Iṣe Apo 10:1-48

Iṣe Apo 10:1-48 Bibeli Mimọ (YBCV)

ỌKUNRIN kan si wà ni Kesarea ti a npè ni Korneliu, balogun ọrún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun ti a npè ni ti Itali, Olufọkansìn, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹniti o nṣe itọrẹ-ãnu pipọ fun awọn enia, ti o si ngbadura sọdọ Ọlọrun nigbagbogbo. Niwọn wakati kẹsan ọjọ, o ri ninu iran kedere angẹli Ọlọrun kan wọle tọ̀ ọ wá, o si wi fun u pe, Korneliu. Nigbati o si tẹjumọ́ ọ, ti ẹ̀ru si ba a, o ni, Kini, Oluwa? O si wi fun u pe, Adura rẹ ati ọrẹ-ãnu rẹ ti goke lọ iwaju Ọlọrun fun iranti. Si rán enia nisisiyi lọ si Joppa, ki nwọn si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru: O wọ̀ si ile ẹnikan Simoni alawọ, ti ile rẹ̀ wà leti okun: on ni yio sọ fun ọ bi iwọ o ti ṣe. Nigbati angẹli na ti o ba Korneliu sọ̀rọ si fi i silẹ lọ, o pè meji ninu awọn iranṣẹ ile rẹ̀, ati ọmọ-ogun olufọkànsin kan, ninu awọn ti ima duro tì i nigbagbogbo; Nigbati o si ti rohin ohun gbogbo fun wọn, o rán wọn lọ si Joppa. Ni ijọ keji bi nwọn ti nlọ li ọ̀na àjo wọn, ti nwọn si sunmọ ilu na, Peteru gùn oke ile lọ igbadura niwọn wakati kẹfa ọjọ: Ebi si pa a gidigidi, on iba si jẹun: ṣugbọn nigbati nwọn npèse, o bọ si ojuran, O si ri ọrun ṣí, ohun elo kan si sọkalẹ bi gọgọwú nla, ti a ti igun mẹrẹrin, sọkalẹ si ilẹ. Ninu rẹ̀ li olorijorí ẹranko ẹlẹsẹ mẹrin wà, ati ohun ti nrakò li aiye ati ẹiyẹ oju ọrun. Ohùn kan si fọ̀ si i pe, Dide, Peteru; mã pa ki o si mã jẹ. Ṣugbọn Peteru dahùn pe, Agbẹdọ, Oluwa; nitori emi kò jẹ ohun èwọ ati alaimọ́ kan ri. Ohùn kan si tún fọ̀ si i lẹkeji pe, Ohun ti Ọlọrun ba ti wẹ̀nu, iwọ máṣe pè e li èwọ mọ́. Eyi si ṣe li ẹrinmẹta: lojukanna a si gbé ohun elo na pada lọ soke ọrun. Bi o si ti ngọ́ Peteru ninu ara rẹ̀ bi a ba ti mọ̀ iran ti on ri yi si, si wo o, awọn ọkunrin ti a rán ti ọdọ Korneliu wá de, nwọn mbère ile Simoni, nwọn duro li ẹnu-ọ̀na, Nwọn nahùn bère bi Simoni ti a npè ni Peteru, wọ̀ nibẹ. Bi Peteru si ti nronu iran na, Ẹmí wi fun u pe, Wo o, awọn ọkunrin mẹta nwá ọ. Njẹ dide, sọkalẹ ki o si ba wọn lọ, máṣe kọminu ohunkohun: nitori emi li o rán wọn. Nigbana ni Peteru sọkalẹ tọ̀ awọn ọkunrin ti a rán si i lati ọdọ Korneliu wá; o ni, Wo o, emi li ẹniti ẹnyin nwá: ere idi rẹ̀ ti ẹ fi wá? Nwọn si wipe, Korneliu balogun ọrún, ọkunrin olõtọ, ati ẹniti o bẹ̀ru Ọlọrun, ti o si ni orukọ rere lọdọ gbogbo orilẹ-ede awọn Ju, on li a ti ọdọ Ọlọrun kọ́ nipasẹ angẹli mimọ́, lati ranṣẹ pè ọ wá si ile rẹ̀ ati lati gbọ́ ọ̀rọ li, ẹnu rẹ. Nigbana li o pè wọn wọle, o si fi wọn wọ̀. Nijọ keji o si dide, o ba wọn lọ, ninu awọn arakunrin ni Joppa si ba a lọ. Nijọ keji nwọn si wọ̀ Kesarea. Korneliu si ti nreti wọn, o si ti pè awọn ibatan ati awọn ọrẹ́ rẹ̀ timọtimọ jọ. O si ṣe bi Peteru ti nwọle, Korneliu pade rẹ̀, o wolẹ li ẹsẹ rẹ̀, o si foribalẹ fun u. Ṣugbọn Peteru gbé e dide, o ni, Dide; enia li emi tikarami pẹlu. Bi o si ti mba a sọ̀rọ, o wọle, o si bá awọn enia pipọ ti nwọn pejọ. O si wi fun wọn pe, Ẹnyin mọ̀ bi o ti jẹ ẽwọ̀ fun ẹniti iṣe Ju, lati ba ẹniti iṣe ara ilẹ miran kẹgbẹ, tabi lati tọ̀ ọ wá; ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mi pe, ki emi ki o máṣe pè ẹnikẹni li ẽwọ̀ tabi alaimọ́. Nitorina ni mo si ṣe wá li aijiyàn, bi a ti ranṣẹ pè mi: njẹ mo bère, nitori kili ẹnyin ṣe ranṣẹ pè mi? Korneliu si dahùn pe, Ni ijẹrin, mo nṣe adura wakati kẹsan ọjọ ni ile mi titi di akoko yi, si wo o, ọkunrin kan alaṣọ àla duro niwaju mi. O si wipe, Korneliu, a gbọ́ adura rẹ, ọrẹ-ãnu rẹ si wà ni iranti niwaju Ọlọrun. Njẹ ranṣẹ lọ si Joppa, ki o si pè Simoni wá, ẹniti apele rẹ̀ jẹ Peteru; o wọ̀ ni ile Simoni alawọ leti okun: nigbati o ba de, yio sọ̀rọ fun ọ. Nitorina ni mo si ti ranṣẹ si ọ lojukanna, iwọ si ṣeun ti o fi wá. Gbogbo wa pé niwaju Ọlọrun nisisiyi, lati gbọ́ ohun gbogbo ti a palaṣẹ fun ọ lati ọdọ Ọlọrun wá. Peteru si yà ẹnu rẹ̀, o si wipe, Nitõtọ mo woye pe, Ọlọrun kì iṣe ojuṣaju enia: Ṣugbọn ni gbogbo orilẹ-ède, ẹniti o ba bẹ̀ru rẹ̀, ti o si nṣiṣẹ ododo, ẹni itẹwọgba ni lọdọ rẹ̀. Ọ̀rọ ti Ọlọrun rán si awọn ọmọ Israeli, nigbati o wasu alafia nipa Jesu Kristi (on li Oluwa ohun gbogbo), Ẹnyin na mọ̀ ọ̀rọ na ti a kede rẹ̀ yiká gbogbo Judea, ti a bẹ̀rẹ si lati Galili wá, lẹhin baptismu ti Johanu wasu rẹ̀; Ani Jesu ti Nasareti, bi Ọlọrun ti dà Ẹmi Mimọ́ ati agbara le e lori: ẹniti o nkiri ṣe ore, nṣe didá ara gbogbo awọn ti Èṣu si npọn loju; nitori Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Awa si li ẹlẹri gbogbo ohun ti o ṣe, ni ilẹ awọn Ju, ati ni Jerusalemu; ẹniti nwọn pa, ti nwọn si fi gbékọ sori igi: On li Ọlọrun jinde ni ijọ kẹta, o si fi i hàn gbangba: Kì iṣe fun gbogbo enia, bikoṣe fun awọn ẹlẹri ti a ti ọwọ Ọlọrun yàn tẹlẹ, fun awa, ti a ba a jẹ, ti a si ba a mu lẹhin igbati o jinde kuro ninu okú. O si paṣẹ fun wa lati wasu fun awọn enia, ati lati jẹri pe, on li a ti ọwọ Ọlọrun yàn ṣe Onidajọ ãye on okú. On ni gbogbo awọn woli jẹri si pe, nipa orukọ rẹ̀ li ẹnikẹni ti o ba gbà a gbọ, yio ri imukuro ẹ̀ṣẹ gbà. Bi Peteru si ti nsọ ọ̀rọ wọnyi li ẹnu, Ẹmí Mimọ́ bà le gbogbo awọn ti o gbọ́ ọ̀rọ na. Ẹnu si yà awọn onigbagbọ ti ìkọlà, iye awọn ti o ba Peteru wá, nitoriti a tu ẹbùn Ẹmi Mimọ́ sori awọn Keferi pẹlu. Nitori nwọn gbọ́, nwọn nfọ onirũru ède, nwọn si nyìn Ọlọrun logo. Nigbana ni Peteru dahùn wipe, Ẹnikẹni ha le ṣòfin omi, ki a má baptisi awọn wọnyi, ti nwọn gbà Ẹmí Mimọ́ bi awa? O si paṣẹ ki a baptisi wọn li orukọ Jesu Kristi. Nigbana ni nwọn bẹ̀ ẹ ki o duro ni ijọ melokan.

Iṣe Apo 10:1-48 Yoruba Bible (YCE)

Ọkunrin kan wà ní Kesaria tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Kọniliu. Ó jẹ́ balogun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ tí à ń pè ní Ẹgbẹ́ Ọmọ Ogun Itali. Olùfọkànsìn ni. Òun ati gbogbo ìdílé rẹ̀ sì bẹ̀rù Ọlọrun. A máa ṣàánú àwọn eniyan lọpọlọpọ, a sì máa gbadura sí Ọlọrun nígbà gbogbo. Ní ọjọ́ kan, ní nǹkan agogo mẹta ọ̀sán, ó rí ìran kan. Angẹli Ọlọrun wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó ní, “Kọniliu!” Kọniliu bá tẹjú mọ́ ọn. Ẹ̀rù bà á, ó ní, “Kí ló dé, alàgbà?” Angẹli yìí bá sọ fún un pé, “Adura rẹ ti gbà; iṣẹ́ àánú rẹ ti gòkè lọ siwaju Ọlọrun. Ọlọrun sì ti ranti rẹ. Nisinsinyii wá rán àwọn kan lọ sí Jọpa, kí wọn lọ pe ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru, kí ó wá. Ó dé sílé ẹnìkan tí ń jẹ́ Simoni, tí ń ṣe òwò awọ, tí ilé rẹ̀ wà létí òkun.” Bí angẹli tí ó ń bá a sọ̀rọ̀ ti lọ tán, ó pe meji ninu àwọn iranṣẹ rẹ̀ ati ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, ọ̀kan ninu àwọn tí ó máa ń dúró tì í tímọ́tímọ́. Ó ròyìn ohun gbogbo fún wọn, ó bá rán wọn lọ sí Jọpa. Ní ọjọ́ keji, bí wọ́n ti ń bá ìrìn àjò wọn lọ, tí wọ́n súnmọ́ Jọpa, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbadura ní nǹkan agogo mejila ọ̀sán. Ebi dé sí i, ó wá ń wá nǹkan tí yóo jẹ. Bí wọ́n ti ń tọ́jú oúnjẹ lọ́wọ́, Peteru bá rí ìran kan. Ó rí ọ̀run tí ó pínyà, tí nǹkankan bí aṣọ tí ó fẹ̀, tí ó ní igun mẹrin, ń bọ̀ wálẹ̀, títí ó fi dé ilẹ̀. Gbogbo ẹranko ẹlẹ́sẹ̀ mẹrin ati oríṣìíríṣìí ẹranko tí ó ń fi àyà fà, ati ẹyẹ ojú ọ̀run ni ó wà ninu rẹ̀. Ó wá gbọ́ ohùn ẹnìkan tí ó ń bá a sọ̀rọ̀, ó ní, “Peteru dìde, pa ẹran kí o jẹ ẹ́!” Ṣugbọn Peteru dáhùn pé, “Èèwọ̀ Oluwa! N kò jẹ ẹrankẹ́ran tabi ẹran àìmọ́ kan rí.” Ohùn náà tún dún létí rẹ̀ lẹẹkeji pé, “Ohun tí Ọlọrun bá ti sọ di mímọ́, o kò gbọdọ̀ pè é ní ohun àìmọ́!” Èyí ṣẹlẹ̀ lẹẹmẹta. Lẹsẹkẹsẹ a tún gbé aṣọ náà lọ sókè ọ̀run. Ìran tí Peteru rí yìí rú u lójú. Bí ó ti ń rò ó pé kí ni ìtumọ̀ ohun tí òun rí yìí, àwọn tí Kọniliu rán sí i ti wádìí ibi tí ilé Simoni wà, wọ́n ti dé ẹnu ọ̀nà. Wọ́n