Iṣe Apo 13:21-23
Iṣe Apo 13:21-23 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ati lẹhinna ni nwọn bère ọba: Ọlọrun si fun wọn ni Saulu ọmọ Kiṣi, ọkunrin kan ninu ẹ̀ya Benjamini, fun ogoji ọdún. Nigbati o si mu u kuro, o gbé Dafidi dide li ọba fun wọn; ẹniti o si jẹri rẹ̀ pe, Mo ri Dafidi ọmọ Jesse ẹni bi ọkàn mi, ti yio ṣe gbogbo ifẹ mi. Lati inu iru-ọmọ ọkunrin yi ni Ọlọrun ti gbe Jesu Olugbala dide fun Israeli gẹgẹ bi ileri
Iṣe Apo 13:21-23 Yoruba Bible (YCE)
Lẹ́yìn náà wọ́n bèèrè fún ọba; Ọlọrun bá fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, láti inú ẹ̀yà Bẹnjamini. Ó jọba fún ogoji ọdún. Nígbà tí Ọlọrun yọ ọ́ lóyè, ó gbé Dafidi dìde fún wọn bí ọba. Ọlọrun jẹ́rìí sí ìwà rẹ̀ nígbà tí ó sọ pé, ‘Mo rí i pé Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ẹni tí ọkàn mi ń fẹ́, ẹni tí yóo ṣe ohun gbogbo bí mo ti fẹ́.’ Láti inú ìran rẹ̀ ni Ọlọrun ti gbé Jesu dìde bí Olùgbàlà fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ìlérí.
Iṣe Apo 13:21-23 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)
Lẹ́yìn náà ni wọ́n sì béèrè ọba; Ọlọ́run sì fún wọn ní Saulu ọmọ Kiṣi, ọkùnrin kan nínú ẹ̀yà Benjamini, fún ogójì ọdún. Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’ “Láti inú irú-ọmọ ọkùnrin yìí ni Ọlọ́run ti gbé Jesu Olùgbàlà dìde fún Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìlérí.