Iṣe Apo 13:1-13

Iṣe Apo 13:1-13 Bibeli Mimọ (YBCV)

AWỌN woli ati awọn olukọni si mbẹ ninu ijọ ti o wà ni Antioku; Barnaba, ati Simeoni ti a npè ni Nigeri, ati Lukiu ara Kirene, ati Manaeni, ti a tọ́ pọ̀ pẹlu Herodu tetrarki, ati Saulu. Bi nwọn si ti njọsìn fun Oluwa, ti nwọn si ngbàwẹ, Ẹmí Mimọ́ wipe, Ẹ yà Barnaba on Saulu sọtọ̀ fun mi fun iṣẹ ti mo ti pè wọn si. Nigbati nwọn si ti gbàwẹ, ti nwọn si ti gbadura, ti nwọn si ti gbe ọwọ́ le wọn, nwọn si rán wọn lọ. Njẹ bi a ti rán wọn lati ọwọ́ Ẹmí Mimọ́ lọ, nwọn sọkalẹ lọ si Seleukia; lati ibẹ̀ nwọn si wọkọ̀ lọ si Kipru. Nigbati nwọn si wà ni Salami, nwọn nwasu ọ̀rọ Ọlọrun ni sinagogu awọn Ju: nwọn si ni Johanu pẹlu fun iranṣẹ wọn. Nigbati nwọn si là gbogbo erekùṣu já de Pafo, nwọn ri ọkunrin kan, oṣó, woli eke, Ju, orukọ ẹniti ijẹ Barjesu, Ẹniti o wà lọdọ Sergiu Paulu bãlẹ ilu na, amoye enia. On na li o ranṣẹ pè Barnaba on Saulu, o si fẹ gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun. Ṣugbọn Elima oṣó na (nitori bẹ̃ni itumọ̀ orukọ rẹ̀) o takò wọn, o nfẹ pa bãlẹ ni ọkàn da kuro ni igbagbọ́. Ṣugbọn Saulu (ti a si npè ni Paulu), o kún fun Ẹmí Mimọ́, o si tẹjumọ́ ọ, o si wipe, Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po? Njẹ nisisiyi, wo o, ọwọ́ Oluwa mbẹ lara rẹ, iwọ o si fọju, iwọ kì yio ri õrùn ni sã kan. Lojukanna owusuwusu ati òkunkun si bò o; o si nwá enia kiri lati fà a lọwọ lọ. Nigbati bãlẹ ri ohun ti o ṣe, o gbagbọ́, ẹnu si yà a si ẹkọ́ Oluwa. Nigbati Paulu ati awọn ti o wà pẹlu rẹ̀ si ṣikọ̀ ni Pafo, nwọn wá si Perga ni Pamfilia: Johanu si fi wọn silẹ, o si pada lọ si Jerusalemu.

Iṣe Apo 13:1-13 Yoruba Bible (YCE)

Àwọn wolii ati àwọn olùkọ́ wà ninu ìjọ tí ó wà ní Antioku. Ninu wọn ni Banaba ati Simeoni tí wọn ń pè ní Adúláwọ̀ wà, ati Lukiusi ará Kirene, ati Manaeni tí wọ́n jọ tọ́ dàgbà pẹlu Hẹrọdu baálẹ̀, ati Saulu. Bí wọ́n ti jọ ń sin Oluwa, tí wọ́n ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ sọ fún wọn pé, “Ẹ ya Banaba ati Saulu sọ́tọ̀ fún mi, fún iṣẹ́ pataki kan tí mo ti pè wọ́n fún.” Lẹ́yìn tí wọ́n ti gbààwẹ̀, tí wọ́n sì gbadura, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn lórí, wọ́n sì ní kí wọ́n máa lọ. Lẹ́yìn tí Ẹ̀mí Mímọ́ ti fi iṣẹ́ lé àwọn mejeeji lọ́wọ́, wọ́n lọ sí Selesia. Láti ibẹ̀ wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Kipru. Nígbà tí wọ́n dé Salami, wọ́n waasu ọ̀rọ̀ Ọlọrun ninu àwọn ilé ìpàdé àwọn Juu. Wọ́n mú Johanu lọ́wọ́ kí wọn lè máa rí i rán níṣẹ́. Wọ́n la erékùṣù náà kọjá, wọ́n dé Pafọsi. Níbẹ̀ ni wọ́n rí ọkunrin Juu kan, tí ó ń pidán, tí ó fi ń tú àwọn eniyan jẹ. Orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Ba-Jesu. Ọkunrin yìí ń ṣiṣẹ́ lọ́dọ̀ gomina ilẹ̀ náà, tí ń jẹ́ Segiu Paulu. Gomina yìí jẹ́ olóye eniyan. Ó ranṣẹ pe Banaba ati Saulu nítorí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọrun. Ṣugbọn Elimasi, tí ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀ jẹ́ onídán, takò wọ́n. Ó ń wá ọ̀nà láti yí ọkàn gomina pada kúrò ninu igbagbọ. Ẹ̀mí Mímọ́ bá gbé Saulu, tí a tún ń pè ní Paulu. Ó tẹjú mọ́ onídán náà, ó ní, “Ìwọ yìí, tí ó jẹ́ kìkì oríṣìíríṣìí ẹ̀tàn ati ìwà burúkú! Ìwọ ọmọ èṣù yìí! Ọ̀tá gbogbo nǹkan tí ó dára! O kò ní yé yí ọ̀nà títọ́ Oluwa po! Ọwọ́ Oluwa tẹ̀ ọ́ nisinsinyii. Ojú rẹ yóo fọ́, o kò ní lè rí oòrùn fún ìgbà kan!” Lójú kan náà, ìkùukùu dúdú dà bò ó. Ó bá ń tá ràrà, ó ń wá ẹni tí yóo fà á lọ́wọ́ kiri. Nígbà tí gomina rí ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó gbàgbọ́; nítorí pé ẹ̀kọ́ nípa Oluwa yà á lẹ́nu. Nígbà tí Paulu ati àwọn ẹlẹgbẹ́ rẹ̀ kúrò ní Pafọsi, wọ́n wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí ìlú Pega ní ilẹ̀ Pamfilia. Johanu fi wọ́n sílẹ̀ níbẹ̀, ó pada lọ sí Jerusalẹmu.