ké “Àgò!” wọ́n sì ń bèèrè bí Simoni tí àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru bá dé sibẹ. Bí Peteru ti ń ronú lórí ìran yìí, Ẹ̀mí sọ fún un pé, “Àwọn ọkunrin mẹta ń wá ọ. Dìde, lọ sí ìsàlẹ̀, kí o bá wọn lọ láì kọminú nítorí èmi ni mo rán wọn.” Nígbà tí Peteru dé ìsàlẹ̀, ó wí fún àwọn ọkunrin náà pé, “Èmi tí ẹ̀ ń wá nìyí, kí ni ẹ̀ ń fẹ́ o?” Wọ́n bá dáhùn pé, “Kọniliu ọ̀gágun ni ó rán wa wá; eniyan rere ni, ó sì bẹ̀rù Ọlọrun tóbẹ́ẹ̀ tí gbogbo àwọn ọmọ Juu fi lè jẹ́rìí sí i. Angẹli Oluwa ni ó sọ fún un pé kí ó ranṣẹ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀, kí ó lè gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” Ni Peteru bá pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò. Nígbà tí ó di ọjọ́ keji, ó dìde, ó bá wọn lọ. Àwọn kan ninu àwọn ọmọ ìjọ ní Jọpa sì tẹ̀lé wọn. Ní ọjọ́ keji tí wọ́n gbéra ní Jọpa ni wọ́n dé Kesaria. Kọniliu ti ń retí wọn. Ó ti pe àwọn ẹbí ati àwọn tí ó jẹ́ ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. Bí Peteru ti fẹ́ wọlé, Kọniliu lọ pàdé rẹ̀. Ó kúnlẹ̀, ó sì foríbalẹ̀. Ṣugbọn Peteru fà á dìde, ó ní, “Dìde! Eniyan ni èmi náà.” Bí ó ti ń bá a sọ̀rọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ó bá a wọlé. Ó rí ọ̀pọ̀ eniyan tí ó ti péjọ. Ó sọ fún wọn pé, “Ó ye yín pé ó lòdì sí òfin wa pé kí ẹni tíí ṣe Juu kí ó ní nǹkan í ṣe pẹlu ẹni tí ó jẹ́ ẹ̀yà mìíràn, tabi kí ó lọ bẹ̀ ẹ́ wò ninu ilé rẹ̀. Ṣugbọn Ọlọrun ti fihàn mí pé n kò gbọdọ̀ pe ẹnikẹ́ni ni eniyan lásán tabi aláìmọ́. Ìdí tí mo ṣe wá láì kọminú nìyí nígbà tí o ranṣẹ sí mi. Mo wá fẹ́ mọ ìdí rẹ̀ tí o fi ranṣẹ sí mi.” Kọniliu dáhùn pé, “Ní ijẹrin, ní déédé àkókò yìí, mo ń gbadura ninu ilé mi ní agogo mẹta ọ̀sán. Ọkunrin kan bá yọ sí mi, ó wọ aṣọ dídán. Ó ní, ‘Kọniliu, Ọlọrun ti gbọ́ adura rẹ, ó sì ti ranti iṣẹ́ àánú rẹ. Nítorí náà, ranṣẹ lọ sí Jọpa, kí o lọ pe Simoni tí àdàpè rẹ̀ ń jẹ́ Peteru wá. Ó dé sílé Simoni tí ń ṣe òwò awọ, létí òkun.’ Lẹsẹkẹsẹ ni mo bá ranṣẹ sí ọ. O ṣeun tí o wá. Nisinsinyii gbogbo wa wà níwájú Ọlọrun láti gbọ́ ohun gbogbo tí Oluwa ti pa láṣẹ fún ọ láti sọ.” Peteru bá tẹnu bọ̀rọ̀. Ó ní, “Ó wá yé mi gan-an pé Ọlọrun kì í ṣe ojuṣaaju. Ẹnikẹ́ni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, tí ó sì ń ṣe rere ni yóo fà mọ́ra láì bèèrè orílẹ̀-èdè tí ó jẹ́. Ẹ mọ iṣẹ́ tí ó rán sí àwọn ọmọ Israẹli, ọ̀rọ̀ ìyìn rere alaafia nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni tíí ṣe Oluwa gbogbo eniyan. Ẹ mọ ohun tí ó ṣẹlẹ̀ ní gbogbo Judia. Ó bẹ̀rẹ̀ láti Galili lẹ́yìn ìrìbọmi tí Johanu ń sọ pé kí àwọn eniyan ṣe. Ẹ mọ̀ nípa Jesu ará Nasarẹti, bí Ọlọrun ti ṣe yàn án, tí ó fún un ní Ẹ̀mí Mímọ́ ati agbára; bí ó ti ṣe ń lọ káàkiri tí ó ń ṣe rere, tí ó ń wo gbogbo àwọn tí Satani ti ń dá lóró sàn, nítorí Ọlọrun wà pẹlu rẹ̀. Àwa yìí ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe ní ilẹ̀ àwọn Juu ati ní Jerusalẹmu. Wọ́n kan ọkunrin yìí mọ́ agbelebu. Ṣugbọn Ọlọrun jí i dìde ní ọjọ́ kẹta, ó sì jẹ́ kí eniyan rí i. Kì í ṣe gbogbo eniyan ni ó rí i bíkòṣe àwọn ẹlẹ́rìí tí Ọlọrun ti yàn tẹ́lẹ̀, àwa tí a bá a jẹ, tí a bá a mu lẹ́yìn tí ó jinde kúrò ninu òkú. Ó wá pàṣẹ fún wa láti waasu fún àwọn eniyan, kí á fi yé wọn pé Jesu yìí ni ẹni tí Ọlọrun ti yàn láti jẹ́ onídàájọ́ àwọn tí ó ti kú ati àwọn tí ó wà láàyè. Òun ni gbogbo àwọn wolii ń jẹ́rìí sí, tí wọ́n sọ pé gbogbo ẹni tí ó bá gbà á gbọ́ yóo ní ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ ní orúkọ rẹ̀.” Bí Peteru ti ń sọ̀rọ̀ báyìí lọ́wọ́, kò tíì dákẹ́ ọ̀rọ̀ tí ń sọ, bẹ́ẹ̀ ni Ẹ̀mí Mímọ́ bá bà lé gbogbo àwọn tí ó ń gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnu ya àwọn onigbagbọ tí wọ́n jẹ́ Juu tí wọ́n bá Peteru wá nítorí àwọn tí kì í ṣe Juu rí ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ gbà lọ́fẹ̀ẹ́ ati lẹ́kùn-únrẹ́rẹ́. Wọ́n gbọ́ tí wọn ń fi oríṣìíríṣìí èdè sọ̀rọ̀, tí wọn ń yin Ọlọrun fún iṣẹ́ ńlá rẹ̀. Peteru bá bèèrè pé, “Ta ló rí ohun ìdíwọ́ kan, ninu pé kí á ṣe ìrìbọmi fún àwọn wọnyi, tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa náà ti gbà á?” Lẹ́yìn náà, ó pàṣẹ pé kí wọ́n ṣe ìrìbọmi ní orúkọ Jesu Kristi. Wọ́n bá bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró lọ́dọ̀ wọn fún ọjọ́ díẹ̀.

