Iṣe Apo 11:23-24
Iṣe Apo 11:23-24 Yoruba Bible (YCE)
Nígbà tí ó dé, tí ó rí bí Ọlọrun ti ṣiṣẹ́ láàrin wọn, inú rẹ̀ dùn. Ó gba gbogbo wọn níyànjú pé kí wọ́n fi gbogbo ọkàn wọn dúró ti Oluwa pẹlu òtítọ́. Nítorí Banaba jẹ́ eniyan rere, tí ó kún fún Ẹ̀mí Mímọ́, tí ó sì gbàgbọ́ tọkàntọkàn, ọ̀pọ̀ eniyan ni ó di onigbagbọ.
Iṣe Apo 11:23-24 Bibeli Mimọ (YBCV)
Ẹniti, nigbati o de ti o si ri õre-ọfẹ Ọlọrun, o yọ̀, o si gba gbogbo wọn niyanju pe, pẹlu ipinnu ọkàn ni ki nwọn ki o fi ara mọ́ Oluwa. Nitori on jẹ enia rere, o si kún fun Ẹmí Mimọ́, ati fun igbagbọ́: enia pipọ li a si kà kún Oluwa.