Iṣe Apo 14:8-28

Iṣe Apo 14:8-28 Bibeli Mimọ (YBCV)

Ọkunrin kan si joko ni Listra, ẹniti ẹsẹ rẹ̀ kò mokun, arọ lati inu iya rẹ̀ wá, ti kò rìn ri. Ọkunrin yi gbọ́ bi Paulu ti nsọ̀rọ: ẹni, nigbati o tẹjumọ́ ọ, ti o si ri pe, o ni igbagbọ́ fun imularada, O wi fun u li ohùn rara pe, Dide duro ṣanṣan li ẹsẹ rẹ. O si nfò soke o si nrìn. Nigbati awọn enia si ri ohun ti Paulu ṣe, nwọn gbé ohùn wọn soke li ède Likaonia, wipe, Awọn oriṣa sọkalẹ tọ̀ wa wá ni àwọ enia. Nwọn si pè Barnaba ni Jupiteri ati Paulu ni Herme nitori on li olori ọ̀rọ isọ. Alufa Jupiteri ti ile oriṣa rẹ̀ wà niwaju ilu wọn, si mu malu ati màriwo wá si ẹnubode, on iba si rubọ pẹlu awọn enia. Ṣugbọn nigbati awọn aposteli Barnaba on Paulu gbọ́, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si sure wọ̀ inu awujọ, nwọn nke rara. Nwọn si nwipe, Ará, ẽṣe ti ẹnyin fi nṣe nkan wọnyi? Enia oniru ìwa kanna bi ẹnyin li awa pẹlu ti a nwasu ihinrere fun nyin, ki ẹnyin ki o yipada kuro ninu ohun asan wọnyi si Ọlọrun alãye, ti o da ọrun on aiye, ati okun, ati ohun gbogbo ti mbẹ ninu wọn: Ẹni, ni awọn iran ti o ti kọja jọwọ gbogbo orilẹ-ède, lati mã rìn li ọna tiwọn. Ṣugbọn ko fi ara rẹ̀ silẹ li ailẹri, ni ti o nṣe rere, o nfun nyin ni òjo lati ọrun wá, ati akokò eso, o nfi onjẹ ati ayọ̀ kún ọkàn nyin. Diẹ li o kù ki nwọn ki o ma le fi ọ̀rọ wọnyi da awọn enia duro, ki nwọn ki o máṣe rubọ bọ wọn. Awọn Ju kan si ti Antioku ati Ikonioni wá, nigbati nwọn yi awọn enia li ọkàn pada, nwọn si sọ Paulu li okuta, nwọn wọ́ ọ jade kuro ni ilu na, nwọn ṣebi o kú. Ṣugbọn nigbati awọn ọmọ-ẹhin duro tì i yiká, o dide, o si wọ̀ ilu na lọ: ni ijọ keji o ba Barnaba lọ si Derbe. Nigbati nwọn si ti wasu ihinrere fun ilu na, ti nwọn si ni ọmọ-ẹ̀hin pupọ, nwọn pada lọ si Listra, ati Ikonioni, ati si Antioku. Nwọn nmu awọn ọmọ-ẹhin li ọkàn le, nwọn ngbà wọn niyanju lati duro ni igbagbọ́, ati pe ninu ipọnju pipọ li awa o fi wọ̀ ijọba Ọlọrun. Nigbati nwọn si ti yàn awọn àgbagba fun olukuluku ijọ, ti nwọn si ti fi àwẹ gbadura, nwọn fi wọn le Oluwa lọwọ, ẹniti nwọn gbagbọ́. Nigbati nwọn si là Pisidia já, nwọn wá si Pamfilia. Nigbati nwọn si ti sọ ọ̀rọ na ni Perga, nwọn sọkalẹ lọ si Atalia: Ati lati ibẹ̀ lọ nwọn ba ti ọkọ̀ lọ si Antioku, lati ibiti a gbé ti fi wọn le õre-ọfẹ Ọlọrun lọwọ, fun iṣẹ ti nwọn ṣe pari. Nigbati nwọn si de, ti nwọn si pè ijọ jọ, nwọn ròhin gbogbo ohun ti Ọlọrun fi wọn ṣe, ati bi o ti ṣí ilẹkun igbagbọ́ fun awọn Keferi. Ki iṣe igba diẹ ni nwọn ba awọn ọmọ-ẹhin gbé.