Iṣe Apo 10:1-48 Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní (YCB)

Ọkùnrin kan sì wà ni Kesarea ti a ń pè ní Korneliu, balógun ọ̀rún ti ẹgbẹ́ ọmọ-ogun tí a ń pè ni Itali. Olùfọkànsìn, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run tilétilé rẹ̀ gbogbo, ẹni tí ó ń tọrẹ àánú púpọ̀ fún àwọn ènìyàn, tí ó sì ń gbàdúrà sọ́dọ̀ Ọlọ́run nígbà gbogbo. Níwọ́n wákàtí kẹsànán ọjọ́, ó rí nínú ìran kedere angẹli Ọlọ́run kan wọlé tọ̀ ọ́ wá, ó sì wí fún un pé, “Korneliu!” Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí. Sì rán ènìyàn nísinsin yìí lọ sí Joppa, kí wọn sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru. Ó wọ̀ sí ilé Simoni aláwọ, tí ilé rẹ̀ wà létí Òkun; òun ni yóò sọ fún ọ bí ìwọ ó ti ṣe.” Nígbà tí angẹli náà tí ó bá Korneliu sọ̀rọ̀ sì fi i sílẹ̀ lọ ó pe méjì nínú àwọn ìránṣẹ́ ilé rẹ̀, àti ọmọ-ogun olùfọkànsìn kan, nínú àwọn ti ó máa ń dúró tì í nígbà gbogbo. Nígbà tí ó sì tí ṣàlàyé ohun gbogbo fún wọn, ó rán wọn lọ sí Joppa. Ni ọjọ́ kejì bí wọ́n ti ń lọ lọ́nà àjò wọn, tí wọ́n sì súnmọ́ ilé náà, Peteru gun òkè ilé lọ láti gbàdúrà ni ìwọ̀n wákàtí kẹfà ọjọ́: Ebi sì pa á gidigidi, ó sì ń fẹ́ láti jẹun: ó bọ́ sí ojúran. Ó sì rí ọ̀run ṣí, ohun èlò kan si sọ̀kalẹ̀ bí gọgọwú ńlá, tí a ti igun mẹ́rẹ̀ẹ̀rin, sọ̀kalẹ̀ sí ilẹ̀: Nínú rẹ̀ ni onírúurú ẹranko ẹlẹ́ṣẹ̀ mẹ́rin wà, àti ohun tí ń rákò ni ayé àti ẹyẹ ojú ọ̀run. Ohùn kan si fọ̀ sí i pe, “Dìde, Peteru; máa pa kí o sì máa jẹ.” Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.” Ohùn kan sì tún fọ̀ sí i lẹ́ẹ̀méjì pé, “Ohun tí Ọlọ́run bá ti wẹ̀mọ́, ìwọ má ṣe pè é ní èèwọ̀ mọ́.” Èyí sì ṣe lẹ́ẹ̀mẹ́ta; lójúkan náà a sì gbé ohun èlò náà padà lọ sókè ọ̀run. Bí Peteru sì ti ń dààmú nínú ara rẹ̀ bí òun bá ti mọ̀ ìran tí òun ri yìí sí, si wò ó, àwọn ọkùnrin tí a rán wá láti ọ̀dọ̀ Korneliu dé. Wọ́n ń béèrè ilé Simoni, wọ́n dúró ní ẹnu-ọ̀nà. Wọn nahùn béèrè bí Simoni tí a ń pè ní Peteru, wọ̀ níbẹ̀. Bí Peteru sì ti ń ronú ìran náà, Ẹ̀mí wí fún un pé, “Wò ó, àwọn ọkùnrin mẹ́ta ń wá ọ. Ǹjẹ́ dìde, sọ̀kalẹ̀ kí ó sì bá wọn lọ, má ṣe kó ara ró láti bá wọn lọ: nítorí èmi ni ó rán wọn.” Nígbà náà ni Peteru sọ̀kalẹ̀ tọ àwọn ọkùnrin náà tí a rán, ó sì wí pé, “Wò ó, èmi ni ẹni tí ẹ̀yin ń wá: kín ni ìdí rẹ̀ ti ẹ fi wá?” Wọ́n sì wí pé, “Korneliu balógun ọ̀rún, ọkùnrin olóòtítọ́, àti ẹni ti ó bẹ̀rù Ọlọ́run, tí ó sì ní orúkọ rere lọ́dọ̀ gbogbo orílẹ̀-èdè àwọn Júù, òun ni a ti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run kọ́ nípasẹ̀ angẹli mímọ́, láti ránṣẹ́ pè ọ́ wá sí ilé rẹ̀ àti láti gbọ́ ọ̀rọ̀ lẹ́nu rẹ.” Nígbà náà