Iṣe Apo 13:1-13 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Àwọn wòlíì àti àwọn olùkọ́ni sì ń bẹ nínú ìjọ ti ó wà ni Antioku; Barnaba àti Simeoni tí a ń pè ni Nigeri, àti Lukiu ará Kirene, àti Manaeni (ẹni tí a tọ́ pọ̀ pẹ̀lú Herodu tetrarki) àti Saulu. Bí wọn sì ti ń jọ́sìn fún Olúwa, tí wọ́n sì ń gbààwẹ̀, Ẹ̀mí Mímọ́ wí pé, “Ẹ ya Barnaba àti Saulu sọ́tọ̀ fún mi fún iṣẹ́ ti mo ti pè wọ́n sí!” Nígbà tí wọ́n sì ti gbààwẹ̀, tí wọn sì ti gbàdúrà, wọ́n gbé ọwọ́ lé wọn, wọ́n sì rán wọn lọ. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi. Nígbà ti wọ́n sì wà ni Salami, wọ́n ń wàásù ọ̀rọ̀ Ọlọ́run ní Sinagọgu àwọn Júù. Johanu náà sì wà pẹ̀lú wọn láti ràn wọ́n lọ́wọ́ fún ìránṣẹ́ wọn. Nígbà tí wọ́n sì la gbogbo erékùṣù já dé Pafosi, wọ́n rí ọkùnrin oṣó àti wòlíì èké kan ti i ṣe Júù, orúkọ ẹni ti ó ń jẹ́ Bar-Jesu. Ó wà lọ́dọ̀ Segiu Paulusi baálẹ̀ ìlú náà tí í ṣe amòye ènìyàn. Òun náà ni ó ránṣẹ́ pe Barnaba àti Saulu, nítorí tí ó fẹ́ gbọ́ ọ̀rọ̀ Ọlọ́run. Ṣùgbọ́n Elimu oṣó (nítorí bẹ́ẹ̀ ni ìtumọ̀ orúkọ rẹ̀) takò wọ́n, ó ń fẹ́ pa baálẹ̀ ni ọkàn dà kúrò ni ìgbàgbọ́. Ṣùgbọ́n Saulu ti a ń pè ni Paulu, ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, ó sì tẹjúmọ́ Elimu, ó sì wí pé, “Ìwọ ti ó kún fún àrékérekè gbogbo, àti fún ìwà ìkà gbogbo, ìwọ ọmọ èṣù, ìwọ ọ̀tá ohun gbogbo, ìwọ kì yóò ha dẹ́kun láti máa yí ọ̀nà òtítọ́ Olúwa po? Ǹjẹ́ nísinsin yìí wò ó, ọwọ́ Olúwa ń bẹ lára rẹ̀, ìwọ ó sì fọjú ìwọ kì yóò rí oòrùn ní sá à kan!” Lójúkan náà, ìkùùkuu àti òkùnkùn sí bò ó; ó sì ń wá ènìyàn kiri láti fa òun lọ́wọ́ lọ. Nígbà tí baálẹ̀ rí ohun tí ó ṣe, ó gbàgbọ́, ẹnu sì yà á sì ẹ̀kọ́ Olúwa. Nígbà tí Paulu àti àwọn tí ó wà pẹ̀lú rẹ̀ si ṣíkọ̀ ni Pafosi wọ́n wá sí Perga ni pamfilia: Johanu sì fi wọ́n sílẹ̀, ó sì padà lọ sí Jerusalẹmu.