Iṣe Apo 14:8-28 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan wà ní ìjókòó ní Listira tí ó yarọ. Láti ìgbà tí wọ́n ti bí i ni ó ti yarọ, kò fi ẹsẹ̀ rẹ̀ rìn rí. Ọkunrin yìí fetí sílẹ̀ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀. Paulu wá tẹjú mọ́ ọn lára, ó rí i pé ó ní igbagbọ pé wọ́n lè mú òun lára dá. Ó bá kígbe sókè, ó ní, “Dìde, kí o dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ bí eniyan.” Ni ọkunrin arọ náà bá fò sókè, ó bá ń rìn. Nígbà tí àwọn eniyan rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n kígbe ní èdè Likaonia pé, “Àwọn oriṣa ti di eniyan, wọ́n tọ̀run wá sáàrin wa!” Wọ́n pe Banaba ní Seusi, wọ́n pe Paulu ní Herime nítorí òun ni ó ń ṣe ògbifọ̀. Ní òde kí á tó wọ odi ìlú ni tẹmpili Seusi wà. Baba olórìṣà Seusi bá mú mààlúù ati òdòdó jìngbìnnì, òun ati ọpọlọpọ èrò, wọ́n ń bọ̀ lẹ́nu odi ìlú níbi tí pẹpẹ Seusi wà, wọ́n fẹ́ wá bọ wọ́n. Nígbà tí Banaba aposteli ati Paulu aposteli gbọ́, wọ́n fa ẹ̀wù wọn ya, wọ́n bá pa kuuru mọ́ àwọn èrò, wọ́n ń kígbe pé, “Ẹ̀yin eniyan, kí ló dé tí ẹ fi ń ṣe irú eléyìí? Eniyan bíi yín ni àwa náà. À ń waasu fun yín pé kí ẹ yipada kúrò ninu àwọn ohun asán wọnyi, kí ẹ sin Ọlọrun alààyè, ẹni tí ó dá ọ̀run ati ayé, ati òkun ati ohun gbogbo tí ó wà ninu wọn. Ní ìgbà ayé àwọn tí ó ti kọjá, ó jẹ́ kí gbogbo àwọn orílẹ̀-èdè máa ṣe ohun tí ó wù wọ́n. Sibẹ kò ṣàì fi àmì ara rẹ̀ hàn: ó ń ṣe iṣẹ́ rere, ó ń rọ òjò fun yín láti ọ̀run, ó ń mú èso jáde lásìkò, ó ń fun yín ní oúnjẹ, ó tún ń mú inú yín dùn.” Pẹlu gbogbo ọ̀rọ̀ yìí, agbára-káká ni wọn kò fi jẹ́ kí àwọn eniyan bọ wọ́n. Ṣugbọn àwọn Juu dé láti Antioku ati Ikoniomu, wọ́n yí ọkàn àwọn eniyan pada, wọ́n sọ Paulu ní òkúta, wọ́n sì wọ́ ọ lọ sẹ́yìn odi, wọ́n ṣebí ó ti kú. Ṣugbọn àwọn onigbagbọ pagbo yí i ká títí ó fi dìde tí ó sì wọ inú ìlú lọ. Ní ọjọ́ keji ó gbéra lọ sí Dabe pẹlu Banaba. Wọ́n waasu ìyìn rere ní ìlú náà, àwọn eniyan pupọ sì di onigbagbọ. Wọ́n bá pada sí Listira ati Ikoniomu ati Antioku ní Pisidia. Wọ́n ń mú àwọn onigbagbọ lọ́kàn le pé kí wọ́n dúró ṣinṣin ninu igbagbọ. Wọ́n ń fi yé wọn pé kí eniyan tó wọ ìjọba Ọlọrun, ó níláti ní ọpọlọpọ ìṣòro. Wọ́n yan àgbà ìjọ fún wọn ninu ìjọ kọ̀ọ̀kan. Nígbà tí wọ́n ti gbadura, tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, wọ́n fi wọ́n lé ọwọ́ Oluwa tí wọ́n gbẹ́kẹ̀ wọn lé. Wọ́n wá gba Pisidia kọjá lọ sí Pamfilia. Nígbà tí wọ́n ti waasu ìyìn rere ní Pega, wọ́n lọ sébùúté ní Atalia. Wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi láti ibẹ̀ lọ sí Antioku ní Siria níbi tí wọ́n ti kọ́ fi wọ́n sábẹ́ ojurere Ọlọrun fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣẹ̀ṣẹ̀ parí. Nígbà tí wọ́n dé ibẹ̀, wọ́n pe gbogbo ìjọ jọ, wọ́n ròyìn ohun gbogbo tí Ọlọrun tọwọ́ wọn ṣe ati bí Ọlọrun ti ṣínà fún àwọn tí kì í ṣe Juu láti gbàgbọ́. Wọ́n dúró níbẹ̀ lọ́dọ̀ àwọn onigbagbọ fún ìgbà pípẹ́.