ni Peteru pè wọ́n wọlé, ó gbà wọ́n lálejò. Ní ọjọ́ kejì, ó sì dìde, ó bá wọn lọ, díẹ̀ nínú àwọn ti o ti gbàgbọ́ ní Joppa sì bá a lọ pẹ̀lú. Lọ́jọ́ kejì wọ́n sì wọ Kesarea, Korneliu sì ti ń retí wọn, ó sì ti pe àwọn ìbátan àti àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀ tímọ́tímọ́ jọ. Ó sì ṣe bí Peteru ti ń wọlé, Korneliu pàdé rẹ̀, ó wólẹ̀ lẹ́sẹ̀ rẹ̀, ó sì foríbalẹ̀ fún un. Ṣùgbọ́n Peteru gbé e dìde, ó ni, “Dìde ènìyàn ni èmi tìkára mi pẹ̀lú.” Bí ó sì ti ń bá a sọ̀rọ̀, ó wọlé ó sì rí àwọn ènìyàn púpọ̀ tí wọ́n péjọ. Ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ̀yin mọ̀ bí ó ti jẹ́ èèwọ̀ fún ẹni tí ó jẹ́ Júù, láti bá ẹni tí ó jẹ́ ará ilẹ̀ mìíràn kẹ́gbẹ́, tàbí láti tọ̀ ọ́ wá; ṣùgbọ́n Ọlọ́run ti fihàn mi pé, ki èmi má ṣe pé ẹnikẹ́ni ni èèwọ̀ tàbí aláìmọ́. Nítorí náà ni mo sì ṣe wá ní àìjiyàn, bí a ti ránṣẹ́ pè mi: ǹjẹ́ mo béèrè, nítorí kín ní ẹ̀yin ṣe ránṣẹ́ pè mi?” Korneliu sì dáhùn pé, “Ní ìjẹrin, mo ń ṣe àdúrà wákàtí kẹsànán ọjọ́ ni ilé mi títí di idayìí, sì wò ó, ọkùnrin kan aláṣọ, àlà dúró níwájú mi. Ó sì wí pé, ‘Korneliu, a gbọ́ àdúrà rẹ, ọrẹ-àánú rẹ̀ sì wà ni ìrántí níwájú Ọlọ́run. Ǹjẹ́ ránṣẹ́ lọ sí Joppa, kí ó sì pe Simoni wá, ẹni ti àpèlé rẹ̀ ń jẹ́ Peteru; ó wọ̀ ní ilé Simoni aláwọ létí Òkun.’ Nítorí náà ni mo sì ṣe ránṣẹ́ sì ọ lójúkan náà, ìwọ sì ṣeun tí ó fi wá. Gbogbo wa pé níwájú Ọlọ́run nísinsin yìí, láti gbọ́ ohun gbogbo, ti a pàṣẹ fún ọ láti ọ̀dọ̀ Ọlọ́run wá.” Peteru sì ya ẹnu rẹ, ó sì wí pé, “Nítòótọ́ mo wòye pé, Ọlọ́run kì í ṣe ojúsàájú ènìyàn. Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀. Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo Ẹ̀yin náà mọ ọ̀rọ̀ náà tí a kéde rẹ̀ yíká gbogbo Judea, tí a bẹ̀rẹ̀ rẹ̀ láti Galili, lẹ́yìn bamitiisi ti Johanu wàásù rẹ̀. Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀. “Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi. Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba. Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú. Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú. Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.” Bí Peteru sì ti ń sọ ọ̀rọ̀ wọ̀nyí lẹ́nu, Ẹ̀mí Mímọ́ bà lé gbogbo àwọn ti ó gbọ́ ọ̀rọ̀ náà. Ẹnu sì yà àwọn onígbàgbọ́ ti a ti kọ nílà tí wọ́n bá Peteru wá, nítorí ti a tu ẹ̀bùn Ẹ̀mí Mímọ́ sórí àwọn aláìkọlà pẹ̀lú. Nítorí wọ́n gbọ́, wọ́n ń fọ onírúurú èdè, wọn sì yin Ọlọ́run lógo. Nígbà náà ni Peteru dáhùn wí pé, “Ẹnikẹ́ni ha lè ṣòfin pe, kí a má bamitiisi àwọn wọ̀nyí tí wọ́n gba Ẹ̀mí Mímọ́ bí àwa?” Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.