júù, tí ó gbàgbọ́; ṣùgbọ́n Giriki ní baba rẹ̀. Ẹni tí a ròhìn rẹ̀ ní rere lọ́dọ̀ àwọn arákùnrin tí ó wà ní Lysra àti Ikoniomu. Òun ni Paulu fẹ́ kí ó bá òun lọ; ó sì mú un, ó sì kọ ọ́ ní ilà, nítorí àwọn Júù tí ó wà ní agbègbè wọ̀nyí: nítorí gbogbo wọn mọ̀ pé, Giriki ni baba rẹ̀. Bí wọn sì ti ń la àwọn ìlú lọ, wọ́n ń fi àwọn àṣẹ, tí a tí pinnu láti ọ̀dọ̀ àwọn aposteli àti àwọn alàgbà tí ó wà ní Jerusalẹmu, lé wọn lọ́wọ́ láti máa pa wọ́n mọ́. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ìjọ sì fẹsẹ̀múlẹ̀ ní ìgbàgbọ́, wọn sí ń pọ̀ sí i ní iye lójoojúmọ́. Wọ́n sì la agbègbè Frigia já, àti Galatia, nítorí tí Ẹ̀mí Mímọ́ kọ̀ fún wọn láti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Asia. Nígbà tí wọ́n dé ọ̀kánkán Misia, wọ́n gbìyànjú láti lọ sí Bitinia, ṣùgbọ́n Ẹ̀mí Jesu kò gbà fún wọn. Nígbà tí wọ́n sì kọjá lẹ́bàá Misia, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Troasi. Ìran kan si hàn sì Paulu ni òru: Ọkùnrin kan ará Makedonia dúró, ó sì ń bẹ̀ ẹ́, wí pé, “Rékọjá wá sí Makedonia, kí o sí ràn wá lọ́wọ́!” Nígbà tí ó sì tí rí ìran náà, lọ́gán ó múra láti lọ sí Makedonia, a ka á sí pé, Ọlọ́run tí pè wá láti wàásù ìhìnrere fún wọn. Nítorí náà nígbà tí àwa ṣíkọ̀ ní Troasi a ba ọ̀nà tààrà lọ sí Samotrakea, ni ọjọ́ kejì a sì dé Neapoli; Láti ibẹ̀ àwa sì lọ si Filipi, tí í ṣe ìlú Makedonia, olú ìlú ìhà ibẹ̀, ìlú lábẹ́ Romu, àwa sì jókòó ní ìlú yìí fún ọjọ́ mélòókan. Lọ́jọ́ ìsinmi, àwa sí jáde lọ sí ẹ̀yìn odi ìlú náà, lẹ́bàá odò kan, níbi tí a rò pé ibi àdúrà wà; àwa sí jókòó, a sì bá àwọn obìnrin tí o péjọ sọ̀rọ̀. Àti obìnrin kan tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Lidia, elése àlùkò, ará ìlú Tiatira, ẹni tí ó sin Ọlọ́run, ó gbọ́ ọ̀rọ̀ wa, ọkàn ẹni tí Olúwa ṣí láti fetísí ohun tí a tí ẹnu Paulu sọ. Nígbà tí a sí bamitiisi rẹ̀, àti àwọn ara ilé rẹ̀, ó bẹ̀ wá, wí pé, “Bí ẹ̀yin bá kà mí ni olóòtítọ́ sí Olúwa, ẹ wá si ilé mi, kí ẹ sí wọ̀ níbẹ̀!” O sí rọ̀ wá.