Iṣe Apo 14:8-28 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọkùnrin kan sí jókòó ni Lysra, ẹni tí ẹsẹ̀ rẹ̀ kò mókun, arọ láti inú ìyá rẹ̀ wá, tí kò rìn rí. Ọkùnrin yìí gbọ́ bí Paulu ti ń sọ̀rọ̀: ẹni, nígbà tí ó tẹjúmọ́ ọn ti ó sì rí i pé, ó ni ìgbàgbọ́ fún ìmúláradá. Ó wí fún un ní ohùn rara pé, “Dìde dúró ṣánṣán lórí ẹsẹ̀ rẹ!” Ó sì ń fò sókè, ó sì ń rìn. Nígbà tí àwọn ènìyàn sì rí ohun tí Paulu ṣe, wọ́n gbé ohùn wọn sókè ni èdè Likaonia, wí pé, “Àwọn ọlọ́run sọ̀kalẹ̀ tọ̀ wá wá ni àwọ̀ ènìyàn!” Wọn sì pe Barnaba ni Seusi àti Paulu ni Hermesi nítorí òun ni olórí ọ̀rọ̀ sísọ. Àlùfáà Seusi, ẹni ti ilé òrìṣà rẹ̀ wá lẹ́yìn odi ìlú wọn sì mú màlúù àti màrìwò wá sí ẹnu ibodè láti rú ẹbọ pẹ̀lú ìjọ ènìyàn sí àwọn aposteli wọ̀nyí. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn aposteli Barnaba àti Paulu gbọ́, wọ́n fa aṣọ wọn ya, wọn sí súré wọ inú àwùjọ, wọn ń ké rara pé: “Ará, èéṣe ti ẹ̀yin fi ń ṣe nǹkan wọ̀nyí? Ènìyàn bí ẹ̀yin náà ni àwa ń ṣe pẹ̀lú, ti a sì ń wàásù ìhìnrere fún yín, kí ẹ̀yin ba à lè yípadà kúrò nínú ohun asán wọ̀nyí sí Ọlọ́run alààyè, tí ó dá ọ̀run àti ayé, òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú wọn. Ní ìran tí ó ti kọjá, ó faradà á fún gbogbo orílẹ̀-èdè, láti máa rìn ni ọ̀nà tiwọn. Ṣùgbọ́n kò fi ara rẹ̀ sílẹ̀ ní àìní ẹ̀rí, ní ti pé ó ṣe rere, ó ń fún yín lójò láti ọ̀run wá, àti ni àkókò èso, ó ń fi oúnjẹ àti ayọ̀ kún ọkàn yín.” Díẹ̀ ni ó kù kí wọn má le fi ọ̀rọ̀ wọ̀nyí dá àwọn ènìyàn dúró, kí wọn má ṣe rú ẹbọ bọ wọ́n. Àwọn Júù kan sì ti Antioku àti Ikoniomu wá, nígbà tí wọ́n yí àwọn ènìyàn lọ́kàn padà, wọ́n sì sọ Paulu ní òkúta, wọ́n wọ́ ọ kúrò sí ẹ̀yin odi ìlú náà, wọn ṣe bí ó ti kú. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn ọmọ-ẹ̀yìn dúró ti i yíká, ó dìde ó sì padà wọ inú ìlú náà lọ. Ní ọjọ́ kejì ó bá Barnaba lọ sí Dabe. Nígbà tí wọ́n sì ti wàásù ìhìnrere fún ìlú náà, tí wọ́n sì ni ọmọ-ẹ̀yìn púpọ̀, wọn padà lọ sí Lysra, àti Ikoniomu, àti Antioku, wọn sì ń mú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn lọ́kàn le, wọ́n sì ń gbà wọ́n níyànjú láti dúró nínú ìgbàgbọ́, àti pé nínú ìpọ́njú púpọ̀, ni àwa ó fi wọ ìjọba Ọlọ́run. Nígbà tí wọ́n sì ti yan àwọn alàgbà fún olúkúlùkù ìjọ, tí wọn sì ti fi àwẹ̀ gbàdúrà, wọn fi wọ́n lé Olúwa lọ́wọ, ẹni tí wọn gbàgbọ́. Nígbà tí wọn sí la Pisidia já, wọ́n wá sí pamfilia. Nígbà tí wọn sì ti sọ ọ̀rọ̀ náà ni Perga, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Atalia: Àti láti ibẹ̀ lọ wọ́n ṣíkọ̀ lọ sí Antioku ní ibi tí a gbé ti fi wọ́n lé oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run lọ́wọ́, fún iṣẹ́ tí wọ́n ṣe parí Nígbà tí wọ́n sì dé, tí wọ́n sì pé ìjọ jọ, wọ́n ròhìn gbogbo ohun tí Ọlọ́run fi wọ́n ṣe, àti bí ó ti ṣí ìlẹ̀kùn ìgbàgbọ́ fún àwọn aláìkọlà. Níbẹ̀ ni wọ́n ń gbé pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ni ọjọ́ púpọ̀.